1 Kíróníkà 5:1-26

5  Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì+ àkọ́bí Ísírẹ́lì—nítorí òun ni àkọ́bí;+ ṣùgbọ́n nítorí sísọ tí ó sọ àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ baba rẹ̀ di aláìmọ́,+ ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí ni a fi fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù+ ọmọkùnrin Ísírẹ́lì, tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò kọ ọrúkọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé fún ẹ̀tọ́ àkọ́bí.  Nítorí Júdà+ ga lọ́lá ju èyíkéyìí láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ẹni tí ó jẹ́ aṣáájú ti wá;+ ṣùgbọ́n Jósẹ́fù ni ó ni ẹ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+  àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì sì ni Hánókù+ àti Pálù,+ Hésírónì àti Kámì.+  Àwọn ọmọkùnrin Jóẹ́lì ni Ṣemáyà ọmọkùnrin rẹ̀, Gọ́ọ̀gù ọmọkùnrin rẹ̀, Ṣíméì ọmọkùnrin rẹ̀,  Míkà ọmọkùnrin rẹ̀, Reáyà ọmọkùnrin rẹ̀, Báálì ọmọkùnrin rẹ̀,  Bééráhì ọmọkùnrin rẹ̀, ẹni tí Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà mú lọ sí ìgbèkùn, ó jẹ́ ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì.  Àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn nínú àkọsílẹ̀ orúkọ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé+ nípa ọmọ ìran wọn, gẹ́gẹ́ bí olórí, sì ni Jéélì, àti Sekaráyà,  àti Bélà ọmọkùnrin Ásásì ọmọkùnrin Ṣémà ọmọkùnrin Jóẹ́lì+—ó ń gbé ní Áróérì+ àti títí dé Nébò+ àti Baali-méónì.+  Àní síhà ìlà-oòrùn, ó ń gbé títí lọ dé àtiwọ aginjù ní Odò Yúfírétì,+ nítorí tí ohun ọ̀sìn wọ́n ti di púpọ̀ níye ní ilẹ̀ Gílíádì.+ 10  Ní àwọn ọjọ́ Sọ́ọ̀lù, wọ́n gbógun ti àwọn ọmọ Hágárì,+ àwọn tí ó wá ṣubú nípa ọwọ́ wọn; nítorí náà, wọ́n ń gbé nínú àwọn àgọ́ wọn jálẹ̀ gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìlà-oòrùn Gílíádì. 11  Ní ti àwọn ọmọ Gádì+ ní iwájú wọn, wọ́n ń gbé ní ilẹ̀ Báṣánì+ títí dé Sálékà.+ 12  Jóẹ́lì ni olórí, Ṣáfámù sì ni igbá-kejì, àti Jánáì àti Ṣáfátì ní Báṣánì. 13  Àwọn arákùnrin wọn tí ó jẹ́ ti ilé àwọn baba ńlá wọn sì ni Máíkẹ́lì àti Méṣúlámù àti Ṣébà àti Jóráì àti Jákánì àti Sáyà àti Ébérì, méje. 14  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Ábíháílì ọmọkùnrin Húúrì, ọmọkùnrin Járóà, ọmọkùnrin Gílíádì, ọmọkùnrin Máíkẹ́lì, ọmọkùnrin Jéṣíṣáì, ọmọkùnrin Jádò, ọmọkùnrin Búsì; 15  Áhì ọmọkùnrin Ábídíélì, ọmọkùnrin Gúnì, olórí ilé àwọn baba ńlá wọn. 16  Wọ́n sì ń bá a lọ láti máa gbé ní Gílíádì,+ ní Báṣánì+ àti ní àwọn àrọko rẹ̀+ àti ní gbogbo àwọn ilẹ̀ ìjẹko Ṣárónì títí dé ibi ìdópinsí wọn. 17  Gbogbo wọn ni a kọrúkọ wọn sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn ìlà ìdílé ní àwọn ọjọ́ Jótámù+ ọba Júdà àti ní àwọn ọjọ́ Jèróbóámù+ ọba Ísírẹ́lì. 18  Ní ti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè; lára àwọn tí wọ́n jẹ́ akíkanjú,+ àwọn ọkùnrin tí ń gbé apata àti idà tí wọ́n sì ń fa ọrun tí a sì kọ́ ní iṣẹ́ ogun, ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún ó dín ogójì ni ó wà tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ 19  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ọmọ Hágárì,+ àti Jétúrì+ àti Náfíṣì+ àti Nódábù. 20  A sì ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìdojú-ìjà-kọ wọ́n, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọmọ Hágárì àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn ni a fi lé wọn lọ́wọ́, nítorí pé Ọlọ́run ni wọ́n ké pè fún ìrànlọ́wọ́+ nínú ogun náà, ó sì jẹ́ kí a pàrọwà sí òun fún ire wọn nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e.+ 21  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ohun ọ̀sìn+ wọn ní òǹdè, ràkúnmí wọn ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàáàrún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ọkàn tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn.+ 22  Nítorí pé ọ̀pọ̀ ni ó ti ṣubú sílẹ̀ ní òkú, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ni ìjà náà.+ Wọ́n sì ń bá a lọ láti máa gbé ní àyè wọn títí di ìgbà ìgbèkùn.+ 23  Ní ti àwọn ọmọ ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè,+ wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà láti Báṣánì+ dé Baali-hámónì+ àti Sénírì+ àti Òkè Ńlá Hámónì.+ Àwọn fúnra wọn di púpọ̀ níye. 24  Ìwọ̀nyí sì ni olórí ilé àwọn baba ńlá wọn: Éférì àti Íṣì àti Élíélì àti Ásíríẹ́lì àti Jeremáyà àti Hodafáyà àti Jádíẹ́lì, àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ akíkanjú, alágbára ńlá, àwọn ọkùnrin olókìkí, àwọn olórí ilé baba ńlá wọn. 25  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, wọ́n sì lọ ń ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe+ pẹ̀lú àwọn ọlọ́run+ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí Ọlọ́run ti pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú wọn. 26  Nítorí náà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ru ẹ̀mí+ Púlì+ ọba Ásíríà+ sókè, àní ẹ̀mí Tiliga-pílínésà+ ọba Ásíríà, tí ó fi kó àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Rúbẹ́nì àti ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè lọ sí ìgbèkùn+ tí ó sì kó wọn wá sí Hálà+ àti Hábórì àti Hárà àti Odò Gósánì láti máa wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé