Òwe 10:1-32

10  Òwe Sólómọ́nì.+ Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ẹni tí ń mú kí baba yọ̀,+ arìndìn ọmọ sì ni ẹ̀dùn-ọkàn ìyá rẹ̀.+  Àwọn ìṣúra ẹni burúkú kì yóò ṣàǹfààní,+ ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.+  Jèhófà kì yóò jẹ́ kí ebi pa ọkàn olódodo,+ ṣùgbọ́n ìfàsí-ọkàn àwọn ẹni burúkú ni yóò tì kúrò.+  Ẹni tí ń fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ ṣiṣẹ́ yóò jẹ́ aláìnílọ́wọ́,+ ṣùgbọ́n ọwọ́ ẹni aláápọn ni yóò sọni di ọlọ́rọ̀.+  Ọmọ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà ń kó jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú sùn lọ fọnfọn nígbà ìkórè.+  Ìbùkún wà fún orí olódodo,+ ṣùgbọ́n ní ti ẹnu àwọn ẹni burúkú, ó ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.+  Ìrántí olódodo ni a ó bù kún,+ ṣùgbọ́n orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.+  Ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà yóò tẹ́wọ́ gba àwọn àṣẹ,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ òmùgọ̀ ní ètè rẹ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+  Ẹni tí ó bá ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe àwọn ọ̀nà ara rẹ̀ ní wíwọ́ yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀.+ 10  Ẹni tí ń ṣẹ́jú yóò ṣokùnfà ìrora,+ ẹni tí ó sì jẹ́ òmùgọ̀ ní ètè rẹ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+ 11  Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè;+ ṣùgbọ́n ní ti ẹnu àwọn ẹni burúkú, ó ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.+ 12  Ìkórìíra ní ń ru asọ̀ sókè,+ ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo ìrélànàkọjá pàápàá mọ́lẹ̀.+ 13  Ètè olóye ni a ti ń rí ọgbọ́n,+ ṣùgbọ́n ọ̀pá ni fún ẹ̀yìn ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.+ 14  Àwọn ọlọ́gbọ́n ni ó ń fi ìmọ̀ ṣúra,+ ṣùgbọ́n ẹnu òmùgọ̀ sún mọ́ ìparun.+ 15  Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀.+ Ìparun àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ni ipò òṣì wọn.+ 16  Ìgbòkègbodò olódodo ń yọrí sí ìyè;+ èso ẹni burúkú ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.+ 17  Ẹni tí ó rọ̀ mọ́ ìbáwí jẹ́ ipa ọ̀nà sí ìyè,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sílẹ̀ ń fa rírìn gbéregbère.+ 18  Níbi tí ẹni tí ń bo ìkórìíra mọ́lẹ̀ bá wà, níbẹ̀ ni ètè èké wà,+ ẹni tí ó sì ń mú ìròyìn búburú wá jẹ́ arìndìn.+ 19  Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá,+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.+ 20  Ahọ́n olódodo jẹ́ ààyò fàdákà;+ ọkàn-àyà ẹni burúkú kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí.+ 21  Àní ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀,+ ṣùgbọ́n àwọn òmùgọ̀ ń kú nítorí tí ọkàn-àyà kù fún wọn.+ 22  Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀,+ kì í sì í fi ìrora kún un.+ 23  Sí arìndìn, bíbá a lọ ní híhu ìwà àìníjàánu dà bí ìdárayá,+ ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà fún ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀.+ 24  Ohun tí ń da jìnnìjìnnì bo ẹni burúkú—èyíinì ni ohun tí yóò dé bá a;+ ṣùgbọ́n ìfẹ́-ọkàn àwọn olódodo ni a ó yọ̀ǹda fún wọn.+ 25  Bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù oníjì ré kọjá, bẹ́ẹ̀ ni ẹni burúkú kò ní sí mọ́;+ ṣùgbọ́n olódodo jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 26  Bí ọtí kíkan sí eyín àti èéfín sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí àwọn tí ó rán an jáde.+ 27  Àní ìbẹ̀rù Jèhófà yóò fi kún àwọn ọjọ́,+ ṣùgbọ́n àwọn ọdún tí ó jẹ́ ti àwọn ẹni burúkú ni a óò ké kúrú.+ 28  Ìfojúsọ́nà àwọn olódodo jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀,+ ṣùgbọ́n ìrètí àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+ 29  Ọ̀nà Jèhófà jẹ́ odi agbára fún aláìlẹ́bi,+ ṣùgbọ́n ìparun ń bẹ fún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.+ 30  Ní ti olódodo, fún àkókò tí ó lọ kánrin, a kì yóò mú kí ó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́;+ ṣùgbọ́n ní ti àwọn ẹni burúkú, wọn kì yóò máa bá a nìṣó ní gbígbé orí ilẹ̀ ayé.+ 31  Ẹnu olódodo—ó ń so èso ọgbọ́n,+ ṣùgbọ́n ahọ́n àyídáyidà ni a óò ké kúrò.+ 32  Ètè olódodo—ó wá mọ ìfẹ́ rere,+ ṣùgbọ́n ẹnu àwọn ẹni burúkú jẹ́ àyídáyidà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé