Àìsáyà 22:1-25
22 Ìkéde nípa Àfonífojì Ìran:*+
Kí ló ṣe yín, tí gbogbo yín fi lọ sórí àwọn òrùlé?
2 Ìwọ tí rúkèrúdò kún inú rẹ,Ìwọ ìlú aláriwo, ìlú tó ń yọ̀ gidigidi.
Kì í ṣe idà ni wọ́n fi pa àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n pa,Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò kú sójú ogun.+
3 Gbogbo àwọn apàṣẹwàá rẹ ti jọ sá lọ.+
Wọ́n mú wọn ní ẹlẹ́wọ̀n láìlo ọfà.
Gbogbo àwọn tí wọ́n rí ni wọ́n mú ní ẹlẹ́wọ̀n,+Bí wọ́n tiẹ̀ sá lọ sí ọ̀nà jíjìn.
4 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé: “Ẹ yí ojú yín kúrò lọ́dọ̀ mi,Màá sì sunkún gidigidi.+
Ẹ má fi dandan sọ pé ẹ fẹ́ tù mí nínúTorí ìparun ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi.+
5 Torí ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, ìṣẹ́gun àti ìbẹ̀rù ni,+Látọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Ní Àfonífojì Ìran.
Wọ́n máa wó ògiri palẹ̀,+Wọ́n sì máa kígbe sí òkè.
6 Élámù+ gbé apó,Pẹ̀lú àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn ẹṣin,*Kírì+ sì ṣí* apata.
7 Àwọn àfonífojì* rẹ tó dáa jùMáa kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,Àwọn ẹṣin* sì máa dúró sí àyè wọn ní ẹnubodè,
8 Wọ́n á mú aṣọ tí wọ́n ta bo* Júdà kúrò.
“Ní ọjọ́ yẹn, o máa wo apá ibi tí wọ́n ń kó nǹkan ìjà sí ní Ilé Igbó,+
9 ẹ sì máa rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàfo Ìlú Dáfídì.+ Ẹ máa gbá adágún omi ìsàlẹ̀ jọ.+
10 Ẹ máa ka àwọn ilé Jerúsálẹ́mù, ẹ sì máa wó àwọn ilé náà láti fi mú kí ògiri náà túbọ̀ lágbára.
11 Láàárín ògiri méjèèjì, ẹ máa ṣe ohun tó lè gba adágún omi àtijọ́ dúró, àmọ́ ẹ ò ní wo Aṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá, ẹ ò sì ní rí Ẹni tó dá a tipẹ́tipẹ́.
12 Ní ọjọ́ yẹn, Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Máa ní kí wọ́n sunkún, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀,+Ó máa ní kí wọ́n fá orí, kí wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.*
13 Àmọ́ dípò ìyẹn, wọ́n ń yọ̀, inú wọn sì ń dùn,Wọ́n ń pa màlúù, wọ́n sì ń dúńbú àgùntàn,Wọ́n ń jẹ ẹran, wọ́n sì ń mu wáìnì.+
‘Ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.’”+
14 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wá ṣí ara rẹ̀ payá ní etí mi pé: “‘A ò ní ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀ yìí fún yín títí ẹ̀yin èèyàn yìí fi máa kú,’+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”
15 Ohun tí Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, sọ nìyí: “Wọlé lọ bá ìríjú yìí, ìyẹn Ṣébínà,+ ẹni tó ń bójú tó ilé,* kí o sì sọ fún un pé,
16 ‘Kí ló jẹ́ tìrẹ níbí, ta sì ni èèyàn rẹ níbí, tí o fi gbẹ́ ibi ìsìnkú síbí fún ara rẹ?’ Ibi gíga ló ń gbẹ́ ibi ìsìnkú rẹ̀ sí; inú àpáta ló ń gbẹ́ ibi ìsinmi* sí fún ara rẹ̀.
17 ‘Wò ó! Jèhófà máa fi ọ́ sọ̀kò sílẹ̀, ìwọ ọkùnrin, ó sì máa fipá gbá ọ mú.
18 Ó dájú pé ó máa dì ọ́ le dan-in dan-in, ó sì máa jù ọ́ dà nù bíi bọ́ọ̀lù sí ilẹ̀ tó fẹ̀. Ibẹ̀ lo máa kú sí, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ ológo máa wà, èyí máa dójú ti ilé ọ̀gá rẹ.
19 Mo máa yọ ọ́ nípò, màá sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.
20 “‘Ní ọjọ́ yẹn, màá pe ìránṣẹ́ mi, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà,
21 màá wọ aṣọ rẹ fún un, màá de ọ̀já rẹ mọ́ ọn pinpin,+ màá sì gbé àṣẹ* rẹ lé e lọ́wọ́. Ó máa di bàbá àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ilé Júdà.
22 Màá sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì+ sí èjìká rẹ̀. Tó bá ṣí ibì kan, ẹnì kankan ò ní tì í; tó bá sì ti ibì kan, ẹnì kankan ò ní ṣí i.
23 Màá kàn án mọ́lẹ̀ bí èèkàn sí ibi tó máa wà títí lọ, ó sì máa dà bí ìtẹ́ ògo fún ilé bàbá rẹ̀.
24 Wọ́n máa gbé gbogbo ògo* ilé bàbá rẹ̀ kọ́ sára rẹ̀, àwọn àtọmọdọ́mọ àtàwọn ọmọ,* gbogbo ohun èlò kéékèèké, àwọn ohun èlò tó rí bí abọ́, títí kan gbogbo ìṣà ńlá.
25 “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘a máa yọ èèkàn tí a kàn mọ́ ibi tó máa wà títí lọ,+ a máa gé e lulẹ̀, ó sì máa ṣubú, ẹrù tó gbé máa ṣubú, ó sì máa pa run, torí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó ṣe kedere pé Jerúsálẹ́mù ló ń sọ.
^ Àkànlò èdè tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa lò láti káàánú ẹnì kan tàbí bá a kẹ́dùn.
^ Tàbí “agẹṣin.”
^ Tàbí “ṣètò.”
^ Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Tàbí “agẹṣin.”
^ Tàbí “ohun tí wọ́n fi dáàbò bo.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “ààfin.”
^ Ní Héb., “ilé.”
^ Tàbí “agbára.”
^ Ní Héb., “ìwúwo.”
^ Tàbí “èéhù.”