2 Àwọn Ọba 7:1-20
7 Wàyí o, Èlíṣà sọ pé: “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní ìwòyí ọ̀la, òṣùwọ̀n séà ìyẹ̀fun kíkúnná kan yóò di ṣékélì kan, òṣùwọ̀n séà ọkà bálì kan yóò sì di ṣékélì kan ní ojú ọ̀nà ibodè Samáríà.’”+
2 Látàrí ìyẹn, olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tí ọba ń fara ti+ ọwọ́ rẹ̀, dá ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ lóhùn, ó sì sọ pé: “Ká ní Jèhófà ṣe àwọn ibodè ibú omi sí ojú ọ̀run,+ nǹkan yìí ha lè ṣẹlẹ̀+ bí?” Ó fèsì pé: “Kíyè sí i, ìwọ yóò fi ojú+ rẹ rí i, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ+ nínú rẹ̀.”
3 Àwọn ọkùnrin mẹ́rin sì wà, adẹ́tẹ̀ ni wọ́n, tí ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n wà ní ibi àtiwọ ẹnubodè;+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Èé ṣe tí a fi jókòó síhìn-ín títí a ó fi kú?
4 Bí a bá sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a wọ ìlú ńlá lọ,’ nígbà tí ìyàn wà nínú ìlú ńlá, ibẹ̀ ni a óò kú sí.+ Bí a bá sì jókòó síhìn-ín, kíkú ni a óò kú pẹ̀lú. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a já wọ inú ibùdó àwọn ará Síríà. Bí wọ́n bá pa wá mọ́ láàyè, àwa yóò wà láàyè; ṣùgbọ́n bí wọ́n bá fi ikú pa wá, kíkú ni a óò kú.”+
5 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n dìde nínú òkùnkùn alẹ́ láti wọ ibùdó àwọn ará Síríà; wọ́n sì ń lọ títí dé ẹ̀yìn odi ibùdó àwọn ará Síríà, sì wò ó! kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀.
6 Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ti mú kí ibùdó àwọn ará Síríà gbọ́+ ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun, ìró àwọn ẹṣin, ìró ẹgbẹ́ ológun+ ńláǹlà, tí wọ́n fi wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Wò ó! Ọba Ísírẹ́lì ti háyà àwọn ọba àwọn ọmọ Hétì+ àti àwọn ọba Íjíbítì+ sí wa, láti wá gbéjà kò wá!”
7 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n dìde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ nínú òkùnkùn alẹ́,+ wọ́n sì fi àwọn àgọ́ wọn àti àwọn ẹṣin+ wọn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀—ní bí ibùdó náà ṣe wà gẹ́lẹ́—wọ́n sì ń sá lọ nítorí ọkàn+ wọn.
8 Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ wọ̀nyí dé ẹ̀yìn odi ibùdó náà, nígbà náà ni wọ́n wọnú àgọ́ kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà àti wúrà àti ẹ̀wù lọ láti ibẹ̀, wọ́n sì lọ dì wọ́n pa mọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n padà wá, wọ́n sì wọnú àgọ́ mìíràn, wọ́n sì kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀, wọ́n sì lọ dì wọ́n pa mọ́.+
9 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ohun tí a ń ṣe kò tọ́. Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìhìn rere!+ Bí a bá lọ́ tìkọ̀, tí a sì dúró ní ti tòótọ́ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, ẹ̀bi yóò lé wa bá.+ Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a wọlé, kí a sì ròyìn ní ilé ọba.”
10 Nítorí náà, wọ́n wá, wọ́n sì pe àwọn aṣọ́bodè+ ìlú ńlá náà, wọ́n sì ròyìn fún wọn, pé: “A dé inú ibùdó àwọn ará Síríà, sì wò ó! kò sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìró ènìyàn kankan, bí kò ṣe kìkì àwọn ẹṣin tí a dè àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a dè àti àwọn àgọ́ ní bí wọ́n ṣe wà gẹ́lẹ́.”+
11 Lójú-ẹsẹ̀, àwọn aṣọ́bodè pè, wọ́n sì ròyìn fún ilé ọba nínú lọ́hùn-ún.
12 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọba dìde ní òru, ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí àwọn ará Síríà ṣe sí wa+ fún yín. Wọ́n mọ̀ ní àmọ̀dunjú pé ebi ń pa+ wá; nítorí náà, wọ́n jáde kúrò nínú ibùdó láti fi ara wọn pa mọ́ ní pápá,+ wọ́n wí pé, ‘Wọn yóò jáde wá láti inú ìlú ńlá, àwa yóò sì mú wọn láàyè, àwa yóò sì wọnú ìlú ńlá lọ.’”
13 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n mú márùn-ún lára àwọn àṣẹ́kù ẹṣin tí ó ṣẹ́ kù nínú ìlú ńlá.+ Wò ó! Wọ́n jẹ́ bákan náà bí gbogbo ogunlọ́gọ̀ Ísírẹ́lì tí ó ṣẹ́ kù nínú rẹ̀. Wò ó! Wọ́n jẹ́ bákan náà bí gbogbo ogunlọ́gọ̀ Ísírẹ́lì tí ó ti ṣègbé.+ Sì jẹ́ kí a ránṣẹ́ jáde lọ wò ó.”
14 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ẹṣin méjì pẹ̀lú àwọn ẹṣin, ọba sì rán wọn jáde tẹ̀ lé ibùdó àwọn ará Síríà, ó wí pé: “Ẹ lọ wò ó.”
15 Látàrí ìyẹn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé wọn títí dé Jọ́dánì; sì wò ó! gbogbo ọ̀nà ni ó kún fún ẹ̀wù àti àwọn nǹkan èlò+ tí àwọn ará Síríà ti kó sọnù bí wọ́n ti ń kánjú lọ.+ Nígbà náà ni àwọn ońṣẹ́ náà padà, wọ́n sì ròyìn fún ọba.
16 Àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ, wọ́n sì piyẹ́+ ibùdó àwọn ará Síríà; nítorí náà, òṣùwọ̀n séà ìyẹ̀fun kíkúnná wá di ṣékélì kan, òṣùwọ̀n séà ọkà bálì sì di ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀+ Jèhófà.
17 Ọba alára sì ti yan olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, ẹni tí ọba ń fara ti+ ọwọ́ rẹ̀, láti bójú tó ojú ọ̀nà ibodè; àwọn ènìyàn sì ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀+ ní ojú ọ̀nà ibodè, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ,+ nígbà tí ó sọ̀rọ̀ ní ìgbà tí ọba sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀.
18 Bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ ṣe sọ fún ọba, pé: “Òṣùwọ̀n séà ọkà bálì méjì tí ó di ṣékélì kan àti òṣùwọ̀n séà ìyẹ̀fun kíkúnná kan tí ó di ṣékélì kan yóò wáyé ní ìwòyí ọ̀la ní ojú ọ̀nà ibodè Samáríà.”+
19 Ṣúgbọ̀n olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun dá ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́ lóhùn, ó sì wí pé: “Ká tilẹ̀ ní Jèhófà ṣe àwọn ibodè ibú omi sí ojú ọ̀run, ó ha lè ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí?”+ Ó fèsì pé: “Kíyè sí i, ìwọ yóò fi ojú rẹ rí i, ṣùgbọ́n ìwọ kí yóò jẹ nínú rẹ̀.”+
20 Bẹ́ẹ̀ ni+ ó sì ṣe ṣẹlẹ̀ sí i, nígbà tí àwọn ènìyàn ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀+ ní ojú ọ̀nà ibodè, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú.