Ẹ́sítérì 9:1-32
9 Ní oṣù kejìlá, èyíinì ni, oṣù Ádárì,+ ní ọjọ́ kẹtàlá rẹ̀, nígbà tí ó tó àkókò láti mú ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀ ṣẹ,+ ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá Júù ti dúró dè láti jẹ gàba lé wọn lórí, àní òdì-kejì rẹ̀ ni ó ṣẹlẹ̀, ní ti pé àwọn Júù alára jẹ gàba lé àwọn tí ó kórìíra wọn lórí.+
2 Àwọn Júù kó ara wọn jọpọ̀+ nínú àwọn ìlú ńlá wọn ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ Ahasuwérúsì Ọba,+ láti gbé ọwọ́ lé àwọn tí ń wá ìṣeléṣe wọn,+ kò sì sí ọkùnrin kan tí ó mú ìdúró rẹ̀ níwájú wọn, nítorí ìbẹ̀rùbojo+ wọn ti mú gbogbo àwọn ènìyàn.
3 Gbogbo àwọn ọmọ aládé+ àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ àti àwọn baálẹ̀+ àti àwọn gómìnà àti àwọn olùṣe iṣẹ́ àmójútó+ tí ó jẹ́ ti ọba sì ń ṣèrànwọ́ fún àwọn Júù, nítorí ìbẹ̀rùbojo+ Módékáì ti mú wọn.
4 Nítorí Módékáì tóbi+ ní ilé ọba, òkìkí+ rẹ̀ sì kàn jákèjádò gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ, nítorí pé ọkùnrin náà Módékáì ń pọ̀ sí i ṣáá.+
5 Àwọn Júù sì ń fi idà+ ṣá gbogbo àwọn ọ̀tá wọn balẹ̀ pẹ̀lú ìpakúpa àti pẹ̀lú pípa àti ìparun, wọ́n sì ń ṣe bí wọ́n ṣe fẹ́ sí àwọn tí ó kórìíra wọn.+
6 Àti ní Ṣúṣánì+ ilé aláruru, àwọn Júù ṣe pípa, ìparun ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin sì ṣẹlẹ̀.
7 Bákan náà, Páṣáńdátà àti Dálífónì àti Ásípátà
8 àti Pọ́rátà àti Adalíà àti Árídátà
9 àti Pámáṣítà àti Árísáì àti Árídáì àti Fáísátà,
10 àwọn ọmọkùnrin+ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti Hámánì+ ọmọkùnrin Hamédátà, ẹni tí ó fi ẹ̀tanú hàn sí àwọn Júù,+ ni wọ́n pa; ṣùgbọ́n wọn kò gbé ọwọ́ wọn lé ohun ìpiyẹ́.+
11 Ní ọjọ́ yẹn, iye àwọn tí a pa ní Ṣúṣánì ilé aláruru wá síwájú ọba.
12 Ọba sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún Ẹ́sítérì Ayaba+ pé: “Ní Ṣúṣánì ilé aláruru,+ àwọn Júù ti ṣe pípa, ìparun ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá sì ti ṣẹlẹ̀. Kí ni wọ́n ti ṣe+ ní ìyókù àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ ọba? Kí sì ni ohun tí ìwọ ń tọrọ? Àní kí a fi fún ọ.+ Kí sì ni ìbéèrè rẹ síwájú sí i?+ Àní kí ó di ṣíṣe.”
13 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ẹ́sítérì sọ pé: “Bí ó bá dára lójú ọba,+ jẹ́ kí a yọ̀ǹda fún àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣánì lọ́la pẹ̀lú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti òní;+ sì jẹ́ kí a gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́ sórí òpó igi.”+
14 Nítorí náà, ọba sọ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀.+ Nígbà náà ni a gbé òfin kan jáde ní Ṣúṣánì, a sì gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́.
15 Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣánì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọpọ̀ pẹ̀lú ní ọjọ́ kẹrìnlá+ oṣù Ádárì, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Ṣúṣánì; ṣùgbọ́n wọn kò gbé ọwọ́ wọn lé ohun ìpiyẹ́.+
16 Ní ti ìyókù àwọn Júù tí ó wà ní àwọn àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ ọba, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀, ìdúró fún ọkàn+ wọ́n sì ṣẹlẹ̀, ìgbẹ̀san+ ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn sì ṣẹlẹ̀ àti pípa ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rún nínú àwọn tí ó kórìíra wọn; ṣùgbọ́n wọn kò gbé ọwọ́ wọn lé ohun ìpiyẹ́,
17 ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì; ìsinmi sì wà ní ọjọ́ kẹrìnlá rẹ̀, sísọ ọ́ di ọjọ́ jíjẹ àkànṣe àsè+ àti ti ayọ̀ yíyọ̀ sì wáyé.+
18 Ní ti àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣánì, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá+ rẹ̀ àti ní ọjọ́ kẹrìnlá rẹ̀, ìsinmi sì wà ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún rẹ̀, sísọ ọ́ di ọjọ́ jíjẹ àkànṣe àsè àti ti ayọ̀ yíyọ̀+ sì wáyé.
