2 Àwọn Ọba 25:1-30
25 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹsàn-án+ tí ó jẹ ọba, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá+ oṣù náà, pé Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé,+ bẹ́ẹ̀ ni, òun àti gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀, láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dó tì í, wọ́n sì ń mọ odi ìsàgatì yí i ká.+
2 Ìlú ńlá náà sì wá wà lábẹ́ ìsàgatì títí di ọdún kọkànlá Sedekáyà Ọba.
3 Ní ọjọ́ kẹsàn-án+ oṣù kẹrin, ìyàn+ mú gidigidi nínú ìlú ńlá náà, kò wá sí oúnjẹ+ kankan fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
4 A sì ṣe àlàfo+ sí ìlú ńlá náà, gbogbo ọkùnrin ogun sì sá lọ ní òru, gba ti ẹnubodè tí ó wà láàárín ògiri onílọ̀ọ́po-méjì tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba,+ nígbà tí àwọn ará Kálídíà+ ká ìlú ńlá náà mọ́; ọba sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ+ sí ìhà Árábà.+
5 Ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa ọba, wọ́n sì lé e bá+ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Jẹ́ríkò;+ gbogbo ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
6 Nígbà náà ni wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n sì mú un gòkè wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà,+ kí wọ́n lè kéde ìpinnu ìdájọ́ lé e lórí.
7 Àwọn ọmọ Sedekáyà ni wọ́n sì pa lójú rẹ̀,+ ó sì fọ́ ojú Sedekáyà,+ lẹ́yìn èyí, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà+ dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+
8 Àti ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ keje oṣù náà, èyíinì ni, ọdún kọkàndínlógún+ Nebukadinésárì Ọba, tí í ṣe ọba Bábílónì, Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+
9 Ó sì tẹ̀ síwájú láti fi iná sun ilé Jèhófà+ àti ilé ọba+ àti gbogbo ilé ní Jerúsálẹ́mù;+ ilé gbogbo ènìyàn ńlá ni ó sì fi iná sun.+
10 Àti àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù, yíká-yíká, ni gbogbo ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Kálídíà tí ó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ bì wó.+
11 Ìyókù àwọn ènìyàn náà+ tí a fi sílẹ̀ sẹ́yìn nínú ìlú ńlá náà àti àwọn olùyalọ tí ó kọ́ja lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì àti ìyókù ogunlọ́gọ̀ náà ni Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó lọ sí ìgbèkùn.+
12 Àwọn kan lára àwọn enìyàn rírẹlẹ̀+ ilẹ̀ náà sì ni olórí ẹ̀ṣọ́ jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù gẹ́gẹ́ bí olùrẹ́wọ́ àjàrà àti gẹ́gẹ́ bí lébìrà àpàpàǹdodo.+
13 Àti àwọn ọwọ̀n bàbà+ tí ó wà ní ilé Jèhófà, àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti òkun bàbà+ tí ó wà ní ilé Jèhófà ni àwọn ará Kálídíà fọ́ sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó bàbà wọn lọ sí Bábílónì.+
14 Àti àwọn garawa àti àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn àlùmọ́gàjí fìtílà àti àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà,+ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n kó.
15 Olórí ẹ̀ṣọ́ sì kó àwọn ìkóná àti àwọn àwokòtò tí ó jẹ́ ojúlówó wúrà+ àti àwọn tí ó jẹ́ ojúlówó fàdákà.+
16 Ní ti ọwọ̀n méjèèjì, òkun kan ṣoṣo yẹn àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Sólómọ́nì ṣe fún ilé Jèhófà, kò sí ọ̀nà láti gbà sọ ìwọ̀n bàbà tí gbogbo nǹkan èlò wọ̀nyí jẹ́.+
17 Ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún+ ni gíga ọwọ̀n kọ̀ọ̀kan, ọpọ́n+ tí ó wà lórí rẹ̀ sì jẹ́ bàbà; gíga ọpọ́n náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti àsokọ́ra bí àwọ̀n àti pómégíránétì+ tí ó wá lára ọpọ́n náà yí ká, gbogbo rẹ̀, jẹ́ bàbà; ọwọ̀n kejì sì ní irú nǹkan wọ̀nyí lára àsokọ́ra bí àwọ̀n náà.
18 Síwájú sí i, olórí ẹ̀ṣọ́ mú Seráyà+ olórí àlùfáà àti Sefanáyà+ àlùfáà kejì àti olùṣọ́nà mẹ́ta;+
19 àti láti inú ìlú ńlá náà, ó mú òṣìṣẹ́ kan láàfin tí ó ní àṣẹ lórí àwọn ọkùnrin ogun, àti ọkùnrin márùn-ún lára àwọn tí ó ní àǹfààní láti dé ọ̀dọ̀ ọba, àwọn tí a rí nínú ìlú ńlá náà; àti akọ̀wé olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni tí ń pe àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ, àti ọgọ́ta ọkùnrin lára àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí a rí nínú ìlú ńlá náà;+
20 nígbà náà ni Nebusárádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ kó wọn,+ ó sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà.+
21 Ọba Bábílónì sì ṣá wọn balẹ̀,+ ó sì fi ikú pa wọ́n ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì.+ Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.+
22 Ní ti àwọn ènìyàn+ tí a fi sílẹ̀ sẹ́yìn ní ilẹ̀ Júdà, àwọn tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ó wá yan Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù+ ọmọkùnrin Ṣáfánì+ ṣe olórí wọn.
23 Nígbà tí gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun,+ àwọn àti àwọn ènìyàn wọn, gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gẹdaláyà+ sípò, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà,+ èyíinì ni, Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà àti Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti Seráyà ọmọkùnrin Táńhúmétì ará Nétófà àti Jaasánáyà ọmọkùnrin ará Máákátì, àwọn àti àwọn ènìyàn wọn.
24 Nígbà náà ni Gẹdaláyà búra+ fún àwọn àti àwọn ènìyàn wọn, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ má fòyà láti jẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ará Kálídíà. Ẹ máa gbé ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ sì máa sin ọba Bábílónì, nǹkan yóò sì lọ dáadáa fún yín.”+
25 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní oṣù keje+ pé Íṣímáẹ́lì+ ọmọkùnrin Netanáyà ọmọkùnrin Élíṣámà lára àwọn ọmọ tí ó jẹ́ ti ọba wá, àti ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ṣá Gẹdaláyà balẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú, àti àwọn Júù àti àwọn ará Kálídíà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mísípà.+
26 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn náà, láti ẹni kékeré dé ẹni ńlá, àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun dìde, wọ́n sì wá sí Íjíbítì;+ nítorí tí àyà ń fò wọ́n nítorí àwọn ará Kálídíà.+
27 Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹtàdínlógójì ìgbèkùn Jèhóákínì+ ọba Júdà, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù náà, pé Efili-méródákì+ ọba Bábílónì, ní ọdún tí ó di ọba, gbé orí+ Jèhóákínì ọba Júdà sókè kúrò ní àtìmọ́lé;
28 ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ ohun rere, ó sì wá gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì.+
29 Ó sì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀;+ ó sì ń jẹ oúnjẹ+ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
30 Ní ti ohun tí a yọ̀ǹda fún un,+ ohun tí a yọ̀ǹda ni a ń fi fún un nígbà gbogbo láti ọ̀dọ̀ ọba, lójoojúmọ́ bí ó ti yẹ, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.