2 Àwọn Ọba 22:1-20
22 Ẹni ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jédídà ọmọbìnrin Ádáyà láti Bósíkátì.+
2 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ ó sì ń rìn ní gbogbo ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀,+ kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+
3 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kejìdínlógún Jòsáyà Ọba pé ọba rán Ṣáfánì+ ọmọkùnrin Asaláyà ọmọkùnrin Méṣúlámù akọ̀wé sí ilé Jèhófà, pé:
4 “Gòkè tọ Hilikáyà+ àlùfáà àgbà+ lọ, kí ó sì kó owó tí a mú wá sí ilé Jèhófà+ jọ,+ èyí tí àwọn olùṣọ́nà+ ti kó jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn náà;
5 kí wọ́n sì fi í lé ọwọ́ àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà,+ àwọn tí a yàn sípò, nínú ilé Jèhófà, kí wọ́n lè fi í fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ náà, àwọn tí wọ́n wà nínú ilé Jèhófà láti tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe,+
6 fún àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn akọ́lé àti àwọn ọ̀mọ̀lé, àti láti ra àwọn ẹ̀là gẹdú àti àwọn òkúta gbígbẹ́ láti tún ilé náà ṣe.+
7 Kìkì pé kí a má ṣe ṣírò owó tí ó wà lọ́dọ̀ wọn sí ọwọ́ ẹni tí a ń fi í sí,+ nítorí pé ìṣòtítọ́+ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́.”
8 Lẹ́yìn náà, Hilikáyà+ àlùfáà àgbà wí fún Ṣáfánì+ akọ̀wé pé:+ “Ìwé òfin+ gan-an ni mo ti rí ní ilé Jèhófà.” Nítorí náà, Hilikáyà fi ìwé náà fún Ṣáfánì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á.
9 Nígbà náà ni Ṣáfánì akọ̀wé wọlé wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì fún ọba lésì, ó sì sọ pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti da owó tí a rí nínú ilé náà, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti fi í lé ọwọ́ àwọn olùṣe iṣẹ́ náà, àwọn tí a yàn sípò, nínú ilé Jèhófà.”+
10 Ṣáfánì akọ̀wé sì ń bá a lọ láti sọ fún ọba, pé: “Ìwé+ kan wà tí Hilikáyà àlùfáà fi fún mi.” Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á níwájú ọba.
11 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé òfin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.+
12 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Hilikáyà àlùfáà àti Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì àti Ákíbórì ọmọkùnrin Mikáyà àti Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà+ ìránṣẹ́ ọba, pé:
13 “Ẹ lọ, ẹ wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà, nítorí tèmi àti nítorí ti àwọn ènìyàn àti nítorí ti gbogbo Júdà, nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí tí a rí; nítorí títobí ni ìhónú Jèhófà+ tí a mú gbaná jẹ sí wa nítorí òtítọ́ náà pé àwọn baba ńlá+ wa kò fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí nípa ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí a kọ nípa wa.”+
14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Hilikáyà àlùfáà àti Áhíkámù àti Ákíbórì àti Ṣáfánì àti Ásáyà lọ sọ́dọ̀ Húlídà wòlíì obìnrin,+ aya Ṣálúmù ọmọkùnrin Tíkífà ọmọkùnrin Háhásì, olùbójútó àwọn ẹ̀wù,+ bí ó ti ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ní ìhà kejì; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ̀rọ̀.+
15 Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí,+ ‘Ẹ wí fún ọkùnrin tí ó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé:
16 “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù+ wá sórí ibí yìí àti sórí àwọn olùgbé rẹ̀,+ àní gbogbo ọ̀rọ̀+ ìwé tí ọba Júdà kà;+
17 nítorí òtítọ́ náà pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀, tí wọ́n sì lọ ń rú èéfín ẹbọ sí àwọn ọlọ́run mìíràn,+ kí wọ́n lè fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn+ mú mi bínú, ìhónú mi sì ni a ti mú gbaná jẹ sí ibí yìí, a kì yóò sì fẹ́ ẹ pa.’”’+
18 Àti ní ti ọba Júdà tí ó rán yín láti wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, èyí ni ohun tí ẹ óò wí fún un, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o ti gbọ́,+
19 nítorí ìdí náà pé ọkàn-àyà rẹ+ rọ̀ tí ó fi jẹ́ pé o rẹ ara rẹ sílẹ̀+ nítorí Jèhófà bí o ṣe gbọ́ ohun tí mo sọ lòdì sí ibí yìí àti àwọn olùgbé rẹ̀, pé kí ó di ohun ìyàlẹ́nu àti ìfiré,+ tí o sì wá gbọn ẹ̀wù rẹ ya,+ tí o sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún níwájú mi, èmi, àní èmi, ti gbọ́,” ni àsọjáde Jèhófà.+
20 “Kíyè sí i, ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi kó ọ jọ+ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ, a ó sì kó ọ jọ dájúdájú sínú itẹ́ tìrẹ ní àlàáfíà,+ ojú rẹ kì yóò sì rí gbogbo ìyọnu àjálù tí èmi yóò mú wá sórí ibí yìí.”’” Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú èsì náà wá fún ọba.