19 Ìdí nìyẹn tí àwọn Júù tí ó wà ní ìgbèríko, tí ń gbé àwọn ìlú ńlá ti àgbègbè jíjìn, fi ń ṣe ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì+ ní ọjọ́ ayọ̀ yíyọ̀+ àti jíjẹ àkànṣe àsè àti ọjọ́ rere+ àti fífi ìpín+ ránṣẹ́ sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.
20 Módékáì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí, ó sì fi àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ Ahasuwérúsì Ọba, àwọn tí ń bẹ nítòsí àti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn,
21 láti gbé iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ kà wọ́n lórí láti máa pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì àti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún rẹ̀ mọ́ déédéé lọ́dọọdún,
22 gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ tí àwọn Júù sinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn+ àti oṣù tí a yí padà fún wọn láti inú ẹ̀dùn-ọkàn sí ayọ̀ yíyọ̀ àti láti inú ọ̀fọ̀+ sí ọjọ́ rere, láti máa pa wọ́n mọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ jíjẹ àkànṣe àsè àti ayọ̀ yíyọ̀ àti fífi ìpín ránṣẹ́ sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì+ àti ẹ̀bùn fún àwọn òtòṣì.+
23 Àwọn Júù sì tẹ́wọ́ gba ohun tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti ohun tí Módékáì ti kọ sí wọn.
24 Nítorí Hámánì+ ọmọkùnrin Hamédátà,+ ọmọ Ágágì,+ ẹni tí ó fi ẹ̀tanú+ hàn sí gbogbo Júù, ni òun fúnra rẹ̀ ti pète-pèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run,+ ó sì ti mú kí a ṣẹ́ Púrì,+ èyíinì ni, Kèké,+ láti kó ìdààmú bá wọn, kí ó sì pa wọ́n run.
25 Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹ́sítérì wọlé wá síwájú ọba, ó fi ìwé àkọsílẹ̀+ sọ pé: “Kí ìpètepèrò búburú+ rẹ̀ tí ó ti ṣe nípa àwọn Júù padà wá sórí ara rẹ̀”;+ wọ́n sì gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi.+
26 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ọjọ́ wọ̀nyí ní Púrímù, gẹ́gẹ́ bí orúkọ Púrì.+ Ìdí nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀rọ̀ lẹ́tà+ yìí àti ohun tí wọ́n ti rí nípa èyí àti ohun tí ó ti wá sórí wọn,
27 tí àwọn Júù fi gbé e karí, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á fún ara wọn àti fún ọmọ wọn àti fún gbogbo àwọn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn,+ pé kò gbọ́dọ̀ kọjá lọ, iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe náà láti máa pa ọjọ́ méjèèjì wọ̀nyí mọ́ déédéé, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ nípa wọn àti gẹ́gẹ́ bí àkókò wọn tí a yàn kalẹ̀ lọ́dọọdún.
28 Ọjọ́ wọ̀nyí ni kí a sì máa rántí, kí a sì máa pa mọ́ ní ìran-ìran, ìdílé kọ̀ọ̀kan, àgbègbè abẹ́ àṣẹ kọ̀ọ̀kan àti ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, ọjọ́ Púrímù wọ̀nyí kò sì gbọ́dọ̀ kọjá lọ láàárín àwọn Júù àti ṣíṣe ààtò ìrántí+ wọn kò gbọ́dọ̀ wá sí òpin láàárín ọmọ wọn.
29 Ẹ́sítérì Ayaba, ọmọbìnrin Ábíháílì,+ àti Módékáì tí í ṣe Júù sì tẹ̀ síwájú láti kọ̀wé lọ́nà tí ó rinlẹ̀ gidigidi láti fìdí ìjóòótọ́ lẹ́tà kejì yìí nípa Púrímù múlẹ̀.
30 Nígbà náà ni ó fi àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù tí ó wà nínú ẹ̀tà-dín-láàádóje àgbègbè abẹ́ àṣẹ+ ilẹ̀ ọba ti Ahasuwérúsì,+ ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́,+
31 láti fìdí ìjóòótọ́ ọjọ́ Púrímù wọ̀nyí múlẹ̀ ní àkókò wọn tí a yàn kalẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Módékáì tí í ṣe Júù àti Ẹ́sítérì Ayaba ṣe gbé e kà wọ́n lórí,+ àti gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti gbé e ka ọkàn ara wọn àti ọmọ wọn,+ àwọn ọ̀ràn nípa ààwẹ̀+ àti igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.+
32 Àsọjáde Ẹ́sítérì sì fìdí ìjóòótọ́ ọ̀ràn wọ̀nyí nípa Púrímù+ múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sílẹ̀ sínú ìwé kan.