Àìsáyà 16:1-14

  • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Móábù ń bá a lọ (1-14)

16  Ẹ fi àgbò ránṣẹ́ sí alákòóso ilẹ̀ náà,Láti Sẹ́ẹ́là gba aginjù Lọ sórí òkè ọmọbìnrin Síónì.   Bí ẹyẹ tí wọ́n lé kúrò nínú ìtẹ́ rẹ̀ + Ni àwọn ọmọbìnrin Móábù máa rí níbi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà nínú odò Áánónì.+   “Ẹ gbani nímọ̀ràn, ẹ tẹ̀ lé ìpinnu náà. Jẹ́ kí òjìji rẹ ní ọ̀sán gangan dà bí òru. Fi àwọn tí wọ́n fọ́n ká pa mọ́, má sì dalẹ̀ àwọn tó ń sá lọ.   Kí àwọn èèyàn mi tó fọ́n ká máa gbé inú rẹ, ìwọ Móábù. Di ibi ààbò fún wọn torí ẹni tó ń pani run.+ Òpin máa dé bá aninilára,Ìparun náà máa dópin,Àwọn tó ń tẹ ẹlòmíì mọ́lẹ̀ sì máa pa rẹ́ ní ayé.   Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa wá mú kí ìtẹ́ kan fìdí múlẹ̀ gbọn-in. Ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ nínú àgọ́ Dáfídì máa jẹ́ olóòótọ́;+Ó máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì máa yára ṣe òdodo.”+   A ti gbọ́ bí Móábù ṣe ń gbéra ga, ó ń gbéra ga gan-an;+Bó ṣe ń gbéra ga, tó ń yangàn, tó sì ń bínú;+Àmọ́ pàbó ni ọ̀rọ̀ asán rẹ̀ máa já sí.   Torí náà, Móábù máa pohùn réré ẹkún torí Móábù;Gbogbo wọn máa pohùn réré ẹkún.+ Àwọn tí wọ́n lù máa dárò torí ìṣù àjàrà gbígbẹ ti Kiri-hárésétì.+   Torí àwọn ilẹ̀ onípele Hẹ́ṣíbónì+ ti gbẹ,Àjàrà Síbúmà,+Àwọn alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè ti tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó pupa fòò* mọ́lẹ̀;Wọ́n ti lọ títí dé Jásérì;+Wọ́n ti tàn dé aginjù. Àwọn ọ̀mùnú rẹ̀ ti tàn kálẹ̀, wọ́n sì ti lọ títí dé òkun.   Ìdí nìyẹn tí màá fi sunkún torí àjàrà Síbúmà bí mo ṣe ń sunkún torí Jásérì. Màá fi omijé mi rin ọ́ gbingbin, ìwọ Hẹ́ṣíbónì àti Éléálè,+Torí pé igbe tí wọ́n ń ké torí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ ti dópin.* 10  A ti mú ayọ̀ àti ìdùnnú kúrò nínú ọgbà eléso,Kò sì sí orin ayọ̀ tàbí ariwo nínú àwọn ọgbà àjàrà.+ Ẹni tó ń fẹsẹ̀ tẹ àjàrà kò tẹ̀ ẹ́ mọ́ ní àwọn ibi ìfúntí láti ṣe wáìnì,Torí mo ti mú kí ariwo náà dáwọ́ dúró.+ 11  Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú mi lọ́hùn-ún ń ru sókè torí Móábù,+Bí ìgbà tí wọ́n ń ta háàpù,Àti inú mi lọ́hùn-ún torí Kiri-hárésétì.+ 12  Kódà, tí Móábù bá tán ara rẹ̀ lókun lórí ibi gíga, tó sì lọ gbàdúrà nínú ibi mímọ́ rẹ̀, kò ní rí nǹkan kan ṣe.+ 13  Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ti sọ nípa Móábù nìyí. 14  Ní báyìí, Jèhófà sọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́ta, bí iye ọdún alágbàṣe,* onírúurú rúkèrúdò ni wọ́n máa fi dójú ti ògo Móábù, àwọn tó máa ṣẹ́ kù máa kéré gan-an, wọn ò sì ní já mọ́ nǹkan kan.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí èso àjàrà pupa kún ara rẹ̀ fọ́fọ́.”
Tàbí kó jẹ́ “Torí pé wọ́n ti ń kígbe ogun sórí èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn rẹ àti ìkórè rẹ.”
Tàbí “tí wọ́n fara balẹ̀ kà bíi ti alágbàṣe”; ìyẹn, ní ọdún mẹ́ta géérégé.