Òwe 23:1-35
23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ jókòó láti bá ọba jẹun, kí o ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa ohun tí ó wà níwájú rẹ,+
2 kí o sì fi ọ̀bẹ sí ara rẹ lọ́fun, bí ìwọ bá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó gba gbogbo ọkàn.+
3 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí àwọn oúnjẹ rẹ̀ olóyinmọmọ, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ oúnjẹ irọ́.+
4 Má ṣe làálàá láti jèrè ọrọ̀.+ Ṣíwọ́ kúrò nínú òye ara rẹ.+
5 Ìwọ ha ti jẹ́ kí ojú rẹ wò ó fìrí bí, nígbà tí kò jámọ́ nǹkan kan?+ Nítorí láìsí àní-àní, ó máa ń ṣe ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ bí ti idì, a sì fò lọ sí ojú ọ̀run.+
6 Má fi oúnjẹ ẹni tí ó jẹ́ aláìní ojú àánú bọ́ ara rẹ,+ tàbí kí o jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí àwọn oúnjẹ rẹ̀ olóyinmọmọ.+
7 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti gbéṣirò lé e nínú ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun rí.+ “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó sọ fún ọ, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà rẹ̀ kò wà pẹ̀lú rẹ.+
8 Òkèlè rẹ tí o ti jẹ, ìwọ yóò pọ̀ ọ́, ìwọ yóò sì ti fi àwọn ọ̀rọ̀ dídùn rẹ ṣòfò.+
9 Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí arìndìn,+ nítorí yóò tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ tí ó jẹ́ ti òye.+
10 Má ṣe sún ààlà àtọjọ́mọ́jọ́ sẹ́yìn,+ má sì wọnú pápá àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba.+
11 Nítorí pé Olùtúnniràpadà wọn lágbára; òun fúnra rẹ̀ yóò gba ẹjọ́ wọn rò pẹ̀lú rẹ.+
12 Mú ọkàn-àyà rẹ wá fún ìbáwí àti etí rẹ fún àwọn àsọjáde ìmọ̀.+
13 Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn fún ọmọdékùnrin.+ Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o fi ọ̀pá nà án, kì yóò kú.
14 Kí ìwọ fi ọ̀pá nà án, kí o lè dá ọkàn rẹ̀ gan-an nídè kúrò lọ́wọ́ Ṣìọ́ọ̀lù.+
15 Ọmọ mi, bí ọkàn-àyà rẹ bá gbọ́n,+ ọkàn-àyà mi yóò yọ̀, àní tèmi.+
16 Àwọn kíndìnrín mi yóò sì yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí ètè rẹ bá sọ̀rọ̀ ìdúróṣánṣán.+
17 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+ ṣùgbọ́n kí o bẹ̀rù Jèhófà láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+
18 Nítorí bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ọjọ́ ọ̀la yóò wà,+ a kì yóò sì ké ìrètí rẹ kúrò.+
19 Ìwọ, ọmọ mi, gbọ́, kí o sì di ọlọ́gbọ́n, kí o sì máa ṣamọ̀nà ọkàn-àyà rẹ nìṣó ní ọ̀nà.+
20 Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri,+ lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì.+
21 Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì,+ àkísà lásán-làsàn sì ni ìṣesùẹ̀sùẹ̀ yóò fi wọ ènìyàn.+
22 Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ,+ má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.+
23 Ra òtítọ́,+ má sì tà á—ọgbọ́n àti ìbáwí àti òye.+
24 Baba olódodo yóò kún fún ìdùnnú láìsí àní-àní;+ ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n yóò yọ̀ pẹ̀lú nínú rẹ̀.+
25 Baba rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, obìnrin tí ó bí ọ yóò sì kún fún ìdùnnú.+
26 Ọmọ mi, fi ọkàn-àyà rẹ fún mi, kí àwọn ojú tìrẹ wọ̀nyẹn sì ní ìdùnnú sí àwọn ọ̀nà tèmi.+
27 Nítorí pé kòtò jíjìn ni kárùwà,+ kànga tóóró sì ni obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.
28 Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́ṣà, ó máa ń lúgọ deni;+ ó sì máa ń mú àwọn aládàkàdekè pọ̀ sí i láàárín àwọn ènìyàn.+
29 Ta ni ó ni ègbé? Ta ni ó ni àìnírọ̀rùn? Ta ni ó ni asọ̀?+ Ta ni ó ni ìdàníyàn? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ni ó ni ojú ṣíṣe bàìbàì?
30 Àwọn tí ó máa ń dúró fún àkókò gígùn nídìí wáìnì ni,+ àwọn tí ń wọlé láti wá àdàlù wáìnì kàn.+
31 Má wo wáìnì nígbà tí ó bá yọ àwọ̀ pupa, nígbà tí ó bá ń ta wíríwírí nínú ife, nígbà tí ó bá ń lọ tìnrín.
32 Ní òpin rẹ̀, a buni ṣán gẹ́gẹ́ bí ejò,+ a sì tu oró jáde gẹ́gẹ́ bí paramọ́lẹ̀.+
33 Ojú ìwọ fúnra rẹ yóò rí àwọn ohun àjèjì, ọkàn-àyà rẹ yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà.+
34 Dájúdájú, ìwọ yóò dà bí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ sí àárín òkun, àní bí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ sí orí òpó ìgbòkun ọkọ̀.+
35 “Wọ́n gbá mi, ṣùgbọ́n àìsàn kò ṣe mí; wọ́n fi agbára lù mí, ṣùgbọ́n èmi kò mọ̀. Ìgbà wo ni èmi yóò jí?+ Èmi yóò ṣì túbọ̀ máa wá a kiri.”+