2 Kíróníkà 24:1-27
24 Ẹni ọdún méje ni Jèhóáṣì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba,+ ogójì ọdún sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Sibáyà láti Bíá-ṣébà.+
2 Jèhóáṣì+ sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà+ ní gbogbo ọjọ́ Jèhóádà àlùfáà.+
3 Jèhóádà sì tẹ̀ síwájú láti fẹ́ aya méjì fún un, ó sì wá bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.+
4 Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé ó wà ní góńgó ọkàn-àyà Jèhóáṣì láti tún ilé Jèhófà ṣe.+
5 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó kó àwọn àlùfáà+ àti àwọn ọmọ Léfì jọpọ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ jáde lọ sí àwọn ìlú ńlá Júdà kí ẹ sì gba owó lọ́wọ́ gbogbo Ísírẹ́lì láti máa fi tún ilé Ọlọ́run yín ṣe+ láti ọdún dé ọdún;+ kí ẹ̀yin, ní tiyín, sì gbé ìgbésẹ̀ kíákíá nínú ọ̀ràn náà.” Àwọn ọmọ Léfì kò sì gbé ìgbésẹ̀ kíákíá.+
6 Nítorí náà, ọba pe Jèhóádà olórí, ó sì wí fún un+ pé: “Èé ṣe tí ẹ kò tíì béèrè fún ìjíhìn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Léfì fún mímú owó orí ọlọ́wọ̀ tí Mósè+ ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ wọlé wá láti Júdà àti Jerúsálẹ́mù, àní ti ìjọ Ísírẹ́lì, fún àgọ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí?+
7 Nítorí ní ti Ataláyà obìnrin burúkú náà, àwọn ọmọ+ rẹ̀ ti fọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ àní gbogbo àwọn ohun mímọ́+ ilé Jèhófà ni wọ́n sì ti fi rúbọ sí àwọn Báálì.”+
8 Nígbà náà ni ọba sọ ọ̀rọ̀ náà, nítorí náà, wọ́n kan àpótí+ kan, wọ́n sì gbé e sí òde ẹnubodè ilé Jèhófà.
9 Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbé ìpè kan jáde jákèjádò Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n mú owó orí ọlọ́wọ̀,+ tí Mósè+ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ lórí Ísírẹ́lì ní aginjù, wá fún Jèhófà.
10 Gbogbo àwọn ọmọ aládé+ àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀,+ wọ́n sì ń mú un wá ṣáá, wọ́n sì ń jù ú sínú àpótí+ náà títí gbogbo wọ́n fi mú wá.
11 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu, òun a gbé àpótí náà wá sábẹ́ àbójútó ọba nípa ọwọ́ àwọn ọmọ Léfì,+ àti pé, gbàrà tí wọ́n bá ti rí i pé owó pọ̀ rẹpẹtẹ,+ akọ̀wé+ ọba àti kọmíṣọ́nnà olórí àlùfáà a wá, wọn a sì da àpótí náà, wọn a sì gbé e sókè, wọn a sì dá a padà sí àyè rẹ̀. Bí wọ́n ti ń ṣe nìyẹn láti ọjọ́ dé ọjọ́, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kó owó jọ ní ọ̀pọ̀ yanturu.
12 Lẹ́yìn náà ni ọba àti Jèhóádà a fi í fún àwọn olùṣe+ iṣẹ́ tí ó jẹ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà,+ wọ́n sì wá jẹ́ olùháyà àwọn agékùúta+ àti àwọn oníṣẹ́ ọnà+ fún títún ilé Jèhófà+ ṣe, àti àwọn oníṣẹ́ irin àti bàbà pẹ̀lú fún títún ilé Jèhófà ṣe.+
13 Àwọn olùṣe iṣẹ́ náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe,+ iṣẹ́ àtúnṣe náà sì ń tẹ̀ síwájú nìṣó ní ọwọ́ wọn, níkẹyìn, wọ́n mú kí ilé Ọlọ́run tòótọ́ dúró ní bí ó ṣe yẹ kí ó dúró, wọ́n sì mú kí ó lágbára.
14 Gbàrà tí wọ́n sì ṣe tán, wọ́n kó ìyókù owó náà wá síwájú ọba àti Jèhóádà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn nǹkan èlò fún ilé Jèhófà, àwọn nǹkan èlò fún iṣẹ́ òjíṣẹ́+ àti fún rírú àwọn ọrẹ ẹbọ àti àwọn ife+ àti àwọn nǹkan èlò wúrà+ àti ti fàdákà; wọ́n sì wá jẹ́ olùrú àwọn ẹbọ sísun+ nínú ilé Jèhófà nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jèhóádà.
15 Jèhóádà sì wá darúgbó, ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún àwọn ọdún,+ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó kú, ó jẹ́ ẹni àádóje ọdún nígbà ikú rẹ̀.
16 Nítorí náà, wọ́n sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọba,+ nítorí pé ó ti ṣe rere ní Ísírẹ́lì+ àti sí Ọlọ́run tòótọ́ àti ilé Rẹ̀.
17 Lẹ́yìn ikú Jèhóádà, àwọn ọmọ aládé+ Júdà wọlé wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún ọba. Ní àkókò yẹn, ọba fetí sí wọn.+
18 Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ àti àwọn òrìṣà,+ tí ó fi jẹ́ pé ìkannú wá wà lòdì sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù nítorí ẹ̀bi wọn yìí.+
19 Ó sì ń rán àwọn wòlíì+ sáàárín wọn ṣáá láti mú wọn padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà; wọ́n sì ń jẹ́rìí lòdì sí wọn ṣáá, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sí i.+
20 Ẹ̀mí+ Ọlọ́run sì bo+ Sekaráyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà+ àlùfáà, tí ó fi dìde dúró lókè àwọn ènìyàn náà tí ó sì wí fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ wí, ‘Èé ṣe tí ẹ fi ń tẹ àwọn àṣẹ Jèhófà lójú, tí ẹ kò fi lè ṣe àṣeyọrí sí rere?+ Nítorí pé ẹ ti fi Jèhófà sílẹ̀, òun, ẹ̀wẹ̀, yóò fi yín sílẹ̀.’”+
21 Níkẹyìn, wọ́n di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí i,+ wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta+ nípa àṣẹ ọba, ní àgbàlá ilé Jèhófà.
22 Jèhóáṣì Ọba kò sì rántí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhóádà baba rẹ̀ ṣe sí i,+ tí ó fi pa ọmọkùnrin rẹ̀, ẹni tí ó wí, nígbà tí ó dé ojú ikú, pé: “Kí Jèhófà rí sí i, kí ó sì béèrè rẹ̀ padà.”+
23 Ó sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìyípo+ ọdún pé ẹgbẹ́ ológun Síríà+ gòkè wá gbéjà kò ó,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti Júdà àti Jerúsálẹ́mù. Nígbà náà ni wọ́n run gbogbo ọmọ aládé+ àwọn ènìyàn náà kúrò láàárín àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì fi gbogbo ohun ìfiṣèjẹ wọn ránṣẹ́ sí ọba Damásíkù.+
24 Nítorí iye àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ẹgbẹ́ ológun àwọn ará Síríà fi gbógun tì wọ́n,+ Jèhófà tìkára rẹ̀ sì fi ẹgbẹ́ ológun tí iye rẹ̀ pọ̀ gan-an lé wọn lọ́wọ́,+ nítorí pé wọ́n ti fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀; wọ́n sì mú àwọn ìgbésẹ̀ ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí Jèhóáṣì.+
25 Nígbà tí wọ́n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ (nítorí wọ́n fi í sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkùnrùn),+ àwọn ìránṣẹ́ òun fúnra rẹ̀ di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun+ sí i nítorí ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọmọkùnrin Jèhóádà+ àlùfáà; wọ́n sì wá pa á lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú.+ Nígbà náà ni wọ́n sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì,+ ṣùgbọ́n wọn kò sin ín sí àwọn ibi ìsìnkú àwọn ọba.+
26 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí ó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí i: Sábádì+ ọmọkùnrin Ṣíméátì ọmọbìnrin Ámónì àti Jèhósábádì ọmọkùnrin Ṣímúrítì ọmọbìnrin Móábù.
27 Ní ti àwọn ọmọ rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí i+ àti fífìdí ilé Ọlọ́run tòótọ́ múlẹ̀,+ ibẹ̀ ni a kọ wọ́n sí nínú ìgbékalẹ̀ àlàyé Ìwé+ Àwọn Ọba. Amasááyà+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.