2 Kíróníkà 26:1-23

26  Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn+ Júdà mú Ùsáyà,+ tí í ṣe ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún, wọ́n sì fi í+ jẹ ọba ní ipò Amasááyà+ baba rẹ̀.  Òun ni ó tún Élótì+ kọ́ tí ó sì wá mú un padà fún Júdà lẹ́yìn tí ọba ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.+  Ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ni Ùsáyà+ nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba, ọdún méjì-lé-láàádọ́ta sì ni ó fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoláyà+ ti Jerúsálẹ́mù.  Ó sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,+ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Amasááyà baba rẹ̀ ṣe.+  Ó sì ń bá a lọ ní títẹ̀ sí wíwá+ Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ Sekaráyà, olùkọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́;+ àti pé, ní àwọn ọjọ́ tí ó wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.+  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ, ó sì bá àwọn Filísínì jà,+ ó sì fọ́ ògiri Gátì+ àti ògiri Jábínè+ àti ògiri Áṣídódì,+ lẹ́yìn èyí tí ó kọ́ àwọn ìlú ńlá sí ìpínlẹ̀ Áṣídódì+ àti sáàárín àwọn Filísínì.  Ọlọ́run tòótọ́ sì ń bá a lọ láti ràn án lọ́wọ́+ ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn Filísínì àti ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ tí ń gbé ní Gọbáálì àti àwọn Méúnímù.+  Àwọn ọmọ Ámónì+ sì bẹ̀rẹ̀ sí fún Ùsáyà ní owó òde.+ Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, òkìkí+ rẹ̀ kàn títí dé Íjíbítì, nítorí pé ó fi okun hàn dé ìwọ̀n àrà ọ̀tọ̀.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ùsáyà kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́bàá Ẹnubodè Igun+ àti lẹ́bàá Ẹnubodè Àfonífojì+ àti lẹ́bàá Ìtì Ògiri, ó sì sọ wọ́n di alágbára. 10  Síwájú sí i, ó kọ́ àwọn ilé gogoro+ sí aginjù, ó sì gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkùdu (nítorí ohun ọ̀sìn tí ó jẹ́ tirẹ̀ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀), àti sí Ṣẹ́fẹ́là+ pẹ̀lú àti sí ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ. Àwọn àgbẹ̀ àti olùrẹ́wọ́ àjàrà ń bẹ ní àwọn òkè ńlá àti ní Kámẹ́lì, nítorí ó jẹ́ olùfẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀. 11  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ùsáyà wá ní agbo ọmọ ogun tí ń ja ogun,+ àwọn tí ń jáde lọ sínú iṣẹ́ ìsìn ológun ní ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun, ní ìbámu pẹ̀lú iye ìforúkọsílẹ̀+ wọn láti ọwọ́ Jéélì akọ̀wé+ àti Maaseáyà tí í ṣe onípò àṣẹ, lábẹ́ ìdarí+ Hananáyà láti inú àwọn ọmọ aládé ọba.+ 12  Gbogbo iye olórí ìdí ilé àwọn baba+ pátá, àwọn akíkanjú,+ alágbára ńlá ọkùnrin,+ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá. 13  Lábẹ́ ìdarí wọn, àwọn agbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dégbèjìdínlógójì ọkùnrin tí ń ja ogun pẹ̀lú agbára ẹgbẹ́ ológun láti ran ọba lọ́wọ́ ní ìdojú-ìjà-kọ ọ̀tá.+ 14  Ùsáyà sì ń bá a lọ láti pèsè apata+ àti aṣóró+ àti àṣíborí+ àti ẹ̀wù tí a fi àdàrọ irin ṣe+ àti ọrun+ àti òkúta kànnàkànnà+ sílẹ̀ fún wọn, fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà pátá. 15  Síwájú sí i, ó ṣe àwọn ẹ̀rọ ogun ní Jerúsálẹ́mù, ìhùmọ̀ àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, kí wọ́n lè wá wà lórí àwọn ilé gogoro+ àti lórí àwọn igun odi, láti máa ta ọfà àti àwọn òkúta ńlá. Nítorí náà, òkìkí+ rẹ̀ kàn dé ọ̀nà jíjìnréré, nítorí a ràn án lọ́wọ́ lọ́nà àgbàyanu títí ó fi di alágbára. 16  Àmọ́ ṣá o, gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera+ àní títí dé àyè tí ń fa ìparun,+ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.+ 17  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Asaráyà àlùfáà àti pẹ̀lú rẹ̀ àwọn àlùfáà Jèhófà, ọgọ́rin akíkanjú ọkùnrin, wọlé tẹ̀ lé e. 18  Nígbà náà ni wọ́n dìde dúró lòdì sí Ùsáyà Ọba,+ wọ́n sì wí fún un pé: “Kì í ṣe iṣẹ́ rẹ,+ Ùsáyà, láti sun tùràrí sí Jèhófà, ṣùgbọ́n ó jẹ́ iṣẹ́ àwọn àlùfáà àwọn ọmọ Áárónì,+ àwọn tí a ti sọ di mímọ́, láti sun tùràrí. Jáde kúrò ní ibùjọsìn; nítorí o ti ṣe àìṣòótọ́, kì í sì í ṣe ògo+ kankan fún ọ níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run.” 19  Ṣùgbọ́n Ùsáyà kún fún ìhónú+ nígbà tí àwo tùràrí+ fún sísun tùràrí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, àti pé, nígbà ìhónú rẹ̀ sí àwọn àlùfáà, ẹ̀tẹ̀+ yọ+ ní iwájú orí rẹ̀ níwájú àwọn àlùfáà nínú ilé Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tùràrí. 20  Nígbà tí Asaráyà olórí àlùfáà àti gbogbo àlùfáà yíjú sí i, họ́wù, kíyè sí i, a ti fi ẹ̀tẹ̀ kọlù ú ní iwájú orí rẹ̀!+ Nítorí náà, wọ́n taraṣàṣà mú un kúrò níbẹ̀, òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú sì ṣe kánkán láti jáde, nítorí pé Jèhófà ti kọlù ú.+ 21  Ùsáyà+ Ọba sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ adẹ́tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó sì ń gbé ní ilé kan ní ẹni tí a yọ kúrò lẹ́nu iṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí adẹ́tẹ̀;+ nítorí a ti yà á nípa sí ilé Jèhófà, nígbà tí Jótámù ọmọkùnrin rẹ̀ ń bójú tó ilé ọba, tí ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 22  Àti ìyókù àlámọ̀rí Ùsáyà,+ ti àkọ́kọ́ àti ti ìkẹyìn, ni Aísáyà+ ọmọkùnrin Émọ́sì+ wòlíì ti kọ. 23  Níkẹyìn, Ùsáyà dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀; nítorí náà, wọ́n sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, ṣùgbọ́n ní pápá ìsìnkú tí ó jẹ́ ti àwọn ọba,+ nítorí wọ́n wí pé: “Adẹ́tẹ̀ ni.” Jótámù+ ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jọba ní ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé