Òwe 7:1-27

7  Ọmọ mi, pa àwọn àsọjáde mi mọ́,+ kí o sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ.+  Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè,+ àti òfin mi bí ọmọlójú rẹ.+  So wọ́n mọ́ ìka rẹ,+ kí o sì kọ wọ́n sára wàláà ọkàn-àyà rẹ.+  Sọ fún ọgbọ́n+ pé: “Arábìnrin mi ni ọ́”; kí o sì pe òye ní “Ẹbí mi obìnrin,”  láti máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ obìnrin tí ó jẹ́ àjèjì,+ lọ́wọ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti mú kí àwọn àsọjáde rẹ̀ dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in.+  Nítorí lójú fèrèsé ilé mi, láti àárín àgánrándì fèrèsé+ mi ni mo ti bojú wolẹ̀,  kí èmi lè tẹjú mọ́ àwọn aláìní ìrírí.+ Mo ní ọkàn-ìfẹ́ nínú fífi òye mọ ọ̀dọ́kùnrin tí ọkàn-àyà kù fún nínú àwọn ọmọkùnrin,+  tí ó ń kọjá lọ ní ojú pópó nítòsí igun ọ̀nà rẹ̀, ọ̀nà tí ó lọ sí ilé rẹ̀ ni ó sì gbà lọ,+  ní wíríwírí ọjọ́, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́,+ nígbà dídé òru àti ìṣúdùdù. 10  Sì wò ó! obìnrin kan ń bẹ tí ó fẹ́ pàdé rẹ̀, nínú ẹ̀wù kárùwà+ àti àlùmọ̀kọ́rọ́yí ọkàn-àyà. 11  Ó jẹ́ aláriwo líle àti alágídí.+ Ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í gbé ilé rẹ̀.+ 12  Nísinsìnyí, ó wà lóde, nísinsìnyí, ó wà ní àwọn ojúde ìlú,+ nítòsí gbogbo igun ọ̀nà sì ni ó ń lúgọ sí.+ 13  Obìnrin náà sì rá a mú, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+ Ó sì mójú kuku, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: 14  “Àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ já lé mi léjìká.+ Òní ni mo san àwọn ẹ̀jẹ́ mi.+ 15  Ìdí nìyẹn tí mo fi jáde wá pàdé rẹ, láti wá ojú rẹ, kí n lè rí ọ. 16  Mo ti fi àwọn aṣọ ìtẹ́lébùsùn ṣe ọ̀ṣọ́ fún àga ìnàyìn mi, pẹ̀lú àwọn ohun tí ó jẹ́ kàlákìnní, aṣọ ọ̀gbọ̀ Íjíbítì.+ 17  Mo ti fi òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn mi.+ 18  Wá, jẹ́ kí a mu ìfẹ́ ní àmuyó títí di òwúrọ̀; jẹ́ kí a fi àwọn ìfihàn ìfẹ́ gbádùn ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.+ 19  Nítorí ọkọ kò sí ní ilé rẹ̀; ó ti rin ìrìn àjò lọ sí ọ̀nà tí ó jìn.+ 20  Ó mú àpò owó lọ́wọ́. Ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú ni yóò wá sí ilé rẹ̀.” 21  Ó ti fi ọ̀pọ̀ yanturu ìyíniléròpadà rẹ̀ ṣì í lọ́nà.+ Ó fi dídùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ètè rẹ̀ sún un dẹ́ṣẹ̀.+ 22  Lójijì, ó ń tọ obìnrin náà lẹ́yìn,+ bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa, àti gan-an gẹ́gẹ́ bí pé a fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dì í fún ìbáwí òmùgọ̀ ènìyàn, 23  títí ọfà fi la ẹ̀dọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ṣe kánkán sínú pańpẹ́,+ kò sì mọ̀ pé ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.+ 24  Wàyí o, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi, kí ẹ sì fiyè sí àwọn àsọjáde ẹnu mi.+ 25  Kí ọkàn-àyà rẹ má yà sí àwọn ọ̀nà obìnrin náà. Má rìn gbéregbère wọ àwọn òpópónà rẹ̀.+ 26  Nítorí ọ̀pọ̀ ni àwọn tí ó ti mú ṣubú lulẹ̀ ní òkú,+ gbogbo àwọn tí a ti ọwọ́ rẹ̀ pa sì pọ̀ níye.+ 27  Àwọn ọ̀nà sí Ṣìọ́ọ̀lù ni ilé+ rẹ̀ jẹ́; wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún ti ikú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé