2 Àwọn Ọba 2:1-25
2 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jèhófà fẹ́ fi ìjì ẹlẹ́fùúùfù gbé Èlíjà+ gòkè re ọ̀run,+ Èlíjà àti Èlíṣà+ bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti Gílígálì.+
2 Èlíjà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Èlíṣà pé: “Jọ̀wọ́, jókòó síhìn-ín, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ti rán mi lọ tààrà sí Bẹ́tẹ́lì.” Ṣùgbọ́n Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ,+ àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ,+ èmi kí yóò fi ọ́ sílẹ̀.”+ Nítorí náà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+
3 Nígbà náà ni àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ tí wọ́n wà ní Bẹ́tẹ́lì jáde tọ Èlíṣà wá, wọ́n sì sọ fún un pé: “O ha mọ̀ ní tòótọ́ pé, lónìí, Jèhófà yóò mú ọ̀gá rẹ kúrò ní ṣíṣe olórí rẹ?”+ Látàrí èyí, ó wí pé: “Èmi pẹ̀lú mọ̀ dáadáa.+ Ẹ dákẹ́.”
4 Wàyí o, Èlíjà sọ fún un pé: “Èlíṣà, jọ̀wọ́, jókòó síhìn-ín, nítorí pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ rán mi lọ sí Jẹ́ríkò.”+ Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ, ó dájú pé èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n wá sí Jẹ́ríkò.
5 Nígbà náà ni àwọn ọmọ àwọn wòlíì tí wọ́n wà ní Jẹ́ríkò tọ Èlíṣà wá, wọ́n sì sọ fún un pé: “O ha mọ̀ ní tòótọ́ pé, lónìí, Jèhófà yóò mú ọ̀gá rẹ kúrò ní ṣíṣe olórí rẹ?” Látàrí èyí, ó wí pé: “Èmi pẹ̀lú mọ̀ dáadáa. Ẹ dákẹ́.”+
6 Wàyí o, Èlíjà sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, jókòó síhìn-ín, nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ rán mi lọ sí Jọ́dánì.”+ Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ, ó dájú pé èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.”+ Nítorí náà, àwọn méjèèjì jọ ń lọ.
7 Àádọ́ta ọkùnrin lára àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì ń bẹ tí ó lọ dúró ní ọ̀kánkán lókèèrè;+ ṣùgbọ́n, ní ti àwọn méjèèjì, wọ́n dúró lẹ́bàá Jọ́dánì.
8 Nígbà náà ni Èlíjà mú ẹ̀wù oyè+ rẹ̀, ó sì ká a, ó sì lu omi náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó pín síhìn-ín àti sọ́hùn-ún, tí àwọn méjèèjì fi sọdá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.+
9 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n ti sọdá, Èlíjà fúnra rẹ̀ sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí èmi yóò ṣe fún ọ kí a tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.”+ Èlíṣà fèsì pé: “Jọ̀wọ́, kí ipa méjì+ nínú ẹ̀mí+ rẹ lè bà lé mi.”+
10 Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ìwọ béèrè+ ohun kan tí ó ṣòro. Bí o bá rí mi nígbà tí a bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rí mi, kì yóò ṣẹlẹ̀.”
11 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń rìn lọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn, họ́wù, wò ó! kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná+ kan àti àwọn ẹṣin oníná, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pààlà sáàárín àwọn méjèèjì; Èlíjà sì gòkè re ọ̀run+ nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù.
12 Ní gbogbo àkókò náà, Èlíṣà rí i, ó sì ń ké jáde pé: “Baba mi, baba mi,+ kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun Ísírẹ́lì àti àwọn ẹlẹ́ṣin+ rẹ̀!” Òun kò sì rí i mọ́. Nítorí náà, ó di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí méjì.+
13 Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú ẹ̀wù oyè+ Èlíjà tí ó já bọ́ lára rẹ̀, ó sì padà, ó sì dúró lẹ́bàá èbúté Jọ́dánì.
14 Nígbà náà ni ó mú ẹ̀wù oyè Èlíjà tí ó já bọ́ lára rẹ̀, ó sì lu omi+ náà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà, àní Òun?”+ Nígbà tí ó lu omi náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n pín síhìn-ín àti sọ́hùn-ún, tí Èlíṣà fi sọdá.
15 Nígbà tí àwọn ọmọ àwọn wòlíì tí wọ́n wà ní Jẹ́ríkò rí i lókèèrè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹ̀mí+ Èlíjà ti sọ̀ kalẹ̀ sórí Èlíṣà.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n wá pàdé rẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba mọ́lẹ̀+ fún un.
16 Wọ́n sì ń bá a lọ láti sọ fún un pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, àádọ́ta ọkùnrin, akíkanjú ènìyàn, ń bẹ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n lọ wá ọ̀gá rẹ. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀mí+ Jèhófà gbé e, tí ó sì wá sọ ọ́ sí orí ọ̀kan nínú àwọn òkè ńlá tàbí sínú ọ̀kan nínú àwọn àfonífojì.” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ rán wọn.”
17 Wọ́n sì ń rọ̀ ọ́ ṣáá, títí ara fi tì í, tí ó fi sọ pé: “Ẹ ránṣẹ́.” Wọ́n wá rán àádọ́ta ọkùnrin; wọ́n sì ń wá a fún ọjọ́ mẹ́ta, ṣùgbọ́n wọn kò rí i.
18 Nígbà tí wọ́n padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ń gbé ní Jẹ́ríkò.+ Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé: “Èmi kò ha sọ fún yín pé, ‘Ẹ má lọ’?”
19 Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà sọ fún Èlíṣà pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, ipò tí ìlú ńlá yìí wà dára,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá mi ṣe rí i; ṣùgbọ́n omi+ rẹ̀ burú, ilẹ̀ yìí sì ń fa ìṣẹ́nú.”+
20 Látàrí ìyẹn, ó sọ pé: “Ẹ wá àwokòtò kékeré tuntun kan wá, kí ẹ sì fi iyọ̀ sínú rẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n wá a wá fún un.
21 Nígbà náà ni ó jáde lọ sí orísun omi náà, ó sì da iyọ̀ sínú rẹ̀,+ ó sì sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Mo sọ omi yìí di afúnni-nílera.+ Ikú tàbí ohun tí ń fa ìṣẹ́nú kì yóò ti inú rẹ̀ wá mọ́.’”
22 A sì ṣe àwòtán omi náà títí di òní yìí,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Èlíṣà tí ó sọ.
23 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè láti ibẹ̀ lọ sí Bẹ́tẹ́lì.+ Bí ó ṣe ń gòkè lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọmọdékùnrin kéékèèké+ kan wà tí ó jáde wá láti inú ìlú ńlá náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń wí fún un ṣáá pé: “Gòkè lọ, apárí!+ Gòkè lọ, apárí!”
24 Níkẹyìn, ó bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì rí wọn, ó sì pe ibi+ wá sórí wọn ní orúkọ Jèhófà. Nígbà náà ni abo béárì+ méjì jáde wá láti inú ẹgàn, wọ́n sì fa méjì-lé-lógójì ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ lára àwọn ọmọ náà.+
25 Ó ń bá a nìṣó ní lílọ láti ibẹ̀ sí Òkè Ńlá Kámẹ́lì,+ láti ibẹ̀, ó padà sí Samáríà.