2 Àwọn Ọba 14:1-29
14 Ní ọdún kejì Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Amasááyà+ ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọba Júdà di ọba.
2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ó jẹ́ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jèhóádínì+ ti Jerúsálẹ́mù.
3 Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó dúró ṣánṣán ní ojú Jèhófà,+ kìkì pé kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀.+ Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhóáṣì baba rẹ̀ ṣe, ni ó ṣe.+
4 Kìkì àwọn ibi gíga ni kò dàwátì.+ Àwọn ènìyàn ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń rú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga.+
5 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ìjọba ti di èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in ní ọwọ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ balẹ̀,+ àwọn tí ó ṣá baba rẹ̀ ọba balẹ̀.+
6 Kò sì fi ikú pa àwọn ọmọ àwọn akọluni náà, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mósè tí Jèhófà pa láṣẹ, pé:+ “Kí a má fi ikú pa àwọn baba nítorí àwọn ọmọ, kí a má sì fi ikú pa àwọn ọmọ pàápàá nítorí àwọn baba; ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni kí a fi ikú pa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀.”+
7 Òun fúnra rẹ̀ ni ó ṣá àwọn ọmọ Édómù balẹ̀+ ní Àfonífojì Iyọ̀,+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn, ó sì fi ogun gba Sẹ́ẹ́là, orúkọ rẹ̀ sì ni a wá pè ní Jókítéélì títí di òní yìí.
8 Ìgbà náà ni Amasááyà rán àwọn ońṣẹ́ sí Jèhóáṣì ọmọkùnrin Jèhóáhásì ọmọkùnrin Jéhù ọba Ísírẹ́lì, pé: “Wá. Jẹ́ kí a wo ara wa lójú.”+
9 Látàrí ìyẹn, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Amasááyà ọba Júdà, pé: “Èpò ẹlẹ́gùn-ún tí ó wà ní Lẹ́bánónì ránṣẹ́ sí kédárì+ tí ó wà ní Lẹ́bánónì, pé, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi kí ó fi ṣe aya.’ Bí ó ti wù kí ó rí, ẹranko ẹhànnà kan láti inú pápá tí ó wà ní Lẹ́bánónì kọjá, ó sì tẹ èpò ẹlẹ́gùn-ún náà mọ́lẹ̀.+
10 Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ìwọ ti ṣá Édómù balẹ̀,+ ọkàn-àyà rẹ sì ti gbé ọ ga.+ Gbádùn ọlá+ rẹ kí ó sì máa gbé ilé tìrẹ. Kí wá ni ìdí tí ìwọ yóò fi kó wọnú gbọ́nmi-si omi-ò-to+ lábẹ́ àwọn ipò tí kò rọgbọ,+ tí ìwọ yóò sì fi ṣubú, ìwọ àti Júdà pẹ̀lú rẹ?”
11 Amasááyà kò sì fetí sílẹ̀.+
Nítorí náà, Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì gòkè wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú,+ òun àti Amasááyà ọba Júdà, ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ tí í ṣe ti Júdà.
12 A sì wá ṣẹ́gun Júdà níwájú Ísírẹ́lì,+ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹsẹ̀ fẹ, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀.
13 Amasááyà ọba Júdà ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọmọkùnrin Ahasáyà sì ni Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì mú ní Bẹti-ṣémẹ́ṣì, lẹ́yìn èyí tí wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ṣe àlàfo sára ògiri Jerúsálẹ́mù níbi Ẹnubodè Éfúráímù+ títí lọ dé Ẹnubodè Igun,+ irínwó ìgbọ̀nwọ́.
14 Ó sì kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí a rí ní ilé Jèhófà+ àti àwọn ìṣúra ilé ọba àti àwọn ẹni àfidógò, lẹ́yìn náà, ó padà lọ sí Samáríà.
15 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèhóáṣì, ohun tí ó ṣe àti agbára ńlá rẹ̀ àti bí ó ṣe bá Amasááyà ọba Júdà jà, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
16 Níkẹyìn, Jèhóáṣì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀,+ a sì sin ín sí Samáríà+ pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì, Jèróbóámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.
17 Amasááyà+ ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọba Júdà sì ń bá a lọ láti wà láàyè fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún+ lẹ́yìn ikú Jèhóáṣì+ ọmọkùnrin Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì.
18 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Amasááyà, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà?+
19 Nígbà tí ó ṣe, wọ́n mulẹ̀ nínú tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ lòdì sí i ní Jerúsálẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí Lákíṣì;+ ṣùgbọ́n wọ́n ránṣẹ́ tẹ̀ lé e lọ sí Lákíṣì, wọ́n sì fi ikú pa á níbẹ̀.+
20 Nítorí náà, wọ́n gbé e sórí àwọn ẹṣin, a sì sin ín+ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì.+
21 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn Júdà mú Asaráyà,+ tí í ṣe ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà náà,+ wọ́n sì fi í jẹ ọba ní ipò Amasááyà baba rẹ̀.+
22 Òun alára ni ó kọ́ Élátì,+ ó sì mú un padà wá fún Júdà lẹ́yìn tí ọba ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.
23 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún Amasááyà ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọba Júdà, Jèróbóámù+ ọmọkùnrin Jèhóáṣì ọba Ísírẹ́lì di ọba ní Samáríà fún ọdún mọ́kàn-lé-lógójì.
24 Ó sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà. Kò yà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Jèróbóámù ọmọkùnrin Nébátì, èyí tí ó fi mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.+
25 Òun ni ó mú ààlà Ísírẹ́lì padà bọ̀ sípò láti àtiwọ Hámátì+ títí lọ dé òkun Árábà,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Jónà+ ọmọkùnrin Ámítáì, wòlíì tí ó wá láti Gati-héférì.+
26 Nítorí tí Jèhófà ti rí ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ kíkorò gidigidi tí ó dé bá Ísírẹ́lì.+ Kò sí aláìní olùrànlọ́wọ́ kankan tàbí ẹni tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún Ísírẹ́lì.+
27 Jèhófà sì ti ṣèlérí pé òun kò ní nu orúkọ Ísírẹ́lì kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Nítorí náà, ó gbà wọ́n là+ nípa ọwọ́ Jèróbóámù ọmọkùnrin Jèhóáṣì.
28 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Jèróbóámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti agbára ńlá rẹ̀, bí ó ṣe jà àti bí ó ṣe mú Damásíkù+ àti Hámátì+ padà bọ̀ wá fún Júdà ní Ísírẹ́lì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì?
29 Níkẹyìn, Jèróbóámù dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì, Sekaráyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.