Ìsíkíẹ́lì 48:1-35
48 “Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ẹ̀yà náà. Láti ìkángun àríwá, ní ìhà tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà Hẹ́tílónì+ dé àtiwọ Hámátì,+ Hasari-énánì,+ ààlà Damásíkù síhà àríwá, ní ìhà Hámátì; kí ó sì ní ojú ààlà ti ìlà-oòrùn àti ti ìwọ̀-oòrùn, ìpín kan fún Dánì.+
2 Àti ní ààlà Dánì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Áṣérì.+
3 Àti ní ààlà Áṣérì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn àní dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Náfútálì.+
4 Àti ní ààlà Náfútálì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Mánásè.+
5 Àti ní ààlà Mánásè, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Éfúráímù.+
6 Àti ní ààlà Éfúráímù, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Rúbẹ́nì.+
7 Àti ní ààlà Rúbẹ́nì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Júdà.+
8 Àti ní ààlà Júdà, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, kí ọrẹ tí ẹ ó fi ṣe ìtọrẹ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀,+ àti gígùn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ìpín láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn. Ibùjọsìn náà yóò sì wà ní àárín rẹ̀.+
9 “Ní ti ọrẹ tí ẹ ó fi ṣe ìtọrẹ fún Jèhófà, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.
10 Àti ní ti ìwọ̀nyí, kí ọrẹ mímọ́ wà fún àwọn àlùfáà,+ níhà àríwá, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́, àti níhà ìwọ̀-oòrùn, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀, àti níhà ìlà-oòrùn, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀, àti níhà gúúsù, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní gígùn. Ibùjọsìn Jèhófà yóò sì wà ní àárín rẹ̀.+
11 Yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà, àwọn tí a ti sọ di mímọ́ nínú àwọn ọmọ Sádókù,+ àwọn tí ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún mi, àwọn tí kò rìn gbéregbère lọ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn gbéregbère lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Léfì ti rìn gbéregbère lọ.+
12 Wọn yóò sì ní ọrẹ láti inú ọrẹ ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ jù lọ, ní ààlà àwọn ọmọ Léfì.+
13 “Àwọn ọmọ Léfì yóò sì ní+ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní fífẹ̀, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpínlẹ̀ àwọn àlùfáà gan-gan; gbogbo gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, fífẹ̀ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá.+
14 Wọn kò sì gbọ́dọ̀ ta èyíkéyìí nínú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ fi ṣe pàṣípààrọ̀, ẹnì kankan kò sì gbọ́dọ̀ mú kí ààyò jù lọ nínú ilẹ̀ náà kọjá kúrò lọ́wọ́ wọn; nítorí ohun mímọ́ ni lójú Jèhófà.+
15 “Ní ti ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní fífẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó jẹ́ ohun kan tí a sọ di àìmọ́ fún ìlú ńlá náà,+ fún ibi gbígbé àti fún ilẹ̀ ìjẹko. Ilú ńlá náà yóò sì wà ní àárín rẹ̀.+
16 Ìwọ̀nyí sì ni ìwọ̀n ìlú ńlá náà: ojú ààlà ti àríwá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún ìgbọ̀nwọ́, àti ojú ààlà ti gúúsù, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún, àti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún, àti ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún.
17 Ìlú ńlá náà yóò sì ní ilẹ̀ ìjẹko,+ níhà àríwá, àádọ́ta-lérúgba ìgbọ̀nwọ́, àti níhà gúúsù, àádọ́ta-lérúgba, àti níhà ìlà-oòrùn, àádọ́ta-lérúgba, àti níhà ìwọ̀-oòrùn, àádọ́ta-lérúgba.
18 “Ohun tí ó sì ṣẹ́ kù sílẹ̀ ní gígùn yóò jẹ́ bákan náà gẹ́lẹ́ bí ọrẹ mímọ́,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìgbọ̀nwọ́ níhà ìlà-oòrùn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá níhà ìwọ̀-oòrùn; yóò sì jẹ́ bákan náà gẹ́lẹ́ bí ọrẹ mímọ́, èso rẹ̀ yóò sì wà fún oúnjẹ fún àwọn tí ń sin ìlú ńlá náà.+
19 Àwọn tí ń sin ìlú ńlá náà láti inú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò sì máa ro ó.+
20 “Gbogbo ọrẹ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ níbùú, ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lóòró. Ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ́gbọọgba ni kí ẹ fi ṣe ìtọrẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ pẹ̀lú ohun ìní ìlú ńlá náà.
21 “Ohun tí ó bá sì ṣẹ́ kù sílẹ̀ yóò jẹ́ ti ìjòyè náà,+ ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún ọrẹ mímọ́ àti ti ohun ìní ìlú ńlá náà,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ọrẹ náà dé ààlà ti ìlà-oòrùn; àti ní ìwọ̀-oòrùn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ náà dé ààlà ti ìwọ̀-oòrùn.+ Bákan náà gẹ́lẹ́ bí ti àwọn ìpín náà, ni yóò jẹ́ fún ìjòyè náà. Ọrẹ mímọ́ àti ibùjọsìn Ilé náà yóò sì wà ní àárín rẹ̀.
22 “Àti ní ti ohun ìní àwọn ọmọ Léfì àti ohun ìní ìlú ńlá náà, láàárín ohun tí ó jẹ́ ti ìjòyè náà ni kí ó wà. Àárín ààlà Júdà+ àti ààlà Bẹ́ńjámínì ni kí ó jẹ́ ti ìjòyè náà.
23 “Àti ní ti àwọn ẹ̀yà yòókù, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ìpín kan fún Bẹ́ńjámínì.+
24 Àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Bẹ́ńjámínì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Síméónì.+
25 Àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Síméónì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Ísákárì.+
26 Àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Ísákárì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Sébúlúnì.+
27 Àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Sébúlúnì, láti ojú ààlà ti ìlà-oòrùn dé ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn, ọ̀kan fún Gádì.+
28 Àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Gádì, dé ojú ààlà ti gúúsù, yóò jẹ́ síhà gúúsù; ààlà náà yóò sì jẹ́ láti Támárì+ dé omi Mẹriba-kádéṣì,+ dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá náà,+ títí dé Òkun Ńlá.+
29 “Èyí ni yóò jẹ́ ilẹ̀ náà tí ẹ óò mú kí ó tipa kèké ṣíṣẹ́ di ogún àwọn ẹ̀yà Isírẹ́lì,+ ìwọ̀nyí ni yóò sì jẹ́ ìpín wọn,”+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.
30 “Ìwọ̀nyí ni yóò sì jẹ́ ibi ìgbàjáde ìlú ńlá náà: Ní ojú ààlà ti àríwá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún ìgbọ̀nwọ́ ni ìwọ̀n náà yóò jẹ́.+
31 “Àwọn ẹnubodè ìlú ńlá náà yóò sì jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ẹnubodè mẹ́ta wà ní àríwá, ẹnubodè Rúbẹ́nì, ọ̀kan; ẹnubodè Júdà, ọ̀kan; ẹnubodè Léfì, ọ̀kan.
32 “Àti ní ojú ààlà ti ìlà-oòrùn, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún ìgbọ̀nwọ́ ni yóò wà, àti ẹnubodè mẹ́ta, àní ẹnubodè Jósẹ́fù, ọ̀kan; ẹnubodè Bẹ́ńjámínì, ọ̀kan; ẹnubodè Dánì, ọ̀kan.
33 “Ojú ààlà ti gúúsù yóò sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún ìgbọ̀nwọ́ ní ti ìwọ̀n, pẹ̀lú ẹnubodè mẹ́ta, ẹnubodè Síméónì, ọ̀kan; ẹnubodè Ísákárì, ọ̀kan; ẹnubodè Sébúlúnì, ọ̀kan.
34 “Ojú ààlà ti ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlélógún ìgbọ̀nwọ́, ẹnubodè mẹ́ta ni ó wà níbẹ̀, ẹnubodè Gádì, ọ̀kan; ẹnubodè Áṣérì, ọ̀kan; ẹnubodè Náfútálì, ọ̀kan.
35 “Ẹgbàásàn-án ìgbọ̀nwọ́ ni yóò wà yí ká; orúkọ ìlú ńlá náà láti ọjọ́ yẹn lọ yóò sì máa jẹ́ Jèhófà Alára Wà Níbẹ̀.”+