Àìsáyà 20:1-6

  • Àmì àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì àti Etiópíà (1-6)

20  Ní ọdún tí Ságónì ọba Ásíríà rán Tátánì* lọ sí Áṣídódì,+ ó bá Áṣídódì jagun, ó sì gbà á.+  Ní àkókò yẹn, Jèhófà gbẹnu Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀, ó ní: “Lọ, kí o tú aṣọ ọ̀fọ̀* kúrò ní ìbàdí rẹ, kí o sì bọ́ bàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó wá ń rìn káàkiri ní ìhòòhò* àti láìwọ bàtà.  Jèhófà wá sọ pé: “Bí ìránṣẹ́ mi Àìsáyà ṣe rìn káàkiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, láti fi ṣe àmì+ àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì+ àti Etiópíà,+  bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọba Ásíríà máa kó àwọn ẹrú Íjíbítì+ àti Etiópíà lọ sí ìgbèkùn, àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn àgbà ọkùnrin, ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà, ìdí wọn á sì hàn síta, Íjíbítì máa rin ìhòòhò.*  Ẹ̀rù máa bà wọ́n, ojú sì máa tì wọ́n torí Etiópíà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé àti Íjíbítì tí wọ́n fi ń yangàn.*  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ń gbé ilẹ̀ etíkun yìí máa sọ pé, ‘Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí a gbẹ́kẹ̀ lé, tí a sá lọ bá pé kó ràn wá lọ́wọ́, kó sì gbà wá lọ́wọ́ ọba Ásíríà! Báwo la ṣe máa yè bọ́ báyìí?’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọ̀gágun.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Tàbí “pẹ̀lú aṣọ jáńpé lára.”
Tàbí “ojú máa ti Íjíbítì.”
Tàbí “tí ẹwà rẹ̀ wù wọ́n.”