Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A5

Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì

Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì gbà pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà tí orúkọ Ọlọ́run gangan fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Orúkọ náà sì ni lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin yìí (יהוה) dúró fún. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò sí orúkọ náà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Torí náà, ọ̀pọ̀ Bíbélì tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì lóde òní kò lo orúkọ náà, Jèhófà, nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ apá tí wọ́n pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Kódà nígbà tí ọ̀pọ̀ atúmọ̀ èdè bá ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fà yọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n máa ń lo “Olúwa” níbi tí lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin náà ti fara hàn, dípò kí wọ́n lo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan.

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Bíbélì yìí lo orúkọ náà, Jèhófà, nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní igba ó lé mẹ́tàdínlógójì (237) ìgbà. Kí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì yìí tó dórí ìpinnu yẹn, ohun méjì pàtàkì tí wọ́n gbé yẹ̀ wò rèé: (1) Àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n fọwọ́ kọ tó wà lónìí kì í ṣe ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Ìwé Mímọ́ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n ṣe àdàkọ ọ̀pọ̀ lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dà àfọwọ́kọ tó wà lónìí. (2) Nígbà yẹn, àwọn tó ń ṣe àdàkọ ìwé àfọwọ́kọ máa ń fi ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà Kyʹri·os, tó túmọ̀ sí “Olúwa” rọ́pò lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù tàbí kó jẹ́ pé ìwé àfọwọ́kọ tí kò ní orúkọ Ọlọ́run nínú ni wọ́n dà kọ.

Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun gbà pé ẹ̀rí tó dájú wà tó fi hàn pé lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ lédè Gíríìkì. Àwọn ẹ̀rí tí wọ́n gbé ìpinnu wọn kà rèé:

  • Lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù wà lọ́pọ̀ ibi nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n lò nígbà ayé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn díẹ̀ wà tí wọn ò gbà bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti rí àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n fọwọ́ kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nítòsí Kúmúránì, kò sí iyè méjì mọ́ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ náà.

  • Nígbà ayé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀, lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù tún fara hàn nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì. Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ni àwọn ọ̀mọ̀wé fi rò pé lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù kò sí nínú Bíbélì Greek Septuagint (Bíbélì Septuagint Lédè Gíríìkì) tó jẹ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì. Àmọ́, nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 1950, wọ́n fi àjákù àwọn ìwé ògbólógbòó kan tó jẹ́ ẹ̀dà Bíbélì Greek Septuagint tó ti wà látìgbà ayé Jésù han àwọn ọ̀mọ̀wé. Orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fi lẹ́tà èdè Hébérù kọ wà nínú àwọn àjákù ìwé náà. Èyí fi hàn pé, nígbà tí Jésù wà láyé, orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tó wà lédè Gíríìkì. Àmọ́, nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni, àwọn ìwé àfọwọ́kọ pàtàkì bíi Codex Vaticanus àti Codex Sinaiticus, tí wọ́n dà kọ látinú Bíbélì Greek Septuagint, ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Jẹ́nẹ́sísì dé Málákì (níbi tó wà tẹ́lẹ̀ nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó wà ṣáájú ìgbà yẹn). Torí náà, kò yani lẹ́nu pé kò sí orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé tí wọ́n tọ́jú látìgbà yẹn, ìyẹn ìwé tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun tàbí apá tó jẹ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì nínú Bíbélì.

    Jésù sọ kedere pé: “Mo wá ní orúkọ Baba mi.” Ó sì tún tẹnu mọ́ ọn pé “orúkọ Baba” òun lòun fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí òun ń ṣe

  • Àwọn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pàápàá fi hàn pé Jésù sábà máa ń tọ́ka sí orúkọ Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ náà. (Jòhánù 17:6, 11, 12, 26) Jésù sọ kedere pé: “Mo wá ní orúkọ Baba mi.” Ó sì tún tẹnu mọ́ ọn pé “orúkọ Baba” òun lòun fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí òun ń ṣe.—Jòhánù 5:43; 10:25.

  • Nítorí pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tó sì jẹ́ àfikún sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, bí Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run ṣe ṣàdédé di àwátì nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fi hàn pé nǹkan míì ti wọ̀ ọ́. Ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni, Jémíìsì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ fún àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé: “Símíónì ti ròyìn ní kíkún bí Ọlọ́run ṣe yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.” (Ìṣe 15:14) Kò ní bọ́gbọ́n mu fún Jémíìsì láti sọ ohun tó sọ yẹn tó bá jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ orúkọ Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí wọn ò sì lò ó.

  • Ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.Ìfihàn 19:1, 3, 4, 6, orúkọ Ọlọ́run wà nínú ọ̀rọ̀ náà “Halelúyà.” Inú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tó túmọ̀ sí “Ẹ Yin Jáà,” ni ọ̀rọ̀ náà “Halelúyà” ti wá. “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà. Ọ̀pọ̀ orúkọ tí wọ́n lò nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló wá látinú orúkọ Ọlọ́run. Kódà, àwọn ìwé ìwádìí kan ṣàlàyé pé ohun tí orúkọ Jésù fúnra rẹ̀ túmọ̀ sí ni “Ti Jèhófà Ni Ìgbàlà.”

  • Àwọn ìwé táwọn Júù kan kọ láyé àtijọ́ fi hàn pé àwọn Júù tó di Kristẹni lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé wọn. Ìwé àkójọ òfin àtẹnudẹ́nu tó ń jẹ́ The Tosefta, tí wọ́n kọ parí ní nǹkan bí ọdún 300 Sànmánì Kristẹni sọ nípa ìwé àwọn Kristẹni kan tí wọ́n dáná sun lọ́jọ́ Sábáàtì pé: “Wọn ò yọ ìwé àwọn Ajíhìnrere àti ìwé àwọn minim [tí wọ́n rò pé wọ́n jẹ́ Júù tó di Kristẹni] nínú iná. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí iná jó wọn mọ́ ibi tí wọ́n wà, tó fi mọ́ Orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú wọn.” Ìwé The Tosefta yìí tún tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Rábì Yosé ará Gálílì kan, tó gbé láyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni. Ó ní Rábì yẹn sọ pé láwọn ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀, “ẹnì kan á gé ibi tí Orúkọ Ọlọ́run wà kúrò nínú wọn [ìyẹn ìwé àwọn Kristẹni], á kó o pa mọ́, á sì fi iná sun ìwé tó kù.”

  • Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì gbà pé ó ṣeé ṣe kí orúkọ Ọlọ́run wà nínú àwọn ibi tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ìwé The Anchor Bible Dictionary, lábẹ́ àkòrí náà, “Lẹ́tà Mẹ́rin Tó Dúró fún Orúkọ Ọlọ́run Nínú Májẹ̀mú Tuntun” sọ pé: “Ẹ̀rí wà tó fi hàn pé lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún Orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Yahweh, wà nínú díẹ̀ tàbí nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí Májẹ̀mú Tuntun fà yọ látinú Májẹ̀mú Láéláé nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ Májẹ̀mú Tuntun sílẹ̀.” Ọ̀mọ̀wé George Howard sì sọ pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti lo lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì lédè Gíríìkì [ìyẹn Bíbélì Septuagint] tó jẹ́ Ìwé Mímọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì ìgbà yẹn ń lò, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn tó kọ Májẹ̀mú Tuntun ò ní yọ àwọn lẹ́tà mẹ́rin náà kúrò tí wọ́n bá ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì.”

  • Àwọn atúmọ̀ Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ti lo orúkọ Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Àwọn kan lára àwọn atúmọ̀ Bíbélì yìí ti lo orúkọ náà ní ọ̀pọ̀ ọdún ká tó ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Lára àwọn atúmọ̀ Bíbélì náà àti ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe rèé: A Literal Translation of the New Testament . . . From the Text of the Vatican Manuscript, látọwọ́ Herman Heinfetter (1863); The Emphatic Diaglott, látọwọ́ Benjamin Wilson (1864); The Epistles of Paul in Modern English, látọwọ́ George Barker Stevens (1898); St. Paul’s Epistle to the Romans, látọwọ́ W. G. Rutherford (1900); The New Testament Letters, látọwọ́ J.W.C. Wand, Bíṣọ́ọ̀bù ìlú London (1946). Ní àfikún, nígbà tí atúmọ̀ Bíbélì náà Pablo Besson túmọ̀ Bíbélì sí èdè Sípáníìṣì ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, ó lo “Jehová” nínú Lúùkù 2:15 àti Júùdù 14. Yàtọ̀ síyẹn, ó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé nínú ìtumọ̀ Bíbélì rẹ̀ tó fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run ló ṣeé ṣe kó wà níbi tí àlàyé náà ń tọ́ka sí. Ṣáájú kí àwọn ìtumọ̀ yẹn tó jáde rárá ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Hébérù láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, ti ń lo lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run nínú ẹsẹ tó pọ̀. Ní èdè Jámánì nìkan ṣoṣo, ó kéré tán, Bíbélì mọ́kànlá (11) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó lo “Jehovah” (tàbí orúkọ Hébérù náà “Yahweh”) nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àwọn atúmọ̀ Bíbélì mẹ́rin lo “Olúwa” àmọ́ wọ́n fi “Jehovah” tàbí “Yahweh” sínú àkámọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ju àádọ́rin (70) lọ lára àwọn Bíbélì lédè Jámánì tó lo orúkọ Ọlọ́run nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé wọn tàbí nínú àlàyé tí wọ́n ṣe.

    Orúkọ Ọlọ́run rèé bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣe 2:34 nínú Bíbélì The Emphatic Diaglott, látọwọ́ Benjamin Wilson (ọdún 1864)

  • Àwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún lo orúkọ Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ọ̀pọ̀ Bíbélì lo orúkọ Ọlọ́run ní fàlàlà ní àwọn èdè ilẹ̀ Áfíríkà, èdè ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà, Éṣíà, Yúróòpù àti erékùṣù Pàsífíìkì. (Wo ibi tí a to àwọn orúkọ náà sí ní  ojú ìwé 1742 àti 1743.) Ìdí tí àwọn atúmọ̀ èdè yẹn fi lo orúkọ Ọlọ́run jọ àwọn ìdí tí a ti mẹ́nu kàn tẹ́lẹ̀. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni wọ́n tẹ díẹ̀ lára àwọn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì yẹn jáde. Lára wọn ni Bíbélì Rotuman (ọdún 1999), tó lo “Jihova” nígbà mọ́kànléláàádọ́ta (51) ní ẹsẹ méjìdínláàádọ́ta (48). Òmíràn ni Bíbélì Batak (Toba) (ọdún 1989) láti orílẹ̀-èdè Indonesia, tó lo “Jahowa” nígbà àádọ́fà (110).

    Orúkọ Ọlọ́run rèé ní Máàkù 12:29, 30 nínú Bíbélì èdè Hawaiian

Kò sí iyè méjì níbẹ̀ pé ìdí tó ṣe kedere wà tí Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ pa dà síbi tó yẹ kó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ohun tí àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sì ṣe gan-an nìyẹn. Wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì ní ìbẹ̀rù tó tọ́ láti má ṣe yọ ohunkóhun kúrò lára ọ̀rọ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.—Ìfihàn 22:18, 19.