Àìsáyà 12:1-6
12 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé o máa sọ pé:
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà,Torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé o bínú sí mi,Ìbínú rẹ ti wá rọlẹ̀, o sì tù mí nínú.+
2 Wò ó! Ọlọ́run ni ìgbàlà mi.+
Màá gbẹ́kẹ̀ lé e, ẹ̀rù ò sì ní bà mí;+Torí Jáà* Jèhófà ni okun mi àti agbára mi,Ó sì ti wá di ìgbàlà mi.”+
3 Tayọ̀tayọ̀ lẹ máa fa omi
Látinú àwọn ìsun ìgbàlà.+
4 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa sọ pé:
“Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,Ẹ jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí ó ṣe!+
Ẹ kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga.+
5 Ẹ kọrin ìyìn sí* Jèhófà,+ torí ó ti ṣe àwọn ohun tó yani lẹ́nu.+
Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé mọ èyí.
6 Ké jáde, kí o sì kígbe ayọ̀, ìwọ* tó ń gbé ní Síónì,Torí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tóbi láàárín rẹ.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
^ Tàbí “kọrin sí.”
^ Ní Héb., “ìwọ obìnrin,” àwọn èèyàn náà lápapọ̀ ló ń fi wé obìnrin kan.