A7-E
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tó Ta Yọ Tí Jésù Ṣe ní Gálílì (Apá Kejì)
ÀKÓKÒ |
IBI |
ÌṢẸ̀LẸ̀ |
MÁTÍÙ |
MÁÀKÙ |
LÚÙKÙ |
JÒHÁNÙ |
---|---|---|---|---|---|---|
31 tàbí 32 |
Agbègbè Kápánáúmù |
Jésù ṣe àpèjúwe nípa Ìjọba Ọlọ́run |
||||
Òkun Gálílì |
Ó dá ìjì dúró nígbà tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi |
|||||
Agbègbè Gádárà |
Ó lé àwọn ẹ̀mí èṣù sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ |
|||||
Ó lè jẹ́ ní Kápánáúmù |
Ó wo obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ sàn; ó jí ọmọbìnrin Jáírù dìde |
|||||
Kápánáúmù (?) |
Ó ṣe ìwòsàn fún afọ́jú àti ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ |
|||||
Násárẹ́tì |
Àwọn ará ìlú rẹ̀ tún kọ̀ ọ́ |
|||||
Gálílì |
Ìrìn àjò rẹ̀ kẹta ní Gálílì; ó mú iṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò sí i nígbà tó rán àwọn àpọ́sítélì jáde |
|||||
Tìbéríà |
Tìbéríà Hẹ́rọ́dù bẹ́ Jòhánù Arinibọmi lórí; Ọ̀rọ̀ nípa Jésù rú Hẹ́rọ́dù lójú |
|||||
32, Ìrékọjá sún mọ́lé (Jo 6:4) |
Kápánáúmù (?); Àríwá Ìlà Oòrùn Òkun Gálílì |
Àwọn àpọ́sítélì dé láti ìrìn àjò iṣẹ́ ìwàásù; Jésù bọ́ 5,000 ọkùnrin |
||||
Àríwá Ìlà Oòrùn Òkun Gálílì; Jẹ́nẹ́sárẹ́tì |
Àwọn èèyàn fẹ́ fi Jésù jọba; ó rìn lórí òkun; ó wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ sàn |
|||||
Kápánáúmù |
Ó sọ pé òun ni “oúnjẹ ìyè”; ọ̀pọ̀ kọsẹ̀, wọ́n sì lọ |
|||||
32, lẹ́yìn Ìrékọjá |
Ó lè jẹ́ ní Kápánáúmù |
Ó bẹnu àtẹ́ lu àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ |
||||
Foníṣíà; Dekapólì |
Ó wo ọmọ obìnrin ará Foníṣíà ti Síríà sàn; ó bọ́ 4,000 ọkùnrin |
|||||
Mágádánì |
Àmì Jónà nìkan ló fún àwọn èèyàn |