2 Àwọn Ọba 10:1-36
10 Wàyí o, Áhábù ní àádọ́rin+ ọmọkùnrin ní Samáríà.+ Nítorí náà, Jéhù kọ àwọn lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samáríà, sí àwọn ọmọ aládé+ Jésíréélì, àwọn àgbà ọkùnrin+ àti àwọn olùtọ́jú tí ó jẹ́ ti Áhábù, ó sọ pé:
2 “Wàyí o, bí lẹ́tà yìí bá ṣe ń tẹ̀ yín lọ́wọ́, àwọn ọmọkùnrin olúwa yín ń bẹ pẹ̀lú yín, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ẹṣin+ àti ìlú ńlá olódi àti ìhámọ́ra sì ń bẹ pẹ̀lú yín.
3 Kí ẹ sì wo èyí tí ó bá dára jù lọ, tí ó sì dúró ṣánṣán jù lọ nínú àwọn ọmọkùnrin olúwa yín, kí ẹ sì gbé e ka orí ìtẹ́ baba rẹ̀.+ Nígbà náà, kí ẹ jà fún ilé olúwa yín.”
4 Àyà sì fò wọ́n gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Wò ó! Ọba méjì+ pàápàá kò dúró níwájú rẹ̀, báwo sì ni àwa alára yóò ṣe dúró?”+
5 Nítorí náà, ẹni tí ń bojú tó ilé náà àti ẹni tí ń bójú tó ìlú ńlá náà àti àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olùtọ́jú+ ránṣẹ́ sí Jéhù, wọ́n sọ pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa, gbogbo ohun tí o bá sì sọ fún wa ni àwa yóò ṣe. Àwa kì yóò fi ẹnikẹ́ni jẹ ọba. Ohun tí ó bá dára ní ojú rẹ ni kí o ṣe.”
6 Látàrí ìyẹn, ó kọ lẹ́tà kejì, ó sọ pé: “Bí ẹ bá jẹ́ tèmi,+ tí ó bá sì jẹ́ ohùn mi ni ẹ ń ṣègbọràn sí, ẹ kó orí àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọkùnrin+ olúwa yín, kí ẹ sì tọ̀ mí wá ní ìwòyí ọ̀la ní Jésíréélì.”+
Wàyí o, àwọn ọmọkùnrin ọba, àádọ́rin ọkùnrin, wà pẹ̀lú àwọn sàràkí ọkùnrin ìlú ńlá tí ń tọ́ wọn.
7 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí lẹ́tà náà tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n lọ kó àwọn ọmọkùnrin ọba, wọ́n sì pa wọ́n, àádọ́rin ọkùnrin,+ lẹ́yìn èyí tí wọ́n kó orí wọn sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí i ní Jésíréélì.
8 Nígbà náà ni àwọn ońṣẹ́+ wọlé wá, wọ́n sì sọ fún un, pé: “Wọ́n ti kó orí+ àwọn ọmọkùnrin ọba dé.” Nítorí náà, ó sọ pé: “Ẹ kó wọn jọ ní òkìtì méjì sí ibi àtiwọ ẹnubodè títí di òwúrọ̀.”+
9 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ pé ó jáde lọ. Nígbà náà ni ó dúró jẹ́ẹ́, ó sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Olódodo ni ẹ̀yin.+ Kíyè sí i, èmi fúnra mi di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí olúwa mi, mo sì pa á;+ ṣùgbọ́n ta ní ṣá gbogbo àwọn wọ̀nyí balẹ̀?
10 Nígbà náà, ẹ mọ̀ pé kò sí ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí yóò bọ́ sí ilẹ̀ láìní ìmúṣẹ+ nínú ohun tí Jèhófà sọ lòdì sí ilé Áhábù;+ Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà.”+
11 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jéhù tẹ̀ síwájú láti ṣá gbogbo ẹni tí ó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Jésíréélì balẹ̀, àti gbogbo sàràkí ọkùnrin rẹ̀+ àti àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà rẹ̀,+ títí òun kò fi jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku olùlàájá kankan fún un.+
12 Ó sì tẹ̀ síwájú láti dìde, ó sì wọlé, nígbà náà ni ó mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí Samáríà. Ilé ìso ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn sì ń bẹ lójú ọ̀nà.
13 Jéhù alára sì bá àwọn arákùnrin+ Ahasáyà+ ọba Júdà pàdé. Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Ta ni yín?” nígbà náà ni wọ́n sọ pé: “Arákùnrin Ahasáyà ni wá, a sì ń bá ọ̀nà wa sọ̀ kalẹ̀ lọ láti béèrè àlàáfíà àwọn ọmọkùnrin ọba àti àwọn ọmọkùnrin ìyáàfin.”
14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ mú wọn láàyè!”+ Nítorí náà, wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n níbi ìkùdu ilé ìso, ọkùnrin méjì-lé-lógójì, kò sì jẹ́ kí ẹyọ ẹnì kan lára wọn ṣẹ́ kù.+
15 Bí ó ṣe ń kọjá lọ láti ibẹ̀, ó ṣalábàápàdé Jèhónádábù+ ọmọkùnrin Rékábù+ tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Nígbà tí ó súre+ fún un, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ó sọ fún un pé: “Ọkàn-àyà rẹ ha dúró ṣánṣán pẹ̀lú mi bí, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọkàn-àyà tèmi ṣe jẹ́ pẹ̀lú ọkàn-àyà rẹ?”+
Jèhónádábù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”
“Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.”
Nítorí náà, ó fún un ní ọwọ́ rẹ̀. Látàrí ìyẹn, ó mú kí ó gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú rẹ̀.+
16 Nígbà náà ni ó sọ pé: “Bá mi ká lọ, kí o sì wo bí èmi kò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.”+ Wọ́n sì mú kí ó bá a gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ lọ.
17 Níkẹyìn, ó dé Samáríà. Wàyí o, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́ kù, tí ó jẹ́ ti Áhábù ní Samáríà balẹ̀, títí ó fi pa wọ́n rẹ́ ráúráú,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó bá Èlíjà sọ.+
18 Síwájú sí i, Jéhù kó gbogbo àwọn ènìyàn jọpọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Áhábù, ní ọwọ́ kan, jọ́sìn Báálì díẹ̀.+ Jéhù, ní ọwọ́ kejì, yóò jọ́sìn rẹ̀ púpọ̀ gan-an.
19 Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì+ Báálì, gbogbo olùjọsìn rẹ̀,+ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀+ wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹyọ ẹnì kan kù, nítorí pé mo fẹ́ rú ẹbọ ńlá sí Báálì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kù kì yóò wà láàyè.” Ní ti Jéhù, ó lo ọgbọ́n wẹ́wẹ́,+ fún ète àtipa àwọn olùjọsìn Báálì run.
20 Jéhù sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Ẹ sọ àpéjọ ọ̀wọ̀ di mímọ́ fún Báálì.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n pòkìkí rẹ̀.
21 Lẹ́yìn ìyẹn, Jéhù ránṣẹ́ jákèjádò Ísírẹ́lì,+ tí ó fi jẹ́ pé gbogbo olùjọsìn Báálì wọlé wá. Kò sì ṣẹ́ ku ẹyọ ẹnì kan tí kò wọlé wá. Wọ́n sì ń wọlé wá sí ilé Báálì,+ ilé Báálì sì wá kún láti ìpẹ̀kun dé ìpẹ̀kun.
22 Wàyí o, ó sọ fún ẹni tí ó wà nídìí ibi tí a ń pa aṣọ mọ́ sí pé: “Kó ẹ̀wù jáde wá fún gbogbo olùjọsìn Báálì.” Nítorí náà, ó kó aṣọ jáde wá fún wọn.
23 Nígbà náà ni Jéhù wọlé ti òun ti Jèhónádábù+ ọmọkùnrin Rékábù, sínú ilé Báálì. Nísinsìnyí ó sọ fún àwọn olùjọsìn Báálì pé: “Ẹ fẹ̀sọ̀ ṣe ìwákiri kí ẹ sì rí i pé kò sí ọ̀kan nínú àwọn olùjọsìn Jèhófà níbí pẹ̀lú yín, bí kò ṣe kìkì àwọn olùjọsìn Báálì.”+
24 Níkẹyìn, wọ́n wọlé wá láti rú àwọn ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun, Jéhù fúnra rẹ̀ sì yan ọgọ́rin ọkùnrin sí òde ní ìkáwọ́ ara rẹ̀, ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ní ti ẹni tí ó bá sá lọ lára àwọn ènìyàn tí èmi yóò fi lé yín lọ́wọ́, ọkàn ẹni náà yóò lọ fún ọkàn onítọ̀hún.”+
25 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó parí rírú ọrẹ ẹbọ sísun náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jéhù sọ fún àwọn sárésáré àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun pé: “Ẹ wọlé, ẹ ṣá wọn balẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹyọ ẹnì kan jáde lọ.”+ Àwọn sárésáré àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun+ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n sì gbé wọn jù síta, wọ́n sì ń lọ títí dé ìlú ńlá ilé Báálì.
26 Nígbà náà ni wọ́n kó àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀+ inú ilé Báálì jáde, wọ́n sì fi iná sun+ gbogbo wọn.
27 Síwájú sí i, wọ́n bi ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ Báálì wó,+ wọ́n sì bi ilé Báálì wó,+ wọ́n sì yà á sọ́tọ́ fún ilé ìgbọ̀nsẹ̀+ títí di òní.
28 Bí Jéhù ṣe pa Báálì rẹ́ ráúráú kúrò ní Ísírẹ́lì nìyẹn.
29 Kìkì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀,+ ni Jéhù kò yà kúrò nínú títọ̀ lẹ́yìn, èyíinì ni, àwọn ọmọ màlúù wúrà,+ èyí tí ọ̀kan nínú wọn wà ní Bẹ́tẹ́lì, tí ọ̀kan sì wà ní Dánì.+
30 Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Jéhù pé: “Nítorí ìdí náà pé o ti ṣe dáadáa ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú mi,+ tí o sì ṣe sí ilé Áhábù+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn-àyà mi, dé ìran kẹrin ni àwọn ọmọ yóò máa jókòó fún ọ lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.”+
31 Jéhù alára kò sì kíyè sára láti fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀+ rìn nínú òfin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Kò yà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+
32 Ní ọjọ́ wọnnì, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ké Ísírẹ́lì kúrò ní ègé-ègé; Hásáélì+ sì ń kọlù wọ́n ṣáá ní gbogbo ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,
33 láti Jọ́dánì síhà yíyọ oòrùn, gbogbo ilẹ̀ Gílíádì,+ àwọn ọmọ Gádì+ àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti àwọn ọmọ Mánásè,+ láti Áróérì,+ èyí tí ó wà lẹ́bàá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, àní Gílíádì àti Báṣánì.+
34 Àti ìyókù àlámọ̀rí Jéhù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo agbára ńlá rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
35 Níkẹyìn, Jéhù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ wọ́n sì sin ín sí Samáríà; Jèhóáhásì+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.
36 Ọjọ́ tí Jéhù sì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ní Samáríà.