2 Àwọn Ọba 4:1-44

4  Wàyí o, obìnrin kan wà nínú aya àwọn ọmọ àwọn wòlíì,+ tí ó ké wá bá Èlíṣà, pé: “Ìránṣẹ́ rẹ, ọkọ mi, ti kú; ìwọ alára sì mọ̀ ní àmọ̀dunjú pé ìránṣẹ́ rẹ ń bá a lọ ní bíbẹ̀rù+ Jèhófà, ẹni tí a jẹ ní gbèsè+ sì ti wá láti kó àwọn ọmọ mi méjèèjì ṣe ẹrú rẹ̀.”  Látàrí èyí, Èlíṣà sọ fún un pé: “Kí ni kí ń ṣe fún ọ?+ Sọ fún mi; kí ni o ní nínú ilé?” Ó fèsì pé: “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ní nǹkan kan rárá nínú ilé bí kò ṣe ìṣà ẹlẹ́nu àrọ ti òróró.”+  Nígbà náà, ó sọ pé: “Lọ, béèrè fún àwọn ohun èlò fún ara rẹ láti òde, lọ́wọ́ gbogbo aládùúgbò rẹ, àwọn òfìfo ohun èlò. Má fi mọ sí díẹ̀.  Kí o sì lọ, kí o sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, kí o sì dà á sínú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, àwọn tí ó bá ti kún ni kí o yà sọ́tọ̀.”  Látàrí ìyẹn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó ti ilẹ̀kùn mọ́ ara rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, wọ́n ń kó àwọn ohun èlò náà sún mọ́ tòsí rẹ̀, òun sì ń dà á.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí àwọn ohun èlò náà kún, ó sọ fún ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Ṣì tún mú ohun èlò mìíràn sún mọ́ tòsí mi.”+ Ṣùgbọ́n ó sọ fún un pé: “Kò sí ohun èlò mìíràn mọ́.” Látàrí ìyẹn, òróró náà dá.+  Nítorí náà, ó wọlé wá, ó sì sọ fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, òun wá sọ pé: “Lọ, ta òróró náà, kí o sì san àwọn gbèsè+ rẹ, kí ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ máa fi èyí tí ó ṣẹ́ kù jẹun.”+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan pé Èlíṣà ń kọjá lọ sí Ṣúnẹ́mù,+ níbi tí obìnrin kan tí ó yọrí ọlá wà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kàn án nípá+ fún un láti jẹ oúnjẹ. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbàkúùgbà tí ó bá ń kọjá lọ, òun a yà sí ibẹ̀ láti jẹ oúnjẹ.  Nígbà tí ó ṣe, ó sọ fún ọkọ+ rẹ̀ pé: “Kíyè sí i, nísinsìnyí, èmi mọ̀ dáadáa pé ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run+ ni ó ń gba ọ̀dọ̀ wa kọjá nígbà gbogbo. 10  Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a ṣe ìyẹ̀wù òrùlé+ kékeré kan sórí ògiri, kí a sì gbé àga ìrọ̀gbọ̀kú kan àti tábìlì kan àti àga kan àti ọ̀pá fìtílà+ kan síbẹ̀ fún un; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbàkigbà tí ó bá wọlé tọ̀ wá wá kí ó lè yà sí ibẹ̀.”+ 11  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan pé, bí ti tẹ́lẹ̀ rí, ó wọlé wá sí ibẹ̀, ó sì yà sí ìyẹ̀wù òrùlé náà, ó sì dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀. 12  Nítorí náà, ó sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀, Géhásì,+ pé: “Pe obìnrin ará Ṣúnẹ́mù+ yìí wá.” Látàrí ìyẹn, ó pè é kí ó lè dúró níwájú rẹ̀. 13  Nígbà náà ni ó sọ fún un pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún un pé, ‘Kíyè sí i, ìwọ ti fi gbogbo ìkálọ́wọ́kò+ yìí ká ara rẹ lọ́wọ́ kò nítorí tiwa. Kí ní ń bẹ tí a lè ṣe fún ọ?+ Ohun kan ha wà tí a lè bá ọ sọ fún ọba+ tàbí fún olórí+ ẹgbẹ́ ọmọ ogun?’” Ó fèsì pé: “Àárín àwọn ènìyàn mi ni mo ń gbé.”+ 14  Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kí wá ni ó wà tí a lè ṣe fún un?” Nígbà náà ni Géhásì sọ pé: “Ní ti tòótọ́, kò ní ọmọkùnrin kankan,+ ọkọ rẹ̀ sì ti darúgbó.” 15  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Pè é.” Nítorí náà, ó pè é, obìnrin náà sì dúró ní ẹnu ọ̀nà. 16  Nígbà náà ni ó sọ pé: “Ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ yìí ní ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò máa gbé ọmọkùnrin kan mọ́ra.”+ Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Rárá, ọ̀gá mi, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́! Má ṣe purọ́ nípa ìránṣẹ́bìnrin rẹ.” 17  Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin+ kan ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ náà ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, gan-an gẹ́gẹ́ bí Èlíṣà ṣe sọ fún un.+ 18  Ọmọ náà sì ń dàgbà nìṣó, ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan pé ó jáde lọ bí ti tẹ́lẹ̀ rí, láti lọ bá baba rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn akárúgbìn.+ 19  Ó sì ń sọ ṣáá fún baba rẹ̀ pé: “Orí mi, orí mi o!”+ Níkẹyìn, ó sọ fún ẹmẹ̀wà pé: “Gbé e lọ fún ìyá rẹ̀.”+ 20  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó gbé e, ó sì gbé e wá fún ìyá rẹ̀. Ó sì ń bá a lọ ní jíjókòó lórí eékún rẹ̀ títí di ọ̀sán gangan, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú.+ 21  Nígbà náà ni ó gòkè lọ, ó sì tẹ́ ẹ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú+ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn, ó sì jáde lọ. 22  Wàyí o, ó pe ọkọ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, fi ọ̀kan lára àwọn ẹmẹ̀wà àti ọ̀kan lára àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ránṣẹ́ sí mi, sì jẹ́ kí n sáré dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ kí n sì padà.”+ 23  Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Èé ṣe tí o fi ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí? Kì í ṣe òṣùpá tuntun+ tàbí sábáàtì.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó sọ pé: “Dáadáa ni.” 24  Nítorí náà, ó di abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ ní gàárì, ó sì sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: “Gbéra, kí o sì tẹ̀ síwájú. Má ṣe dáwọ́ eré dúró nítorí tèmi, bí kò ṣe pé mo bá wí bẹ́ẹ̀ fún ọ.” 25  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ, ó sì dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ní Òkè Ńlá Kámẹ́lì. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ rí i níwájú, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún ẹmẹ̀wà+ rẹ̀, Géhásì, pé: “Wò ó! Obìnrin ará Ṣúnẹ́mù náà nìyẹn. 26  Wàyí o, jọ̀wọ́, sáré lọ pàdé rẹ̀, kí o sì sọ fún un pé, ‘Ṣé dáadáa ni o wà? Ṣé dáadáa ni ọkọ rẹ wà? Ṣé dáadáa ni ọmọ náà wà?’” Ó fèsì pé: “Dáadáa ni.” 27  Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ní òkè ńlá náà, kíákíá, ó dì í mú ní ẹsẹ̀.+ Látàrí èyí, Géhásì sún mọ́ tòsí láti tì í kúrò,+ ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run+ tòótọ́ sọ pé: “Jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́,+ nítorí ọkàn rẹ̀ korò+ nínú rẹ̀; Jèhófà tìkára rẹ̀ sì fi í pa mọ́+ fún mi, kò sí sọ ọ́ fún mi.” 28  Ó sọ wàyí pé: “Ṣé mo béèrè ọmọkùnrin nípasẹ̀ olúwa mi? Èmi kò ha sọ pé, ‘Má ṣamọ̀nà mi sí ìrètí èké’?”+ 29  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún Géhásì+ pé: “Di abẹ́nú+ rẹ lámùrè, kí o sì mú ọ̀pá+ mi ní ọwọ́ rẹ, kí o sì lọ. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o bá ẹnikẹ́ni pàdé, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kí i;+ bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni kí ọ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn. Kí o sì fi ọ̀pá mi lé ojú ọmọdékùnrin+ náà.” 30  Látàrí èyí, ìyá ọmọdékùnrin náà sọ pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ+ àti bí ọkàn rẹ ti ń bẹ,+ dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.”+ Nítorí náà, ó dìde, ó sì bá a lọ. 31  Géhásì alára sì kọjá lọ ṣáájú wọn, ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọdékùnrin náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn tàbí àfiyèsí.+ Nítorí náà, ó padà wá pàdé rẹ̀, ó sì sọ fún un, ó wí pé: “Ọmọdékùnrin náà kò jí.”+ 32  Níkẹyìn, Èlíṣà wọnú ilé náà, kíyè sí i, ọmọdékùnrin náà ti kú, a tẹ́ ẹ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú+ rẹ̀. 33  Nígbà náà ni ó wọlé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà.+ 34  Níkẹyìn, ó gòkè lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lé ọmọ+ náà, ó sì fi ẹnu tirẹ̀ lé ẹnu rẹ̀ àti ojú tirẹ̀ lé ojú rẹ̀ àti àtẹ́lẹwọ́ tirẹ̀ lé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó sì tẹ̀ ba lé e lórí, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara ọmọ náà sì wá móoru. 35  Lẹ́yìn náà, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú ilé, lẹ́ẹ̀kan sí ìhà ìhín àti lẹ́ẹ̀kan sí ìhà ọ̀hún, lẹ́yìn èyí tí ó gòkè lọ, tí ó sì tẹ̀ ba lé e lórí. Ọmọdékùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sín ní èyí tí ó tó ìgbà méje, lẹ́yìn èyí tí ọmọdékùnrin náà la ojú+ rẹ̀. 36  Nígbà náà ni ó pe Géhásì, ó sì sọ pé: “Pe obìnrin ará Ṣúnẹ́mù+ yìí wá.” Nítorí náà, ó pè é, ó sì wọlé tọ̀ ọ́ wá. Nígbà náà ni ó sọ pé: “Gbé ọmọkùnrin+ rẹ.” 37  Ó sì wọlé, ó sì wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀+ fún un, lẹ́yìn èyí tí ó gbé ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì jáde lọ.+ 38  Èlíṣà alára sì padà sí Gílígálì,+ ìyàn+ sì wà ní ilẹ̀ náà. Bí àwọn ọmọ àwọn wòlíì+ ti jókòó níwájú rẹ̀,+ nígbà tí ó ṣe, ó sọ fún ẹmẹ̀wà+ rẹ̀ pé: “Gbé ìkòkò ìse-oúnjẹ títóbi kaná, kí o sì se ọbẹ̀ fún àwọn ọmọ àwọn wòlíì.”+ 39  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọ̀kan jáde lọ sí pápá láti já ewéko málò,+ ó sì wá rí àjàrà ìgbẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ká tàgíìrì lórí rẹ̀, ẹ̀kún ẹ̀wù rẹ̀, lẹ́yìn náà, ó wá, ó sì gé e pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ sínú ìkòkò ọbẹ̀ náà, nítorí tí wọn kò mọ ohun tí ó jẹ́. 40  Lẹ́yìn náà, wọ́n dà á fún àwọn ọkùnrin náà láti jẹ. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n jẹ lára ọbẹ̀ náà, wọ́n ké jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ ikú ń bẹ nínú ìkòkò+ náà.” Wọn kò sì lè jẹun. 41  Nítorí náà, ó sọ pé: “Nígbà náà, ẹ wá ìyẹ̀fun wá.” Lẹ́yìn tí ó bù ú sínú ìkòkò náà, ó ń bá a lọ láti sọ pé: “Dà á fún àwọn ènìyàn náà kí wọ́n lè jẹun.” Kò sì sí ohun aṣeniléṣe kankan tí ó wà nínú ìkòkò+ náà mọ́. 42  Ọkùnrin kan sì wà tí ó wá láti Baali-ṣálíṣà,+ ó sì mú oúnjẹ àwọn àkọ́pọ́n èso,+ ogún ìṣù ọkà bálì,+ àti ọkà tuntun nínú àpò oúnjẹ rẹ̀ wá+ fún ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́. Nígbà náà ni ó sọ pé: “Fi í fún àwọn ènìyàn náà kí wọ́n lè jẹun.”+ 43  Bí ó ti wù kí ó rí, aṣèránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú ọgọ́rùn-ún ènìyàn?”+ Ó fèsì pé: “Fi í fún àwọn ènìyàn náà kí wọ́n lè jẹun, nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Jíjẹ àti àjẹṣẹ́kù+ yóò ṣẹlẹ̀.’” 44  Látàrí ìyẹn, ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun, wọ́n sì jẹ àjẹṣẹ́kù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé