Ìsíkíẹ́lì 41:1-26
41 Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú mi wá sínú tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn àwọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni fífẹ̀ rẹ̀ ní ìhín, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà sì ni fífẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀hún, fífẹ̀ ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ náà.
2 Fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, àwọn ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìhín àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ọ̀hún. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn gígùn rẹ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́; àti fífẹ̀ rẹ̀, ogún ìgbọ̀nwọ́.
3 Ó sì wọ inú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ọwọ̀n ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì; àti ẹnu ọ̀nà náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà; fífẹ̀ ẹnu ọ̀nà náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méje.
4 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn gígùn rẹ̀, ogún ìgbọ̀nwọ́; àti fífẹ̀ rẹ̀, ogún ìgbọ̀nwọ́,+ níwájú tẹ́ńpìlì. Lẹ́yìn náà, ó wí fún mi pé: “Èyí ni Ibi Mímọ́ Jù Lọ.”+
5 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọn ògiri ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. Fífẹ̀ ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin níhà gbogbo; ó wà yí ilé náà ká, níhà gbogbo.+
6 Àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ sì jẹ́ ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ lórí ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́, àjà mẹ́ta, àti nígbà ọgbọ̀n; wọ́n sì wọ inú ògiri tí ó jẹ́ ti ilé yẹn, èyíinì ni, àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ yí ká, kí a bàa lè dì wọ́n mú, ṣùgbọ́n a kò dì wọ́n mú sára ògiri ilé náà.+
7 Ìmúgbòòrò sì ń bẹ àti yíyípadà sókè-sókè sí àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́, nítorí ọ̀nà àbákọjá aláyìí-kọrọyí ilé náà lọ sókè-sókè yí ilé náà ká.+ Nítorí náà, ìmúgbòòrò síwájú wà fún ilé náà sókè, àti láti àjà ìsàlẹ̀ pátápátá, ènìyàn lè gòkè lọ sí àjà òkè pátápátá,+ gba ti àjà àárín.
8 Mo sì rí i pé pèpéle gíga kan wà fún ilé náà yí ká. Ní ti ìpìlẹ̀ àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́, ọ̀pá esùsú kíkún kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà dé ibi ìsopọ̀+ wà.
9 Fífẹ̀ ògiri tí ó jẹ́ ti ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́, ní òde, jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Àyè tí a fi sílẹ̀ gbayawu sì wà nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ tí ó jẹ́ ti ilé náà.
10 Àti láàárín àwọn yàrá ìjẹun,+ fífẹ̀ náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ yí ilé náà ká, níhà gbogbo.
11 Ẹnu ọ̀nà ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ sì wà ní ìhà àyè tí a fi sílẹ̀ gbayawu, ẹnu ọ̀nà kan síhà àríwá àti ẹnu ọ̀nà kan síhà gúúsù; fífẹ̀ àyè ilẹ̀ tí a fi sílẹ̀ gbayawu náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, níha gbogbo.
12 Ilé tí ó wà níwájú àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀, tí ìhà rẹ̀ dojú kọ ìwọ̀-oòrùn, jẹ́ àádọ́rin ìgbọ̀nwọ́ ní gbígbòòrò. Ògiri ilé náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀, ó sì wà níhà gbogbo; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
13 Ó sì wọn ilé náà, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn; àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀ àti ilé náà àti ògiri rẹ̀, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.
14 Fífẹ̀ iwájú ilé náà àti àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀ níhà ìlà-oòrùn jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
15 Ó sì wọn gígùn ilé tí ó wà níwájú àgbègbè tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí ó wà lẹ́yìn rẹ̀ àti ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
Àti tẹ́ńpìlì náà àti àyè inú lọ́hùn-ún+ àti àwọn gọ̀bì àgbàlá náà;
16 àwọn ibi àbáwọlé, àti àwọn fèrèsé oníférémù tóóró,+ àti àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀ wà yí ká àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ní iwájú ibi àbáwọlé, igi pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ wà tí a ṣe ọ̀ṣọ́ sí yí ká,+ ó sì jẹ́ láti ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ dé ibi àwọn fèrèsé; àwọn fèrèsé náà sì jẹ́ èyí tí a bò.
17 Dé òkè ẹnu ọ̀nà àti títí dé ilé inú lọ́hùn-ún àti lóde àti lára gbogbo ògiri yí ká, lára ilé inú lọ́hùn-ún àti lóde, àwọn ìwọ̀n ń bẹ,
18 àní àwọn kérúbù tí a gbẹ́+ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ,+ pẹ̀lú àwòrán igi ọ̀pẹ láàárín kérúbù kan àti kérúbù kan, kérúbù náà sì ní ojú méjì.+
19 Ojú ènìyàn sì wà níhà àwòrán igi ọ̀pẹ ní ìhà ìhín, àti ojú ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ níhà àwòrán igi ọ̀pẹ ní ìhà ọ̀hún,+ a gbẹ́ wọn sára ilé náà yí ká.
20 Láti ilẹ̀pẹ̀pẹ̀ dé òkè ẹnu ọ̀nà ni àwọn kérúbù tí a gbẹ́ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ wà, lára ògiri tẹ́ńpìlì.
21 Ní ti tẹ́ńpìlì náà, òpó ilẹ̀kùn náà dọ́gba ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin;+ àti ní iwájú ibi mímọ́ ni ìrísí kan wà tí ó dà bí ìrísí tí ó tẹ̀ lé e yìí:
22 pẹpẹ tí a fi igi ṣe jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, ó sì ní àwọn arópòódògiri rẹ̀.+ Gígùn rẹ̀ àti àwọn ògiri rẹ̀ ni a sì fi igi ṣe. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún mi pé: “Èyí ni tábìlì tí ó wà níwájú Jèhófà.”+
23 Tẹ́ńpìlì àti ibi mímọ́ ní ilẹ̀kùn méjì.+
24 Awẹ́ méjì sì wà fún àwọn ilẹ̀kùn náà, àwọn méjèèjì sì ṣeé yí. Ilẹ̀kùn kan ní awẹ́ méjì, èkejì sì ní awẹ́ méjì.
25 A sì ṣe àwọn kérúbù àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ+ sára wọn, sára àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì, bí àwọn tí a ṣe sárá ògiri, ìbòrí aṣíjiboni tí a fi igi ṣe sì wà lókè iwájú gọ̀bì náà lóde.
26 Àwọn fèrèsé oníférémù tóóró+ àti àwọn àwòrán igi ọ̀pẹ sì wà ní ìhín àti ní ọ̀hún lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ gọ̀bì náà àti àwọn ìyẹ̀wù ẹ̀gbẹ́ ilé náà àti àwọn ìbòrí aṣíjiboni náà.