Òwe 27:1-27

27  Má ṣògo nípa ọ̀la,+ nítorí ìwọ kò mọ ohun tí ọjọ́ kan yóò bí.+  Àjèjì ni kí ó yìn ọ́, kí ó má ṣe jẹ́ ẹnu ìwọ fúnra rẹ; ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, kí ó má ṣe jẹ́ ètè ìwọ fúnra rẹ.+  Ìwúwo òkúta àti ẹrù iyanrìn+—ṣùgbọ́n ìbínú láti ọ̀dọ̀ òmùgọ̀ wúwo ju àwọn méjèèjì lọ.+  Ìwà ìkà ti ìhónú ń bẹ, àti àkúnya ìbínú pẹ̀lú,+ ṣùgbọ́n ta ní lè dúró níwájú owú?+  Ìbáwí àfitọ́nisọ́nà tí a fi hàn síta+ sàn ju ìfẹ́ tí a fi pa mọ́.  Àwọn ọgbẹ́ tí olùfẹ́ dá síni lára jẹ́ ti ìṣòtítọ́,+ ṣùgbọ́n àwọn ìfẹnukonu olùkórìíra jẹ́ ohun tí a ó pàrọwà fún.+  Ọkàn tí ó yó a tẹ afárá oyin mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n fún ọkàn tí ebi ń pa gbogbo ohun kíkorò ni ó dùn.+  Gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ tí ń fò lọ kúrò ní ìtẹ́ rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí ń sá lọ kúrò ní ipò rẹ̀.+  Òróró àti tùràrí+ ni ohun tí ń mú kí ọkàn-àyà yọ̀, bákan náà ni dídùn alábàákẹ́gbẹ́ ẹni jẹ́ nítorí ìmọ̀ràn ọkàn.+ 10  Má fi alábàákẹ́gbẹ́ tìrẹ sílẹ̀ tàbí alábàákẹ́gbẹ́ baba rẹ, má sì wọ ilé arákùnrin tìrẹ ní ọjọ́ àjálù rẹ. Aládùúgbò tí ó wà nítòsí sàn ju arákùnrin tí ó jìnnà réré.+ 11  Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀,+ kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.+ 12  Afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù ti fi ara rẹ̀ pa mọ́;+ aláìní ìrírí tí ó ti gba ibẹ̀ kọjá ti jìyà àbájáde rẹ̀.+ 13  Gba ẹ̀wù rẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹni náà lọ ṣe onídùúró fún àjèjì;+ àti nínú ọ̀ràn obìnrin ilẹ̀ òkèèrè, fi ipá gba ohun ìdógò lọ́wọ́ ọkùnrin náà.+ 14  Ẹni tí ń fi ohùn rara súre fún ọmọnìkejì rẹ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ìfiré ni a ó kà á sí níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.+ 15  Òrùlé jíjò tí ń léni lọ ní ọjọ́ òjò àrọ̀-ìdá àti aya alásọ̀ ṣeé fi wéra.+ 16  Ẹnikẹ́ni tí ó bá pèsè ibi ààbò fún un pèsè ibi ààbò fún ẹ̀fúùfù, òróró sì ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ bá pàdé. 17  Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.+ 18  Ẹni tí ó bá ń fi ìṣọ́ ṣọ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, òun alára yóò jẹ èso rẹ̀,+ ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ọ̀gá rẹ̀ sì ni a ó bọlá fún.+ 19  Bí ojú ti ń bá ojú ṣe rẹ́gí nínú omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn-àyà ènìyàn sí ènìyàn. 20  Ṣìọ́ọ̀lù àti ibi ìparun+ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn;+ bẹ́ẹ̀ ni ojú ènìyàn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.+ 21  Ìkòkò ìyọ́hunmọ́ wà fún fàdákà,+ ìléru sì wà fún wúrà;+ ẹnì kọ̀ọ̀kan sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyìn rẹ̀.+ 22  Bí o bá tilẹ̀ fi ọmọrí odó gún òmùgọ̀ kúnná nínú odó, láàárín ọkà tí a ti pa, ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kì yóò fi í sílẹ̀.+ 23  Ó yẹ kí o mọ ìrísí agbo ẹran rẹ ní àmọ̀dunjú. Fi ọkàn-àyà rẹ sí àwọn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ;+ 24  nítorí ìṣúra kì yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ bẹ́ẹ̀ ni adé dáyádémà kì yóò wà jálẹ̀ ìran-ìran. 25  Koríko tútù ti lọ, koríko tuntun sì ti fara hàn, a sì ti kó ewéko àwọn òkè ńlá jọ.+ 26  Àwọn ẹgbọrọ àgbò ń bẹ fún aṣọ rẹ,+ àwọn òbúkọ sì ni iye owó pápá. 27  Wàrà ewúrẹ́ tí ó pọ̀ tó sì ń bẹ fún oúnjẹ rẹ, fún oúnjẹ agbo ilé rẹ, àti àlùmọ́ọ́nì+ ìgbésí ayé fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin rẹ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé