Ẹ́sítérì 4:1-17
4 Módékáì+ alára sì wá mọ̀ nípa ohun gbogbo tí a ti ṣe;+ Módékáì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọn ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ+ àti eérú+ bora, ó sì jáde lọ sí àárín ìlú ńlá náà, ó sì ké jáde pẹ̀lú igbe ẹkún rara àti kíkorò.+
2 Níkẹyìn, ó wá títí dé iwájú ẹnubodè ọba,+ nítorí pé ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ wá sí ẹnubodè ọba.
3 Àti ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀,+ ibikíbi tí ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀ bá dé, ọ̀fọ̀ ńláǹlà+ wà láàárín àwọn Júù, àti ààwẹ̀ gbígbà+ àti ẹkún sísun àti ìpohùnréré ẹkún. Aṣọ àpò ìdọ̀họ+ àti eérú+ di èyí tí a tẹ́ sílẹ̀ bí àga ìrọ̀gbọ̀kú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.
4 Àwọn ọ̀dọ́bìnrin Ẹ́sítérì àti àwọn ìwẹ̀fà+ rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wọlé wá, wọ́n sì sọ fún un. Ó sì dun ayaba gidigidi. Nígbà náà ni ó fi ẹ̀wù ránṣẹ́ láti fi wọ Módékáì, kí ó sì mú aṣọ àpò ìdọ̀họ rẹ̀ kúrò lára rẹ̀. Kò sì gbà á.+
5 Látàrí èyí, Ẹ́sítérì pe Hátákì,+ ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó yàn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, ó sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún un nípa Módékáì, láti mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí àti ohun tí èyí jẹ́.
6 Nítorí náà, Hátákì jáde lọ sọ́dọ̀ Módékáì sí ojúde ìlú ńlá tí ó wà níwájú ẹnubodè ọba.
7 Nígbà náà ni Módékáì sọ fún un nípa gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i+ àti iye owó pàtó tí Hámánì ti sọ pé kí wọ́n san sí ibi ìṣúra ọba+ láti gbéjà ko àwọn Júù, láti pa wọ́n run.+
8 Àti ẹ̀dà+ ìwé òfin tí a ti fi fúnni ní Ṣúṣánì+ pé kí a pa wọ́n rẹ́ ráúráú ni ó fi fún un láti fi han Ẹ́sítérì àti kí ó sì sọ fún un, kí ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ fún un+ pé kí ó wọlé tọ ọba lọ, kí ó sì fi taratara bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀,+ kí ó sì ṣe ìbéèrè ní tààràtà níwájú rẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀.+
9 Wàyí o, Hátákì+ wọlé, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Módékáì fún Ẹ́sítérì.
10 Lẹ́yìn náà ni Ẹ́sítérì sọ fún Hátákì, ó sì pàṣẹ fún un nípa Módékáì+ pé:
11 “Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba àti àwọn ènìyàn àgbègbè abẹ́ àṣẹ ọba ni wọ́n mọ̀ pé, ní ti ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí tí a kò bá pè, tí ó bá wọlé tọ ọba lọ ní àgbàlá inú lọ́hùn-ún,+ òfin+ rẹ̀ kan ṣoṣo ni pé kí a ṣe ikú pa á; àyàfi bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí i ni òun pẹ̀lú yóò fi wà láàyè+ dájúdájú. Ní ti èmi, a kò tíì pè mí láti wọlé tọ ọba lọ fún ọgbọ̀n ọjọ́ báyìí.”
12 Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ Ẹ́sítérì fún Módékáì.
13 Nígbà náà ni Módékáì sọ pé kí wọ́n fún Ẹ́sítérì lésì pé: “Má rò nínú ọkàn rẹ pé agbo ilé ọba yóò yèbọ́ lọ́nà èyíkéyìí ju gbogbo àwọn Júù yòókù.+
14 Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò yìí, ìtura àti ìdáǹdè yóò dìde fún àwọn Júù láti ibòmíràn;+ ṣùgbọ́n ní ti ìwọ àti ilé baba rẹ, ẹ ó ṣègbé. Ta sì ni ó mọ̀ bóyá nítorí irú àkókò yìí ni ìwọ fi dé ipò ọlá ayaba?”+
15 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ẹ́sítérì sọ pé kí wọ́n fún Módékáì lésì pé:
16 “Máa lọ, kó gbogbo àwọn Júù tí a lè rí ní Ṣúṣánì+ jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀+ nítorí mi, kí ẹ má jẹun, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má mu fún ọjọ́ mẹ́ta,+ ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi pẹ̀lú àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin mi,+ èmi yóò gbààwẹ̀ bákan náà, látàrí ìyẹn, èmi yóò sì wọlé tọ ọba lọ, èyí tí kò bá òfin mu; bí ó bá ṣe pé èmi yóò ṣègbé,+ èmi yóò ṣègbé.”
17 Látàrí èyí, Módékáì kọjá lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ẹ́sítérì gbé kalẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí àṣẹ.