2 Sámúẹ́lì 23:1-39
23 Ìwọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dáfídì:+
“Àsọjáde Dáfídì ọmọkùnrin Jésè,+
Àti àsọjáde abarapá ọkùnrin tí a gbé sókè sí ibi gíga,+
Ẹni àmì òróró+ Ọlọ́run Jékọ́bù,
Àti ẹni gbígbádùnmọ́ni nídìí orin atunilára+ Ísírẹ́lì.
2 Ẹ̀mí Jèhófà ni ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ mi,+
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì wà lórí ahọ́n mi.+
3 Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé,
Àpáta Ísírẹ́lì bá mi sọ̀rọ̀ pé,+
‘Nígbà tí ẹni tí ń ṣàkóso lórí aráyé bá jẹ́ olódodo,+
Tí ó ń ṣàkóso nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run,+
4 Nígbà náà, yóò dà bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, nígbà tí oòrùn ràn,+
Òwúrọ̀ tí kò ní àwọsánmà.
Láti inú ìtànyòò, láti inú òjò, koríko jáde wá láti inú ilẹ̀.’+
5 Nítorí pé bẹ́ẹ̀ ha kọ́ ni agbo ilé mi rí pẹ̀lú Ọlọ́run?+
Nítorí pé májẹ̀mú+ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ó fi fún mi,
Tí a mù wà létòletò nínú ohun gbogbo, tí ó sì wà lábẹ́ ààbò.+
Nítorí èyí ni gbogbo ìgbàlà+ mi àti gbogbo inú dídùn mi,
Kì í ha ṣe ìdí níyẹn tí òun yóò fi mú kí ó dàgbà?+
6 Ṣùgbọ́n a lé+ àwọn tí kò dára fún ohunkóhun+ lọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún,+ gbogbo wọn;
Nítorí a kì yóò fi ọwọ́ mú wọn.
7 Nígbà tí ọkùnrin kan bá fọwọ́ kàn wọ́n
Ó ní láti fi irin àti ẹ̀rú ọ̀kọ̀ dìhámọ́ra dáadáa,
Iná ni a ó sì fi sun wọ́n lúúlúú.”+
8 Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin alágbára ńlá+ tí ó jẹ́ ti Dáfídì: Joṣebi-báṣébétì+ tí í ṣe Tákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà. Ó ń ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ fìrìfìrì lórí ẹgbẹ̀rin tí a pa lẹ́ẹ̀kan náà.
9 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e ni Élíásárì+ ọmọkùnrin Dódò+ ọmọkùnrin Áhóhì, ó wà lára àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta tí ó wà pẹ̀lú Dáfídì nígbà tí wọ́n ṣáátá àwọn Filísínì. Wọ́n ti kó ara wọn jọpọ̀ níbẹ̀ fún ìjà ogun, nítorí náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá padà.+
10 Òun ni ó dìde tí ó sì ń ṣá àwọn Filísínì balẹ̀ nìṣó, títí ọwọ́ rẹ̀ fi di aláìlókun, tí ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ típẹ́ mọ́ idà,+ tí ó fi jẹ́ pé Jèhófà ṣe ìgbàlà ńláǹlà ní ọjọ́ yẹn;+ àti ní ti àwọn ènìyàn náà, wọ́n padà sẹ́yìn rẹ̀ kìkì láti bọ́ nǹkan kúrò lára àwọn tí a ṣá balẹ̀.+
11 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e sì ni Ṣámáhì ọmọkùnrin Ágéè tí í ṣe Hárárì.+ Àwọn Filísínì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọpọ̀ sí Léhì, ní ibi tí abá pápá kan tí ó kún fún ẹ̀wà lẹ́ńtìlì+ wà nígbà náà; àwọn ènìyàn náà sì sá lọ nítorí àwọn Filísínì.
12 Ṣùgbọ́n ó mú ìdúró rẹ̀ ní àárín abá náà, ó sì dá a nídè, ó sì ń ṣá àwọn Filísínì balẹ̀ nìṣó, tí ó fi jẹ́ pé Jèhófà ṣe ìgbàlà ńlá.+
13 Mẹ́ta lára àwọn ọgbọ̀n olórí+ sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì wá nígbà ìkórè, sọ́dọ̀ Dáfídì ní hòrò Ádúlámù;+ abúlé àgọ́ àwọn Filísínì sì dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Réfáímù.+
14 Nígbà yẹn, Dáfídì sì wà ní ibi tí ó nira láti dé;+ ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó+ ti àwọn Filísínì sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà yẹn.
15 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Dáfídì fi ìfàsí-ọkàn rẹ̀ hàn, ó sì wí pé: “Ì bá ṣe pé mo lè rí omi mu láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó wà ní ẹnubodè!”+
16 Látàrí ìyẹn, àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà fi ipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n sì fa omi láti inú ìkùdu Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ó wà ní ẹnubodè, wọ́n sì ń gbé e bọ̀ wá sọ́dọ̀ Dáfídì;+ kò sì gbà láti mu ún, ṣùgbọ́n ó dà+ á jáde fún Jèhófà.
17 Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi,+ Jèhófà, pé èmi yóò ṣe èyí! [Èmi yóò ha mu] ẹ̀jẹ̀+ àwọn ọkùnrin tí wọ́n lọ ní fífi ọkàn wọn wewu?” Kò sì gbà láti mu ún.
Ìwọ̀nyí ni ohun tí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà ṣe.
18 Ní ti Ábíṣáì+ arákùnrin Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà,+ òun ni olórí ọgbọ̀n, ó sì ń ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ fìrìfìrì lórí ọ̀ọ́dúnrún tí a pa, ó sì ní ìfùsì bí àwọn mẹ́ta náà.+
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ẹni sàràkí ju àwọn ọgbọ̀n yòókù, ó sì wá jẹ́ olórí wọn, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+
20 Ní ti Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà+ ọmọ akíkanjú kan, ẹni tí ó ṣe ohun púpọ̀ ní Kábúséélì,+ òun fúnra rẹ̀ ni ó ṣá àwọn ọmọkùnrin méjì ti Áríélì ará Móábù balẹ̀; òun fúnra rẹ̀ sì ni ó sọ̀ kalẹ̀, tí ó sì ṣá kìnnìún+ kan balẹ̀ nínú kòtò omi kan ní ọjọ́ tí ìrì dídì ń sẹ̀.+
21 Òun sì ni ó ṣá ọkùnrin ará Íjíbítì náà balẹ̀, tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.+ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, síbẹ̀, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ bá a pẹ̀lú ọ̀pá, ó sì já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+
22 Nǹkan wọ̀nyí ni Bẹnáyà+ ọmọkùnrin Jèhóádà ṣe; ó sì ní ìfùsì bí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá mẹ́ta náà.+
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ sàràkí ju ọgbọ̀n náà, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta náà; ṣùgbọ́n Dáfídì yàn án sínú ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.+
24 Ásáhélì+ arákùnrin Jóábù wà lára ọgbọ̀n náà; Élíhánánì+ ọmọkùnrin Dódò ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,
25 Ṣámáhì+ ará Háródù, Élíkà ará Háródù,
26 Hélésì+ tí í ṣe Pálútì, Írà+ ọmọkùnrin Íkéṣì+ ará Tékóà,
27 Abi-ésérì+ ọmọ Ánátótì,+ Mébúnáì ọmọ Húṣà,+
28 Sálímónì ọmọ Áhóhì,+ Máháráì+ ará Nétófà,
29 Hélébù+ ọmọkùnrin Báánáhì ará Nétófà, Ítítáì+ ọmọkùnrin Ríbáì ti Gíbíà ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì,
30 Bẹnáyà+ ará Pírátónì, Hídáì ti àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Gááṣì,+
31 Abi-álíbónì tí í ṣe Ábátì, Ásímáfẹ́tì+ ará Báhúmù,
32 Élíábà tí í ṣe Ṣáálíbónì, àwọn ọmọ Jáṣénì, Jónátánì,+
33 Ṣámáhì tí í ṣe Hárárì, Áhíámù+ ọmọkùnrin Ṣárárì tí í ṣe Hárárì,
34 Élífélétì ọmọkùnrin Áhásíbáì ọmọkùnrin ará Máákátì, Élíámù ọmọkùnrin Áhítófẹ́lì+ ará Gílò,
35 Hésírò+ ará Kámẹ́lì, Pááráì ará Árábù,
36 Ígálì ọmọkùnrin Nátánì+ ti Sóbà, Bánì ọmọ Gádì,
37 Sélékì+ ọmọ Ámónì, Náháráì ará Béérótì, àwọn arùhámọ́ra Jóábù ọmọkùnrin Seruáyà,
38 Írà tí í ṣe Ítírì,+ Gárébù+ tí í ṣe Ítírì,
39 Ùráyà+ ọmọ Hétì—gbogbo wọ́n jẹ́ mẹ́tàdínlógójì.