Àwọn Onídàájọ́ 6:1-40

6  Nígbà náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.+ Nítorí náà, Jèhófà fi wọ́n lé ọwọ́ Mídíánì+ fún ọdún méje.  Ọwọ́ Mídíánì sì wá lékè Ísírẹ́lì.+ Nítorí Mídíánì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àwọn ibi ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí tí ó jẹ́ ti abẹ́ ilẹ̀ fún ara wọn, èyí tí ó wà nínú àwọn òkè ńlá, àti àwọn hòrò àti àwọn ibi tí ó ṣòro láti dé.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí Ísírẹ́lì bá fún irúgbìn,+ Mídíánì àti Ámálékì+ àti àwọn Ará Ìlà-Oòrùn+ a gòkè wá, bẹ́ẹ̀ ni, wọn a gòkè wá gbéjà kò wọ́n.  Wọn a sì dó tì wọ́n, wọn a sì run èso ilẹ̀ náà dé iyàn-níyàn Gásà, wọn kì yóò sì jẹ́ kí ohun ìgbẹ́mìíró èyíkéyìí tàbí àgùntàn tàbí akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì.+  Nítorí àwọn àti ohun ọ̀sìn wọn a gòkè wá pẹ̀lú àwọn àgọ́ wọn. Wọn a wá ní iye tí ó pọ̀ bí eéṣú,+ àwọn àti àwọn ràkúnmí wọn kò sì níye;+ wọn a sì wá sí ilẹ̀ náà láti run ún.+  Ísírẹ́lì sì di òtòṣì gidigidi nítorí Mídíánì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ ní tìtorí Mídíánì,+  Jèhófà tẹ̀ síwájú láti rán ọkùnrin kan, wòlíì kan,+ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ò sì wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Èmi ni ó mú yín gòkè wá láti Íjíbítì,+ tí mo sì tipa bẹ́ẹ̀ mú yín jáde ní ilé ẹrú.+  Báyìí ni mo ṣe dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ Íjíbítì àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó ń ni yín lára, mo sì lé wọn jáde kúrò níwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín.+ 10  Síwájú sí i, mo wí fún yín pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.+ Ẹ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì+ nínú ilẹ̀ àwọn ẹni tí ẹ ń gbé.”+ Ẹ kò sì fetí sí ohùn mi.’”+ 11  Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì Jèhófà wá,+ ó sì jókòó sábẹ́ igi ńlá tí ó wà ní Ọ́fírà, èyí tí ó jẹ́ ti Jóáṣì ọmọ Abi-ésérì,+ bí Gídíónì+ ọmọkùnrin rẹ̀ ti ń lu àlìkámà níbi ìfúntí wáìnì kí ó lè tètè ṣe é kí Mídíánì tó rí i. 12  Nígbà náà ni áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án, ó sì wí fún un pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ,+ ìwọ akíkanjú, alágbára ńlá.” 13  Látàrí èyí, Gídíónì wí fún un pé: “Dákun, olúwa mi, ṣùgbọ́n bí Jèhófà bá wà pẹ̀lú wa, èé ṣe nígbà náà, tí gbogbo èyí fi wá sórí wa,+ gbogbo àwọn ìṣe àgbàyanu+ rẹ̀ dà, tí àwọn baba wa ṣèròyìn fún wa,+ pé, ‘Íjíbítì ha kọ́ ni Jèhófà ti mú wa gòkè wá?’+ Wàyí o, Jèhófà ti kọ̀ wá tì,+ ó sì fi wá lé àtẹ́lẹwọ́ Mídíánì.” 14  Látàrí ìyẹn, Jèhófà kọjú sí i, ó sì wí pé: “Lọ pẹ̀lú agbára rẹ yìí,+ dájúdájú, ìwọ yóò sì gba Ísírẹ́lì là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Mídíánì.+ Èmi kò ha rán ọ bí?”+ 15  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún un pé: “Dákun, Jèhófà. Kí ni kí n fi gba Ísírẹ́lì là?+ Wò ó! Ẹgbẹ̀rún tèmi ni èyí tí ó kéré jù lọ ní Mánásè, èmi sì ni ó kéré jù lọ ní ilé baba mi.”+ 16  Ṣùgbọ́n Jèhófà wí fún un pé: “Nítorí pé èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ dájúdájú, ìwọ yóò sì ṣá Mídíánì+ balẹ̀ bí ẹni pé ọkùnrin kan ṣoṣo ni.” 17  Látàrí èyí, ó wí fún un pé: “Wàyí o, bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ,+ kí ìwọ pẹ̀lú ṣe iṣẹ́ àmì kan fún mi, pé ìwọ ni ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀.+ 18  Jọ̀wọ́, má ṣe kúrò níhìn-ín títí èmi yóò fi tọ̀ ọ́ wá,+ tí èmi yóò sì mú ẹ̀bùn mi jáde, tí èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí pé: “Èmi, ní tèmi, yóò jókòó síhìn-ín títí ìwọ yóò fi padà.” 19  Gídíónì sì wọlé lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pèsè ọmọ ewúrẹ́ kan sílẹ̀,+ ó sì fi òṣùwọ̀n eéfà ìyẹ̀fun kan ṣe àwọn àkàrà aláìwú.+ Ẹran náà ni ó fi sínú apẹ̀rẹ̀, omitoro rẹ̀ ni ó sì fi sínú ìkòkò ìse-oúnjẹ, lẹ́yìn èyí tí ó gbé e jáde lọ bá a lábẹ́ igi ńlá náà, ó sì gbé e kalẹ̀. 20  Wàyí o, áńgẹ́lì Ọlọ́run tòótọ́ wí fún un pé: “Gbé ẹran náà àti àwọn àkàrà aláìwú náà, kí o sì gbé wọn sórí àpáta ńlá lọ́hùn-ún yẹn,+ sì da omitoro náà jáde.” Látàrí ìyẹn, ó ṣe bẹ́ẹ̀. 21  Nígbà náà ni áńgẹ́lì Jèhófà na orí ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kan ẹran náà àti àwọn àkàrà aláìwú náà, iná sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè láti inú àpáta náà, ó sì jó ẹran àti àwọn àkàrà aláìwú+ náà run. Ní ti áńgẹ́lì Jèhófà, ó pòórá mọ́ ọn lójú. 22  Nítorí náà, Gídíónì mọ̀ pé áńgẹ́lì Jèhófà ni.+ Ní kíá, Gídíónì wí pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nítorí ìdí náà pé mo ti rí áńgẹ́lì Jèhófà lójúkojú!”+ 23  Ṣùgbọ́n Jèhófà wí fún un pé: “Àlàáfíà ni fún ọ.+ Má bẹ̀rù.+ Ìwọ kì yóò kú.”+ 24  Nítorí náà, Gídíónì mọ pẹpẹ+ kan níbẹ̀ fún Jèhófà, a sì ń pè e ní+ Jehofa-ṣálómù títí di òní yìí. Ó ṣì wà ní Ọ́fírà+ ti àwọn ọmọ Abi-ésérì. 25  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òru yẹn pé Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Mú ẹgbọrọ akọ màlúù náà, akọ màlúù tí ó jẹ́ ti baba rẹ, ìyẹn ni, ẹgbọrọ akọ màlúù kejì , ọlọ́dún méje, kí o sì ya pẹpẹ Báálì+ tí ó jẹ́ ti baba rẹ lulẹ̀, òpó ọlọ́wọ̀ tí ó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni kí o gé lulẹ̀.+ 26  Kí o sì mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní orí ibi odi agbára yìí, pẹ̀lú ọ̀wọ́ àwọn òkúta, kí o sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù kejì kí o sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun lórí àwọn ègé igi òpó ọlọ́wọ̀ tí ìwọ yóò gé lulẹ̀.” 27  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Gídíónì mú ọkùnrin mẹ́wàá lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì lọ ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ fún un;+ ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ pé, nítórí pé ó bẹ̀rù agbo ilé baba rẹ̀ àti àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà púpọ̀ jù láti ṣe é ní ọ̀sán, ó lọ ṣe é ní òru.+ 28  Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ bí ti tẹ́lẹ̀ rí, họ́wù, wò ó! a ti bi pẹpẹ Báálì wó, òpó ọlọ́wọ̀+ tí ó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni a ti gé lulẹ̀, ẹgbọrọ akọ màlúù kejì ni a sì ti fi rúbọ lórí pẹpẹ tí a mọ. 29  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ta ní ṣe nǹkan yìí?” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí, wọ́n sì ṣe ìwákiri. Níkẹyìn, wọ́n wí pé: “Gídíónì ọmọkùnrin Jóáṣì ni ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí.” 30  Nítorí náà, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà sọ fún Jóáṣì pé: “Mú ọmọkùnrin rẹ jáde kí ó lè kú,+ nítorí pé ó ti bi pẹpẹ Báálì wó, àti nítorí pé ó ti gé òpó ọlọ́wọ̀ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lulẹ̀.” 31  Látàrí èyí, Jóáṣì+ wí fún gbogbo àwọn tí wọ́n dúró lòdì sí i pé:+ “Ẹ̀yin ha ni ẹni tí yóò gbèjà Báálì lábẹ́ òfin láti rí i bóyá ẹ̀yin fúnra yín lè gbà á là bí? Ẹnì yòówù tí ó bá gbèjà rẹ̀ lábẹ́ òfin ni ó yẹ kí a fi ikú pa, àní ní òwúrọ̀ yìí.+ Bí Ọlọ́run bá ni,+ ẹ jẹ́ kí ó gbèjà ara rẹ̀ lábẹ́ òfin,+ nítorí pé ẹnì kan ti bi pẹpẹ rẹ̀ wó.” 32  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní Jerubáálì+ ní ọjọ́ náà, pé: “Jẹ́ kí Báálì gbèjà ara rẹ̀ lábẹ́ òfin, nítorí pé ẹnì kan ti bi pẹpẹ rẹ̀ wó.”+ 33  Gbogbo Mídíánì+ àti Ámálékì+ àti àwọn Ará Ìlà-Oòrùn+ sì kóra jọpọ̀ bí ọ̀kan,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọdá, wọ́n sì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jésíréélì.+ 34  Ẹ̀mí+ Jèhófà sì bo Gídíónì tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí fun ìwo,+ a sì pe àwọn ọmọ Abi-ésérì+ jọ sẹ́yìn rẹ̀. 35  Ó sì rán àwọn ońṣẹ́+ jáde la gbogbo Mánásè já, a sì pe àwọn náà jọ sẹ́yìn rẹ̀. Ó rán àwọn ońṣẹ́ jáde jákèjádò Áṣérì àti Sébúlúnì àti Náfútálì pẹ̀lú, wọ́n sì gòkè wá pàdé rẹ̀. 36  Nígbà náà ni Gídíónì wí fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Bí ìwọ yóò bá gba Ísírẹ́lì là nípasẹ̀ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí,+ 37  èmi yóò fi ìṣùpọ̀ irun àgùntàn sílẹ̀ síta ní ilẹ̀ ìpakà níhìn-ín. Bí ìrì bá sẹ̀ sórí ìṣùpọ̀ irun náà nìkan ṣoṣo ṣùgbọ́n tí orí gbogbo ilẹ̀ jẹ́ gbígbẹ, nígbà náà, èmi yóò mọ̀ pé ìwọ yóò gba Ísírẹ́lì là nípasẹ̀ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí.” 38  Ó sì wá já sí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì , tí ó sì fún ìṣùpọ̀ irun náà, ó ro ìrì tí ó tó láti fi omi kún àwokòtò ńlá fún àsè láti ara ìṣùpọ̀ irun náà. 39  Bí ó ti wù kí ó rí, Gídíónì wí fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ìbínú rẹ ru sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré sí i. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n fi ìṣùpọ̀ irun náà ṣe ìdánwò lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré sí i. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ìṣùpọ̀ irun náà nìkan ṣoṣo jẹ́ gbígbẹ, sì jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀.” 40  Nítorí náà, Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ ní òru yẹn; ìṣùpọ̀ irun náà nìkan ṣoṣo sì jẹ́ gbígbẹ, ìrì sì sẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé