2 Sámúẹ́lì 18:1-33
18 Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí ka iye àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì fi àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ ṣe olórí wọn.
2 Síwájú sí i, Dáfídì rán ìdá mẹ́ta+ àwọn ènìyàn náà ní ìkáwọ́ Jóábù+ àti ìdá mẹ́ta ní ìkáwọ́ Ábíṣáì+ ọmọkùnrin Seruáyà, arákùnrin Jóábù,+ àti ìdá mẹ́ta ní ìkáwọ́ Ítítáì+ ará Gátì. Nígbà náà ni ọba sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: “Èmi fúnra mi yóò bá yín jáde lọ pẹ̀lú láìsí àní-àní.”
3 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà sọ pé: “Ìwọ kì yóò jáde lọ,+ nítorí bí a bá tilẹ̀ sá, wọn kì yóò fi ọkàn-àyà wọn sí wa lára;+ bí ìdajì wa bá sì kú, wọn kì yóò fi ọkàn-àyà wọn sí wa lára, nítorí tí ìwọ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá wa;+ wàyí o, yóò sàn bí ìwọ yóò bá wúlò fún wa láti máa fún wa ní ìrànlọ́wọ́+ láti inú ìlú ńlá wá.”
4 Nítorí náà, ọba sọ fún wọn pé: “Ohun yòówù tí ó bá dára ní ojú yín ni èmi yóò ṣe.”+ Ọba sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè,+ gbogbo àwọn ènìyàn náà sì jáde lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.+
5 Ọba sì ń bá a lọ láti pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítítáì, pé: “Ẹ ṣe ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́+ nítorí mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí nítorí ọ̀ràn Ábúsálómù.
6 Àwọn ènìyàn náà sì bá ọ̀nà wọn jáde lọ sí pápá láti pàdé Ísírẹ́lì; ìjà ogun náà sì wá jẹ́ ní igbó Éfúráímù.+
7 Níkẹyìn, a ṣẹ́gun+ àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì+ níbẹ̀ níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, ìfikúpa tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì já sí èyí tí ó pọ̀ ní ọjọ́ yẹn, ọ̀kẹ́ kan ènìyàn.
8 Ìjà ogun tí ó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì wá tàn kálẹ̀ dé gbogbo ilẹ̀ tí ojú lè rí. Síwájú sí i, igbó ṣe èyí tí ó pọ̀ ní jíjẹ àwọn ènìyàn náà run ju èyí tí idà ṣe ní jíjẹ wọ́n run ní ọjọ́ yẹn.
9 Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Ábúsálómù bá ara rẹ̀ níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Ìbaaka sì ni Ábúsálómù gùn, ìbaaka náà sì wá sábẹ́ àwọn ẹ̀tun tí ó so kọ́ra lára igi ńlá ràbàtà kan, tí ó fi jẹ́ pé orí rẹ̀ há sórí igi ńlá náà pinpin, ó sì rọ̀ dirodiro láàárín ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,+ níwọ̀n bí ìbaaka náà tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ ti kọjá lọ.
10 Nígbà náà ni ọkùnrin kan rí i, ó sì sọ fún Jóábù,+ ó sì wí pé: “Wò ó! Mo rí i tí Ábúsálómù so rọ̀ sórí igi ńlá kan.”
11 Látàrí èyí, Jóábù sọ fún ọkùnrin tí ń sọ fún un pé: “Kíyè sí i, ìwọ rí i, èé sì ti ṣe tí ìwọ kò fi ṣá a balẹ̀ níbẹ̀? Nígbà náà, ì bá ti jẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe tèmi láti fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá àti ìgbànú kan.”+
12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sọ fún Jóábù pé: “Ká ní èmi tilẹ̀ ń wọn ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà ní àtẹ́lẹwọ́ mi, èmi kò ní na ọwọ́ mi jáde lòdì sí ọmọ ọba; nítorí etí-ìgbọ́ wa ni ọba ti pàṣẹ fún ìwọ àti Ábíṣáì àti Ítítáì, pé, ‘Ẹ ṣọ́ ara yín, ẹnì yòówù tí ì báà jẹ́, lórí ọ̀dọ́kùnrin náà, lórí Ábúsálómù.’+
13 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi ì bá ti ṣe àdàkadekè sí ọkàn rẹ̀, gbogbo ọ̀ràn náà pàápàá kì bá sì pa mọ́ fún ọba,+ ìwọ fúnra rẹ ì bá sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”
14 Látàrí èyí, Jóábù fèsì pé: “Má ṣe jẹ́ kí n dá ara mi dúró lọ́nà yìí níwájú rẹ!” Pẹ̀lú ìyẹn, ó kó ọ̀kọ̀ tẹ́ẹ́rẹ́ mẹ́ta sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó sì tẹ̀ síwájú láti fi wọ́n gún+ ọkàn-àyà Ábúsálómù ní àgúnyọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè ní àárín+ igi ńlá náà.
15 Nígbà náà ni àwọn ẹmẹ̀wà mẹ́wàá tí ń ru àwọn ohun ìjà Jóábù sún mọ́ tòsí, wọ́n sì kọlu Ábúsálómù, kí wọ́n lè fi ikú pa á.+
16 Jóábù fun ìwo+ wàyí, kí àwọn ènìyàn náà lè padà ní lílépa Ísírẹ́lì; nítorí Jóábù ti dá àwọn ènìyàn náà dúró.
17 Níkẹyìn, wọ́n gbé Ábúsálómù sọ sínú igbó, sínú kòtò ńlá kan, wọ́n sì kó òkúta jọ pèlèmọ̀-pelemọ lé e lórí.+ Ní ti gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sá lọ, olúkúlùkù ọkùnrin, sí ilé rẹ̀.
18 Wàyí o, Ábúsálómù fúnra rẹ̀, nígbà tí ó wà láàyè, ti gbé ọwọ̀n kan, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé e nà ró fún ara rẹ̀,+ èyí tí ó wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Ọba,+ nítorí ó sọ pé: “Èmi kò ní ọmọkùnrin láti lè pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí.”+ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe ọwọ̀n náà,+ a sì ń bá a lọ láti pè é ní Ohun Ìránnilétí Ábúsálómù títí di òní yìí.
19 Wàyí o, ní ti Áhímáásì+ ọmọkùnrin Sádókù, ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sáré lọ ro ìhìn náà fún ọba, nítorí pé Jèhófà ti ṣe ìdájọ́ fún un láti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+
20 Ṣùgbọ́n Jóábù sọ fún un pé: “Ìwọ kì í ṣe amúhìnwá lónìí yìí, ìwọ yóò sì ro ìhìn ní ọjọ́ mìíràn; ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò ro ìhìn, nítorí ìdí náà pé ọmọkùnrin ọba ti kú.”+
21 Nígbà náà ni Jóábù sọ fún ọmọ Kúṣì pé:+ “Lọ, sọ ohun tí ìwọ rí fún ọba.” Látàrí ìyẹn, ọmọ Kúṣì tẹrí ba fún Jóábù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré.
22 Áhímáásì ọmọkùnrin Sádókù tún sọ fún Jóábù wàyí pé: “Nísinsìnyí, jẹ́ kí ohun yòówù tí ó bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ kí ó ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi alára pẹ̀lú sáré tọ ọmọ Kúṣì lẹ́yìn.” Bí ó ti wù kí ó rí, Jóábù sọ pé: “Èé ṣe tí ìwọ alára fi ní láti sáré, ọmọkùnrin mi, nígbà tí a kò rí ìhìn kankan fún ọ?”
23 Síbẹ̀, ó sọ pé: “Nísinsìnyí, jẹ́ kí ohun yòówù tí ó bá fẹ́ ṣẹlẹ̀ kí ó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kí n sáré.” Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Sáré!” Áhímáásì sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré gba ti Àgbègbè,+ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó kọjá ọmọ Kúṣì.
24 Wàyí o, Dáfídì jókòó láàárín ẹnubodè méjèèjì .+ Láàárín àkókò náà, olùṣọ́+ lọ sí òrùlé ẹnubodè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Níkẹyìn, ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì rí i, sì wò ó! ọkùnrin kan ń bẹ tí ń sáré ní òun nìkan.
25 Nítorí náà, olùṣọ́ pè, ó sì sọ fún ọba, ọba sì fèsì pé: “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan, ìhìn wà ní ẹnu rẹ̀.” Ó sì ń bọ̀, ó ń sún mọ́ tòsí láìsọsẹ̀.
26 Wàyí o, olùṣọ́ rí ọkùnrin mìíràn tí ń sáré. Nítorí náà, olùṣọ́ pe aṣọ́bodè, ó sì sọ pé: “Wò ó! Ọkùnrin mìíràn ń sáré ní òun nìkan!” ọba sì fèsì pé: “Amúhìnwá ni ẹni yìí pẹ̀lú.”
27 Olùṣọ́ sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Mo ń rí i pé ọ̀nà ìgbàsáré ẹni àkọ́kọ́ dà bí ọ̀nà ìgbàsáré+ Áhímáásì+ ọmọkùnrin Sádókù,” ọba sì fèsì pé: “Ènìyàn rere nìyí,+ ìhìn rere+ sì ni ó yẹ kí ó mú wá.”
28 Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Áhímáásì pè, ó sì wí fún ọba pé: “Dáadáa ni!” Pẹ̀lú ìyẹn, ó tẹrí ba fún ọba pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀. Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ìbùkún+ ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ti fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé e lọ́wọ́!”+
29 Bí ó ti wù kí ó ri, ọba sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Áhímáásì fèsì pé: “Mo rí arukutu ńláǹlà nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba àti ìránṣẹ́ rẹ, èmi kò sì mọ ohun tí ó jẹ́.”+
30 Nítorí náà, ọba sọ pé: “Bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, mú ìdúró rẹ níhìn-ín.” Látàrí ìyẹn, ó bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì dúró jẹ́ẹ́.
31 Ọmọ Kúṣì+ sì rèé tí ń wọlé bọ̀, ọmọ Kúṣì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Kí olúwa mi ọba tẹ́wọ́ gba ìhìn, nítorí Jèhófà ti ṣe ìdájọ́ fún ọ lónìí, láti gbà ọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ń dìde sí ọ.”+
32 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún ọmọ Kúṣì pé: “Ṣé dáadáa ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Ọmọ Kúṣì fèsì pé: “Kí àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba àti gbogbo àwọn tí ó dìde sí ọ fún ibi dà bí ọ̀dọ́kùnrin náà.”+
33 Nígbà náà ni ìyọlẹ́nu bá ọba, ó sì gòkè lọ sí ìyẹ̀wù òrùlé+ lórí ojú ọ̀nà ibodè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún; ohun tí ó sì sọ nìyí bí ó ti ń rìn lọ: “Ọmọkùnrin mi Ábúsálómù, ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi+ Ábúsálómù! Áà ì bá ṣe pé mo ti kú, èmi fúnra mi, dípò ìwọ, Ábúsálómù ọmọkùnrin mi, ọmọkùnrin mi!”+