A7-A
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀
Bí Ìtàn inú Ìwé Ìhìn Rere Mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Ṣe Ṣẹlẹ̀ Tẹ̀ Léra
Àwọn àtẹ ìsọfúnni tó wà níbí yìí ní àwòrán ilẹ̀ àwọn ibi tí Jésù lọ àtàwọn ibi tó ti wàásù. Àwọn àmì ẹlẹ́nu ṣóńṣó tó wà nínú àwọn àwòrán ilẹ̀ náà kò tọ́ka sí ibi tí Jésù gbà gangan, wọ́n wulẹ̀ ń sọ ibi téèyàn lè rìn gbà. Àmì “n.” túmọ̀ sí “nǹkan bíi.”
Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀
ÀKÓKÒ |
IBI |
ÌṢẸ̀LẸ̀ |
MÁTÍÙ |
MÁÀKÙ |
LÚÙKÙ |
JÒHÁNÙ |
---|---|---|---|---|---|---|
3 Ṣ.S.K. |
Jerúsálẹ́mù, tẹ́ńpìlì |
Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbí Jòhánù Arinibọmi fún Sekaráyà |
||||
c. 2 Ṣ.S.K. |
Násárẹ́tì; Jùdíà |
Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbí Jésù fún Màríà; ó lọ wo mọ̀lẹ́bí rẹ̀, Èlísábẹ́tì |
||||
2 Ṣ.S.K. |
Ìgbèríko olókè nílẹ̀ Jùdíà |
Wọ́n bí Jòhánù Arinibọmi, wọn sì sọ ọ́ lórúkọ; Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀; Jòhánù máa wà ní aginjù |
||||
2 Ṣ.S.K., n. Oct. 1 |
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù |
Wọ́n bí Jésù; “Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara” |
||||
Nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; Bẹ́tílẹ́hẹ́mù |
Áńgẹ́lì kéde ìhìn rere fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn; àwọn áńgẹ́lì yin Ọlọ́run; àwọn olùṣọ́ àgùntàn lọ wo ọmọ jòjòló náà |
|||||
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; Jerúsálẹ́mù |
Jésù dádọ̀dọ́ (ní ọjọ́ kẹjọ); àwọn òbí rẹ̀ gbé e lọ sí tẹ́ńpìlì (lẹ́yìn ogójì ọjọ́) |
|||||
1 Ṣ.S.K. tàbí 1 S.K. |
Jerúsálẹ́mù; Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; Íjíbítì; Násárẹ́tì |
Àwọn awòràwọ̀ ṣèbẹ̀wò; ìdílé sá lọ sí Íjíbítì; Hẹ́rọ́dù pa àwọn ọmọdékùnrin; ìdílé pa dà láti Íjíbítì wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní Násárẹ́tì |
||||
12 S.K., Ìrékọjá |
Jerúsálẹ́mù |
ésù ọmọ ọdún méjìlá (12) wà ní tẹ́ńpìlì ó ń bi àwọn olùkọ́ ní ìbéèrè |
||||
Násárẹ́tì |
Ó pa dà sí Násárẹ́tì; ó ń fi ara rẹ̀ sábẹ́ àwọn òbí rẹ̀; ó kọ́ iṣẹ́ káfíńtà; Màríà tọ́ ọmọkùnrin mẹ́rin míì, ó tún ní àwọn ọmọbìnrin (Mt 13:55, 56; Mr 6:3) |
|||||
29, ìgbà ìrúwé |
Aginjù, Odò Jọ́dánì |
Jòhánù Arinibọmi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ |