1 Sámúẹ́lì 10:1-27
10 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ṣágo+ òróró, ó sì dà á sí orí rẹ̀, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu,+ ó sì wí pé: “Kì í ha ṣe nítorí pé Jèhófà ti fòróró yàn ọ́ ṣe aṣáájú+ lórí ogún+ rẹ̀ ni bí?
2 Bí o ti ń lọ kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, dájúdájú, ìwọ yóò rí ọkùnrin méjì nítòsí ibojì Rákélì+ ní ìpínlẹ̀ Bẹ́ńjámínì ní Sélésà, dájúdájú, wọn yóò sì sọ fún ọ pé ‘A ti rí àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí o wá lọ ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, baba rẹ ti jáwọ́ nínú ọ̀ràn àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ náà, ó sì ń ṣàníyàn nípa yín, ó wí pé: “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọkùnrin mi?”’+
3 Ìwọ yóò sì kọjá lọ láti ibẹ̀ síwájú sí í, ìwọ yóò sì lọ títí dé ibi igi ńlá Tábórì, ọkùnrin mẹ́ta tí ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ ní Bẹ́tẹ́lì+ yóò sì bá ọ pàdé níbẹ̀, ọ̀kan gbé ọmọ ẹran mẹ́ta,+ ọ̀kan gbé ìṣù búrẹ́dì ribiti mẹ́ta,+ ọ̀kan sì gbé ìṣà wáìnì títóbi kan.+
4 Dájúdájú, wọn yóò sì béèrè àlàáfíà rẹ,+ wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù búrẹ́dì méjì , kí o gbà á lọ́wọ́ wọn.
5 Lẹ́yìn ìyẹn ni ìwọ yóò dé òkè kékeré Ọlọ́run tòótọ́,+ níbi tí ẹgbẹ́ ogun+ àwọn Filísínì wà. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí o bá ń bọ̀ níbẹ̀ sí ìlú ńlá, dájúdájú, ìwọ yóò pàdé àwùjọ àwọn wòlíì+ tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ibi gíga,+ ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti ìlù tanboríìnì+ àti fèrè+ àti háàpù+ sì wà níwájú wọn, bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì.
6 Dájúdájú, ẹ̀mí+ Jèhófà yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ, dájúdájú, ìwọ pa pọ̀ pẹ̀lú wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì,+ a ó sì yí ọ padà di ènìyàn mìíràn.
7 Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àmì+ wọ̀nyí bá dé sí ọ, kí o ṣe ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí pé ó ṣeé ṣe+ fún ara rẹ, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú rẹ.+
8 Kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ ṣáájú mi sí Gílígálì;+ sì wò ó! èmi yóò sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú àwọn ẹbọ sísun, láti rú àwọn ẹbọ ìdàpọ̀.+ Ọjọ́ méje+ ni kí o fi dúró títí èmi yóò fi tọ̀ ọ́ wá, dájúdájú, èmi yóò sì jẹ́ kí o mọ ohun ti ìwọ yóò ṣe.”
9 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó yí èjì ká rẹ̀ láti lọ kúrò lọ́dọ̀ Sámúẹ́lì, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí yí ọkàn-àyà rẹ̀ padà di òmíràn;+ gbogbo àmì+ wọ̀nyí sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ ní ọjọ́ yẹn.
10 Nítorí náà, wọ́n lọ láti ibẹ̀ sí òkè kékeré náà, sì kíyè sí i, àwùjọ àwọn wòlíì wà níbẹ̀ láti pàdé rẹ̀; ní kíá, ẹ̀mí Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí i ṣiṣẹ́ lára rẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì+ ní àárín wọn.
11 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i, wò ó! òun pẹ̀lú àwọn wòlíì ni wọ́n jọ ń sọ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Kí ni èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin Kíṣì? Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú ha wà lára àwọn wòlíì bí?”+
12 Nígbà náà ni ọkùnrin kan láti ibẹ̀ dáhùn, ó sì wí pé: “Ṣùgbọ́n ta ni baba wọn?” Ìdí nìyẹn tí ó fi di ọ̀rọ̀ òwe+ pé: “Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú ha wà lára àwọn wòlíì bí?”
13 Níkẹyìn, ó parí sísọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì, ó sì wá sí ibi gíga náà.
14 Lẹ́yìn náà, arákùnrin baba Sọ́ọ̀lù sọ fún òun àti fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Ibo ni ẹ lọ?” Látàrí ìyẹn, ó wí pé: “Láti wá àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,+ a sì ń bá a nìṣó ní lílọ láti wá wọn, ṣùgbọ́n wọn kò sí níbẹ̀. Nítorí náà, a tọ Sámúẹ́lì lọ.”
15 Látàrí èyí, arákùnrin òbí Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún mi, Kí ni Sámúẹ́lì sọ fún yín?”
16 Ẹ̀wẹ̀, Sọ́ọ̀lù sọ fún arákùnrin òbí rẹ̀ pé: “Ó sọ fún wa, láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, pé wọ́n ti rí àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ọ̀ràn nípa ipò ọba, èyí tí Sámúẹ́lì ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ni kò sì sọ fún un.+
17 Sámúẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí pe àwọn ènìyàn náà jọ sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà,+
18 ó sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,+ ‘Èmi ni ó mú Ísírẹ́lì gòkè wá láti Íjíbítì, tí ó sì dá yín nídè kúrò lọ́wọ́ Íjíbítì+ àti kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìjọba tí ó ń ni yín lára.+
19 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin—lónìí, ẹ ti kọ Ọlọ́run yín+ ẹni tí ó jẹ́ olùgbàlà fún yín kúrò nínú gbogbo ibi yín àti àwọn wàhálà yín, ẹ sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ọba ni kí o fi jẹ lórí wa.” Wàyí o, ẹ mú ìdúró yín níwájú Jèhófà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà+ yín àti ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún yín.’”
20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Sámúẹ́lì mú kí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sún mọ́ tòsí,+ a sì mú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.+
21 Lẹ́yìn náà, ó mú kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sún mọ́ tòsí nípa àwọn ìdílé rẹ̀, a sì mú ìdílé àwọn Mátírì.+ Níkẹyìn, a mú Sọ́ọ̀lù ọmọkùnrin Kíṣì.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá a kiri, a kò sì rí i.
22 Nítorí náà, wọ́n wádìí+ síwájú sí i lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ọkùnrin náà ha ti dé síbí nísinsìnyí bí?” Jèhófà fèsì pé: “Òun rèé, tí ó fara pa mọ́+ sáàárín ẹrù àjò.”
23 Nítorí náà, wọ́n sáré, wọ́n sì mú un láti ibẹ̀. Nígbà tí ó mú ìdúró rẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn náà, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn yòókù lọ láti èjì ká rẹ̀ sókè.+
24 Nígbà náà ni Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Ṣé ẹ rí ẹni tí Jèhófà yàn,+ pé kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn?” Gbogbo àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n sì wí pé: “Kí ọba kí ó pẹ́!”+
25 Látàrí ìyẹn, Sámúẹ́lì bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó tọ́ sí ipò ọba,+ ó sì kọ ọ́ sínú ìwé kan, ó si fi í lélẹ̀ níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà ni Sámúẹ́lì rán gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
26 Ní ti Sọ́ọ̀lù alára, ó lọ sí ilé rẹ̀ ní Gíbíà,+ àwọn akíkanjú ọkùnrin tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn-àyà wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a lọ.+
27 Ní ti àwọn ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun,+ wọ́n wí pé: “Báwo ni ẹni yìí yóò ṣe gbà wá là?”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n tẹ́ńbẹ́lú+ rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn èyíkéyìí wá fún un.+ Ṣùgbọ́n ó wà bí aláìlèsọ̀rọ̀.+