2 Àwọn Ọba 16:1-20
16 Ní ọdún kẹtàdínlógún Pékà ọmọkùnrin Remaláyà, Áhásì+ ọmọkùnrin Jótámù ọba Júdà di ọba.
2 Ẹni ogún ọdún ni Áhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù; kò sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀.+
3 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ àní ọmọ tirẹ̀ ni ó mú la iná kọjá,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí+ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé jáde nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
4 Ó sì ń bá a nìṣó ní rírúbọ àti ní rírú èéfín ẹbọ lórí àwọn ibi gíga+ àti lórí àwọn òkè kéékèèké+ àti lábẹ́ gbogbo igi tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.+
5 Ìgbà náà ni Résínì+ ọba Síríà àti Pékà+ ọmọkùnrin Remaláyà ọba Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè wá láti bá Jerúsálẹ́mù jagun, wọ́n sì sàga ti Áhásì, ṣùgbọ́n wọn kò lè jà.+
6 Ní àkókò yẹn, Résínì ọba Síríà mú Élátì padà wá fún Édómù, lẹ́yìn èyí tí ó kó àwọn Júù kúrò ní Élátì;+ àwọn ọmọ Édómù, ní tiwọn, sì wọ Élátì, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní gbígbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
7 Nítorí náà, Áhásì rán àwọn ońṣẹ́ sí Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà, pé: “Ìránṣẹ́ rẹ+ àti ọmọkùnrin rẹ ni mí. Gòkè wá gbà mí là+ kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Síríà àti kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ọba Ísírẹ́lì, àwọn tí ó dìde sí mi.”
8 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Áhásì kó fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Jèhófà àti nínú àwọn ìṣúra ilé ọba,+ ó sì fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀+ ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà.
9 Látàrí ìyẹn, ọba Ásíríà fetí sí i, ọba Ásíríà sì gòkè lọ sí Damásíkù,+ ó sì gbà á,+ ó sì kó àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbèkùn lọ sí Kírì,+ ó sì fi ikú pa Résínì.+
10 Nígbà náà ni Áhásì+ Ọba lọ pàdé Tigilati-pílésà+ ọba Ásíríà ní Damásíkù, ó sì wá rí pẹpẹ+ tí ó wà ní Damásíkù. Nítorí náà, Áhásì Ọba fi iṣẹ́ ọnà pẹpẹ náà àti àwòṣe rẹ̀ ní ti gbogbo iṣẹ́ ọnà+ rẹ̀ ránṣẹ́ sí Úríjà àlùfáà.
11 Úríjà+ àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ pẹpẹ náà.+ Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Áhásì Ọba fi ránṣẹ́ láti Damásíkù, bẹ́ẹ̀ ni Úríjà àlùfáà ṣe mọ ọ́n, títí di ìgbà tí Áhásì Ọba fi dé láti Damásíkù.
12 Nígbà tí ọba dé láti Damásíkù, ọba wá rí pẹpẹ náà; ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ pẹpẹ náà,+ ó sì rú àwọn ẹbọ lórí rẹ̀.+
13 Ó sì ń bá a lọ láti mú ọrẹ ẹbọ sísun+ rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ rẹ̀ rú èéfín,+ ó sì da ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀ jáde, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ tirẹ̀ sára pẹpẹ náà.
14 Pẹpẹ bàbà+ tí ó wà ní iwájú Jèhófà ni ó sì mú sún mọ́ tòsí wàyí láti iwájú ilé náà, láti àárín pẹpẹ tirẹ̀ àti ilé Jèhófà,+ ó sì gbé e sí ìhà àríwá pẹpẹ tirẹ̀.
15 Áhásì Ọba sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún un, àní fún Úríjà+ àlùfáà, pé: “Orí pẹpẹ ńlá náà ni kí o ti mú ọrẹ ẹbọ sísun òwúrọ̀ rú èéfín,+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà ìrọ̀lẹ́+ pẹ̀lú àti ọrẹ ẹbọ sísun ti ọba+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun ti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọrẹ ẹbọ ọkà wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn; gbogbo ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sì ni kí o wọ́n sára rẹ̀. Ní ti pẹpẹ bàbà náà, yóò jẹ́ ohun kan tí èmi yóò gbé yẹ̀ wò.”
16 Úríjà+ àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Áhásì Ọba pa láṣẹ.+
17 Síwájú sí i, Áhásì Ọba ké+ abala ẹ̀gbẹ́+ ara àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ sí wẹ́wẹ́, ó sì gbé bàsíà+ kúrò lórí wọn; òkun+ ni ó sì gbé sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí àwọn akọ màlúù bàbà+ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sì wá gbé e sórí ibi tí a fi òkúta tẹ́.
18 Ibi àbòlórí fún sábáàtì, èyí tí wọ́n kọ́ sínú ilé náà àti ọ̀nà àbáwọlé ti ọba tí ó wà ní òde ni ó sì ṣí nípò padà kúrò ní ilé Jèhófà nítorí ọba Ásíríà.
19 Ní ti ìyókù àlámọ̀rí Áhásì, ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé+ àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà?
20 Níkẹyìn, Áhásì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Ńlá Dáfídì;+ Hesekáyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.