Kólósè 4:1-18
4 Ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe ohun tí ó jẹ́ òdodo àti ohun tí ó bá ẹ̀tọ́ mu fún àwọn ẹrú yín,+ ní mímọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ní Ọ̀gá kan ní ọ̀run.+
2 Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà,+ kí ẹ máa wà lójúfò nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́,+
3 lẹ́sẹ̀ kan náà, kí ẹ máa gbàdúrà fún àwa pẹ̀lú,+ kí Ọlọ́run lè ṣí ilẹ̀kùn+ àsọjáde fún wa, láti sọ àṣírí ọlọ́wọ̀+ nípa Kristi, èyí tí mo tìtorí rẹ̀ wà nínú àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n+ ní ti tòótọ́;
4 kí n lè fi í hàn kedere bí ó ti yẹ kí n sọ̀rọ̀.+
5 Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn tí ń bẹ lóde,+ kí ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ+ padà fún ara yín.
6 Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́,+ tí a fi iyọ̀ dùn,+ kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn+ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.
7 Gbogbo àwọn àlámọ̀rí mi ni Tíkíkù,+ arákùnrin mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ àti ẹrú ẹlẹgbẹ́ mi nínú Olúwa, yóò sọ di mímọ̀ fún yín.
8 Fún ète náà gan-an pé kí ẹ lè mọ àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú wa àti pé kí òun lè tu ọkàn-àyà yín nínú,+ ni mo ṣe ń rán an sí yín
9 pa pọ̀ pẹ̀lú Ónẹ́símù,+ arákùnrin mi olùṣòtítọ́ àti olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí ó ti àárín yín wá. Gbogbo nǹkan tí ń bẹ níhìn-ín ni wọn yóò sọ di mímọ̀ fún yín.
10 Àrísítákọ́sì+ òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi kí yín, Máàkù+ mọ̀lẹ́bí Bánábà sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, (nípa ẹni tí ẹ rí àwọn àṣẹ gbà pé kí ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà+ á bí ó bá wá sọ́dọ̀ yín,)
11 àti Jésù tí a ń pè ní Jọ́sítù, àwọn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn tí ó dádọ̀dọ́. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.
12 Epafírásì,+ ẹni tí ó ti àárín yín wá, ẹrú Kristi Jésù, kí yín, nígbà gbogbo ni ó ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀, pé kí ẹ lè dúró lọ́nà tí ó pé+ níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.
13 Ní tòótọ́, mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ṣe ìsapá ńláǹlà nítorí yín àti nítorí àwọn tí ń bẹ ní Laodíkíà+ àti nítorí àwọn tí ń bẹ ní Hirapólísì.
14 Lúùkù+ oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n ní kí a kí yín, Démà+ sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
15 Ẹ bá mi kí àwọn ará ní Laodíkíà àti obìnrin náà Nímífà àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.+
16 Nígbà tí ẹ bá sì ti ka lẹ́tà yìí láàárín yín, ẹ ṣètò pé kí a kà á+ pẹ̀lú nínú ìjọ àwọn ará Laodíkíà, kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó wá láti Laodíkíà.
17 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ sọ fún Ákípọ́sì+ pé: “Máa ṣọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o tẹ́wọ́ gbà nínú Olúwa, kí o lè mú un ṣẹ.”
18 Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, ní ọwọ́ ara mi.+ Ẹ máa bá a lọ ní fífi àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi sọ́kàn.+ Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú yín.