Àìsáyà 2:1-22

  • A gbé òkè Jèhófà ga (1-5)

    • Wọ́n á fi idà rọ ohun ìtúlẹ̀ (4)

  • Ọjọ́ Jèhófà máa tẹ àwọn agbéraga lórí ba (6-22)

2  Ohun tí Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù nìyí:+   Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*Òkè ilé Jèhófà Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,+A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,Gbogbo orílẹ̀-èdè á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+   Ọ̀pọ̀ èèyàn máa lọ, wọ́n á sì sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+ Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”+ Torí òfin* máa jáde láti Síónì,Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.+   Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,Ó sì máa yanjú ọ̀rọ̀* láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn. Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+ Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+   Ẹ̀yin ilé Jékọ́bù, ẹ wá,Ẹ jẹ́ ká rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.+   Torí o ti pa àwọn èèyàn rẹ, ilé Jékọ́bù tì.+ Torí àwọn nǹkan tó wá láti Ìlà Oòrùn ti kún ọwọ́ wọn;Wọ́n ń pidán+ bí àwọn Filísínì,Àwọn ọmọ àjèjì sì pọ̀ láàárín wọn.   Fàdákà àti wúrà kún ilẹ̀ wọn,Ìṣúra wọn kò sì lópin. Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,Kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn ò sì níye.+   Àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí kún ilẹ̀ wọn.+ Wọ́n ń forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,Fún ohun tí wọ́n fi ìka ara wọn ṣe.   Èèyàn wá ń forí balẹ̀, ó di ẹni tó rẹlẹ̀,O ò sì lè dárí jì wọ́n. 10  Wọ inú àpáta, kí o sì fi ara rẹ pa mọ́ sínú iyẹ̀pẹ̀,Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá.+ 11  Ojú èèyàn tó ń gbéra ga máa wálẹ̀,A sì máa tẹrí ìgbéraga àwọn èèyàn ba.* Jèhófà nìkan la máa gbé ga ní ọjọ́ yẹn. 12  Torí ọjọ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni.+ Ó ń bọ̀ wá sórí gbogbo ẹni tó ń gbéra ga àti ẹni gíga,Sórí gbogbo èèyàn, ì báà jẹ́ ẹni gíga tàbí ẹni tó rẹlẹ̀,+ 13  Sórí gbogbo igi kédárì Lẹ́bánónì tó ga, tó sì ta yọÀti sórí gbogbo igi ràgàjì* Báṣánì, 14  Sórí gbogbo òkè ńláńláÀti sórí gbogbo òkè tó ga, 15  Sórí gbogbo ilé gogoro àti gbogbo odi ààbò, 16  Sórí gbogbo ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ Àti sórí gbogbo ọkọ̀ ojú omi tó wuni. 17  Ìgbéraga èèyàn máa wálẹ̀,A sì máa tẹrí ìgbéraga àwọn èèyàn ba.* Jèhófà nìkan la máa gbé ga ní ọjọ́ yẹn. 18  Àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí máa pòórá pátápátá.+ 19  Àwọn èèyàn sì máa wọ ihò inú àpátaÀti àwọn ihò inú ilẹ̀,+Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá,+Nígbà tó dìde láti mi ayé jìgìjìgì, kó sì kó jìnnìjìnnì bá a. 20  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa mú àwọn ọlọ́run wọn tí kò ní láárí, tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe,Èyí tí wọ́n ṣe fúnra wọn kí wọ́n lè máa forí balẹ̀ fún un,Wọ́n á sì jù wọ́n sí àwọn asín* àti àwọn àdán,+ 21  Kí wọ́n lè wọ àwọn ihò inú àpátaÀti inú àwọn pàlàpálá àpáta,Torí bí Jèhófà ṣe wà níbí ń dẹ́rù bani,Iyì rẹ̀ sì ga lọ́lá,Nígbà tó dìde láti mi ayé jìgìjìgì, kó sì kó jìnnìjìnnì bá a. 22  Fún àǹfààní ara yín, ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn lásán mọ́,Ẹni tí kò yàtọ̀ sí èémí ihò imú rẹ̀.* Kí nìdí tí ẹ fi máa kà á sí?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí “tún nǹkan ṣe.”
Tàbí “rẹ ìgbéraga àwọn èèyàn wálẹ̀.”
Tàbí “igi óákù.”
Tàbí “rẹ ìgbéraga àwọn èèyàn wálẹ̀.”
Àwọn eku tó ń jẹ nǹkan run.
Tàbí “tí èémí rẹ̀ wà nínú ihò imú rẹ̀.”