1 Sámúẹ́lì 17:1-58
17 Àwọn Filísínì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ibùdó wọn jọpọ̀ fún ogun. Nígbà tí a kó wọn jọpọ̀ sí Sókóhì,+ èyí tí ó jẹ́ ti Júdà, nígbà náà ni wọ́n dó sáàárín Sókóhì àti Ásékà,+ ní Efesi-dámímù.+
2 Ní ti Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀, wọ́n sì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ Éláhì,+ wọ́n sì tẹ́ ìtẹ́gun láti pàdé àwọn Filísínì.
3 Àwọn Filísínì sì dúró lórí òkè ńlá ní ìhà ìhín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dúró lórí òkè ńlá ní ìhà ọ̀hún, àfonífojì sì wà láàárín wọn.
4 Akọgun kan sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti àwọn ibùdó àwọn Filísínì, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gòláyátì,+ láti Gátì,+ gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.+
5 Àṣíborí bàbà sì wà ní orí rẹ̀, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin+ ṣe wọ̀, èyí tí ó ní àwọn ìpẹ́ agbẹ́nuléra, ìwọ̀n ẹ̀wù náà tí a fi àdàrọ irin ṣe sì jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣékélì bàbà.
6 Kóbìtà bàbà sì wà lókè ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ẹ̀ṣín+ bàbà láàárín àwọn èjì ká rẹ̀.
7 Ẹ̀rú igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì dà bí ìtì igi àwọn olófì,+ abẹ ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ṣékélì irin; ẹni tí ó gbé apata ńlá sì ń lọ níwájú rẹ̀.
8 Nígbà náà ni ó dúró jẹ́ẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí náhùn jáde sí ìlà ogun Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi jáde wá láti tẹ́ ìtẹ́gun? Kì í ha ṣe èmi ni Filísínì náà, tí ẹ̀yin sì jẹ́ ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù?+ Ẹ yan ọkùnrin kan fún ara yín, kí ẹ sì jẹ́ kí ó sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ mí wá.
9 Bí ó bá lè bá mi jà, tí ó sì ṣá mi balẹ̀, nígbà náà, àwa yóò di ìránṣẹ́ fún yín. Ṣùgbọ́n bí èmi fúnra mi bá figẹ̀ wọngẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí mo sì ṣá a balẹ̀, ẹ̀yin pẹ̀lú yóò di ìránṣẹ́ fún wa, ẹ ó sì máa sìn wá.”+
10 Filísínì náà sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Èmi fúnra mi ṣáátá+ ìlà ogun Ísírẹ́lì lónìí yìí. Ẹ fún mi ní ọkùnrin kan, kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ jà!”+
11 Nígbà tí Sọ́ọ̀lù+ àti gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Filísínì náà sọ, àyà wọ́n já, wọ́n sì fòyà gidigidi.+
12 Wàyí o, Dáfídì jẹ́ ọmọkùnrin ará Éfúrátà+ yìí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè. Ó sì ní ọmọkùnrin mẹ́jọ.+ Ní àwọn ọjọ́ Sọ́ọ̀lù, ọkùnrin náà sì ti darúgbó láàárín àwọn ènìyàn.
13 Àwọn mẹ́ta tí ó dàgbà jù lọ nínú àwọn ọmọkùnrin Jésè sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ. Wọ́n tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù lọ sí ogun,+ orúkọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó lọ sí ogun náà sì ni Élíábù+ àkọ́bí, àti Ábínádábù+ ọmọkùnrin rẹ̀ èkejì àti Ṣámáhì+ ẹ̀kẹta.
14 Dáfídì sì ni àbíkẹ́yìn,+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó dàgbà jù lọ sì tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù.
15 Dáfídì máa ń lọ, ó sì máa ń padà láti ọ̀dọ̀ Sọ́ọ̀lù láti ṣètọ́jú àgùntàn+ baba rẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
16 Filísínì náà sì ń bá a nìṣó ní jíjáde wá síwájú ní òwúrọ̀ kùtùkùtù àti ní ìrọ̀lẹ́, ó sì mú ìdúró rẹ̀ fún ogójì ọjọ́.
17 Nígbà náà ni Jésè wí fún Dáfídì ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, kó òṣùwọ̀n eéfà àyangbẹ ọkà+ yìí àti ìṣù búrẹ́dì mẹ́wàá wọ̀nyí lọ fún àwọn arákùnrin rẹ, tètè gbé wọn lọ sí ibùdó fún àwọn arakùnrin rẹ.
18 Kí o sì mú wàrà wọ̀nyí tí a pín sí ìpín mẹ́wàá lọ fún olórí ẹgbẹ̀rún;+ pẹ̀lúpẹ̀lù, kí o bójú tó àwọn arákùnrin rẹ ní ti àlàáfíà wọn,+ kí o sì gba àmì ìdánilójú kan bọ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn.”
19 Láàárín àkókò yìí, Sọ́ọ̀lù àti àwọn àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Éláhì,+ wọ́n ń bá àwọn Filísínì jà.+
20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Dáfídì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì fi àwọn àgùntàn sílẹ̀ sábẹ́ àbójútó olùtọ́jú, ó sì kó àwọn ìpèsè náà, ó sì lọ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésè ti pàṣẹ fún un.+ Nígbà tí ó dé gbàgede ibùdó,+ àwọn ẹgbẹ́ ológun ń jáde lọ síbi ìlà ogun,+ wọ́n sì kígbe sókè fún ìjà ogun náà.
21 Ísírẹ́lì àti àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ ìlà ogun láti pàdé ìlà ogun.
22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì fi ẹrù àjò+ náà sílẹ̀ sábẹ́ àbójútó olùtọ́jú ẹrù àjò,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ síbi ìlà ogun. Nígbà tí ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí béèrè nípa àlàáfíà àwọn arákùnrin rẹ̀.+
23 Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, họ́wù, kíyè sí i, akọgun náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gòláyátì,+ tí í ṣe Filísínì náà láti Gátì,+ ń gòkè bọ̀ láti ìlà ogun àwọn Filísínì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà bí ti ìṣáájú,+ Dáfídì sì fetí sí i.
24 Ní ti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì, nígbà tí wọ́n rí ọkùnrin náà, họ́wù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ ní tìtorí rẹ̀, wọ́n sì fòyà gidigidi.+
25 Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Ẹ ha rí ọkùnrin tí ń gòkè bọ̀ yìí? Nítorí àtiṣáátá+ Ísírẹ́lì ni ó fi ń gòkè bọ̀. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ọkùnrin tí ó bá ṣá a balẹ̀, ọba yóò fi ọrọ̀ ńláǹlà sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀, yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un,+ ilé baba rẹ̀ ni yóò sì dá sílẹ̀ lómìnira ní Ísírẹ́lì.”+
26 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó dúró nítòsí rẹ̀ pé: “Kí ni ohun tí a ó ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá ṣá Filísínì+ náà tí ó wà níbẹ̀ yẹn balẹ̀, tí ó sì yí ẹ̀gàn kúrò lórí Ísírẹ́lì ní ti tòótọ́?+ Nítorí ta ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́+ yìí jẹ́ tí yóò fi máa ṣáátá+ àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?”+
27 Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà gẹ́gẹ́ bí ti ìṣáájú fún un, pé: “Bí a ó ti ṣe nìyí fún ọkùnrin náà tí ó bá ṣá a balẹ̀.”
28 Élíábù+ arákùnrin rẹ̀ tí ó dàgbà jù lọ sì wá gbọ́ bí ó ti ń bá àwọn ọkùnrin náà sọ̀rọ̀, ìbínú Élíábù sì gbóná sí Dáfídì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi sọ pé: “Èé ṣe tí o fi sọ̀ kalẹ̀ wá? Abẹ́ àbójútó ta ni o sì fi ìwọ̀nba àwọn àgùntàn wọnnì sílẹ̀ sí ní aginjù?+ Èmi alára mọ ìkùgbù rẹ àti búburú ọkàn-àyà rẹ+ dáadáa, nítorí pé o ti sọ̀ kalẹ̀ wá fún ète àtirí ìjà ogun náà.”+
29 Dáfídì fèsì pé: “Kí ni mo tíì ṣe báyìí? Kì í ha ṣe ọ̀rọ̀ kan lásán ni bí?”+
30 Pẹ̀lú ìyẹn, ó yí padà kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí ẹlòmíràn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ kan náà bí ti ìṣáájú,+ ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn náà sì fún un ní èsì bí ti tẹ́lẹ̀ rí.+
31 Nítorí náà, a wá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ, wọ́n sì lọ sọ ọ́ níwájú Sọ́ọ̀lù. Fún ìdí yìí ó mú kí ó wá.
32 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà ọkùnrin èyíkéyìí rẹ̀wẹ̀sì nínú rẹ̀.+ Ìránṣẹ́ rẹ fúnra rẹ̀ yóò lọ, yóò sì bá Filísínì yìí jà ní ti tòótọ́.”+
33 Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Ìwọ kò lè lọ bá Filísínì yìí láti bá a jà,+ nítorí ọmọdékùnrin lásán-làsàn ni ọ́,+ òun sì jẹ́ ọkùnrin ogun láti ìgbà ọmọdékùnrin rẹ̀.”
34 Dáfídì sì ń bá a lọ láti sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ìránṣẹ́ rẹ di olùṣọ́ àgùntàn baba rẹ̀ láàárín agbo ẹran, kìnnìún kan sì wá,+ àti béárì kan pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran ọ̀sìn.
35 Mo sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, mo sì ṣá a balẹ̀,+ mo sì gbà á sílẹ̀ ní ẹnu rẹ̀. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dìde sí mi, mo rá irùngbọ̀n rẹ̀ mú, mo sì ṣá a balẹ̀, mo sì fi ikú pa á.
36 Àti kìnnìún àti béárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ ṣá balẹ̀; Filísínì aláìdádọ̀dọ́+ yìí yóò sì dà bí ọ̀kan nínú wọn, nítorí ó ti ṣáátá+ àwọn ìlà ogun+ Ọlọ́run alààyè.”+
37 Dáfídì wá fi kún un pé: “Jèhófà, ẹni tí ó dá mi nídè kúrò ní àtẹ́sẹ̀ kìnnìún náà àti kúrò ní àtẹ́sẹ̀ béárì náà, òun ni ẹni tí yóò dá mi nídè kúrò ní ọwọ́ Filísínì yìí.”+ Látàrí èyí, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ.”+
38 Wàyí o, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀wù rẹ̀ wọ Dáfídì, ó sì fi àṣíborí bàbà dé e ní orí, lẹ́yìn èyí tí ó gbé ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe wọ̀ ọ́.
39 Nígbà náà ni Dáfídì sán idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó sì dáwọ́ lé àtilọ [ṣùgbọ́n kò lè lọ], nítorí pé kò tíì dán wọn wò rí. Níkẹyìn, Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Èmi kò lè wọ nǹkan wọ̀nyí lọ, nítorí èmi kò tíì dán wọn wò rí.” Nítorí náà, Dáfídì bọ́ wọn kúrò.+
40 Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú ọ̀pá rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yan òkúta márùn-ún tí ó jọ̀lọ̀ jù lọ fún ara rẹ̀ láti inú àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, ó sì fi wọ́n sínú àpò olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀ tí ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ìkóhunsí, kànnàkànnà+ rẹ̀ sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ Filísínì náà.
41 Filísínì náà sì ń bọ̀, ó túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì sí i, ọkùnrin tí ó gbé apata ńlá sì wà níwájú rẹ̀.
42 Wàyí o, nígbà tí Filísínì náà wò, tí ó sì rí Dáfídì, ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ́ńbẹ́lú+ rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọmọdékùnrin+ àti apọ́nbéporẹ́,+ tí ó lẹ́wà ní ìrísí.+
43 Nípa báyìí, Filísínì náà sọ fún Dáfídì pé: “Ṣé ajá+ ni mí, tí ìwọ fi ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ọ̀pá?” Pẹ̀lú ìyẹn, Filísínì náà fi àwọn ọlọ́run rẹ̀ pe ibi sọ̀ kalẹ̀ wá sórí Dáfídì.+
44 Filísínì náà sì ń bá a lọ láti sọ fún Dáfídì pé: “Sáà máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko inú pápá.”+
45 Ẹ̀wẹ̀, Dáfídì sọ fún Filísínì náà pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín,+ ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá.+
46 Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ọ balẹ̀, èmi yóò sì mú orí rẹ kúrò lára rẹ; dájúdájú, èmi yóò sì fi àwọn òkú ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run lónìí yìí àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé;+ àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀ ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì.+
47 Gbogbo ìjọ yìí yóò sì mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là,+ nítorí pé ti Jèhófà ni ìjà ogun náà,+ òun yóò sì fi yín lé wa lọ́wọ́.”+
48 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, Filísínì náà dìde, ó sì ń bọ̀, ó sì túbọ̀ ń sún mọ́ tòsí láti pàdé Dáfídì, Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wéré, ó sì ń sáré lọ síhà ìlà ogun láti pàdé Filísínì náà.+
49 Nígbà náà ni Dáfídì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àpò rẹ̀, ó sì mú òkúta kan níbẹ̀, ó sì gbọ̀n ọ́n, tí ó fi ba+ Filísínì náà ní iwájú orí, òkúta náà sì wọ iwájú orí rẹ̀ lọ, ó sì ṣubú ní ìdojúbolẹ̀ sórí ilẹ̀.+
50 Nítorí náà, Dáfídì, pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta, lágbára ju Filísínì náà, ó sì ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì fi ikú pa á; kò sì sí idà ní ọwọ́ Dáfídì.+
51 Dáfídì sì ń bá a lọ ní sísáré, ó sì wá dúró lórí Filísínì náà. Nígbà náà ni ó mú idà rẹ̀,+ ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ rẹ̀, ó sì fi ikú pa á pátápátá nígbà tí ó fi í gé orí rẹ̀ kúrò.+ Àwọn Filísínì sì wá rí i pé alágbára ńlá wọ́n ti kú, wọ́n sì fẹsẹ̀ fẹ.+
52 Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà dìde, wọ́n sì hó yèè, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa+ àwọn Filísínì títí lọ dé àfonífojì + àti títí dé àwọn ẹnubodè Ékírónì,+ àwọn tí ó gbọgbẹ́ lọ́nà tí ó lè yọrí sí ikú nínú àwọn Filísínì ń bá a nìṣó ní ṣíṣubú lójú ọ̀nà láti Ṣááráímù,+ títí dé Gátì àti títí dé Ékírónì.
53 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà kúrò nínú lílépa àwọn Filísínì kíkankíkan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn ibùdó wọn ní ìkógun.+
54 Nígbà náà ni Dáfídì gbé orí+ Filísínì náà, ó sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, àwọn ohun ìjà rẹ̀ ni ó sì fi sínú àgọ́ rẹ̀.+
55 Wàyí o, ní ìṣẹ́jú tí Sọ́ọ̀lù rí Dáfídì tí ń jáde lọ pàdé Filísínì náà, ó sọ fún Ábínérì+ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun pé: “Ábínérì, ọmọkùnrin+ ta ni+ ọmọdékùnrin yìí?” Ábínérì fèsì pé: “Nípa ìwàláàyè ọkàn rẹ, ìwọ ọba, èmi kò mọ̀ rárá!”
56 Nítorí náà, ọba sọ pé: “Ìwọ wádìí nípa ọmọkùnrin ẹni tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà jẹ́.”
57 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbàrà tí Dáfídì padà láti ibi tí ó ti ṣá Filísínì náà balẹ̀, Ábínérì sì mú un wá síwájú Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú orí+ Filísínì náà ní ọwọ́ rẹ̀.
58 Wàyí o, Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Ọmọkùnrin ta ni ọ́, ọmọdékùnrin?” Dáfídì fèsì pé: “Ọmọkùnrin Jésè+ ìránṣẹ́ rẹ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”+