Àìsáyà 24:1-23

  • Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà di òfìfo (1-23)

    • Jèhófà di Ọba ní Síónì (23)

24  Wò ó! Jèhófà máa sọ ilẹ̀ náà* di òfìfo, ó sì máa sọ ọ́ di ahoro.+ Ó ń dojú rẹ̀ dé,*+ ó sì ń tú àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ ká.+   Bákan náà ló máa rí fún gbogbo èèyàn: Àwọn èèyàn àti àlùfáà,Ìránṣẹ́kùnrin àti ọ̀gá rẹ̀ ọkùnrin,Ìránṣẹ́bìnrin àti ọ̀gá rẹ̀ obìnrin,Ẹni tó ń rà àti ẹni tó ń tà,Ẹni tó ń yáni ní nǹkan àti ẹni tó ń yá nǹkan,Ẹni tó ń yáni lówó àti ẹni tó ń yáwó.+   Wọ́n máa mú kí ilẹ̀ náà ṣófo pátápátá;Wọ́n máa kó gbogbo ẹrù rẹ̀,+Torí Jèhófà ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.   Ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀;*+ ó ń joro. Ilẹ̀ tó ń méso jáde ò lọ́ràá mọ́; ó ti ń ṣá. Àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ náà ti rẹ̀ dà nù.   Àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ti ba ibẹ̀ jẹ́,+Torí wọ́n ti rú òfin,+Wọ́n ti yí ìlànà pa dà,+Wọ́n sì da májẹ̀mú tó wà pẹ́ títí.*+   Ìdí nìyẹn tí ègún fi jẹ ilẹ̀ náà run,+Tí a sì dẹ́bi fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà fi dín kù,Àwọn tó sì ṣẹ́ kù níbẹ̀ ò pọ̀ rárá.+   Wáìnì tuntun ń ṣọ̀fọ̀,* àjàrà rọ,+Gbogbo àwọn tí inú wọn sì ń dùn ń kẹ́dùn.+   Ayọ̀ ìlù tanboríìnì ti dáwọ́ dúró;Ariwo àwọn tó ń ṣe àríyá ti dópin;Ìró ayọ̀ háàpù ti dáwọ́ dúró.+   Wọ́n ń mu wáìnì láìsí orin,Ọtí sì ń korò lẹ́nu àwọn tó ń mu ún. 10  Ìlú tí wọ́n pa tì ti wó lulẹ̀;+Gbogbo ilé wà ní títì pa kí ẹnikẹ́ni má bàa wọlé. 11  Wọ́n ń kígbe ní àwọn ojú ọ̀nà torí wáìnì. Gbogbo ìdùnnú ti pòórá;Ayọ̀ ilẹ̀ náà ti lọ.+ 12  Wọ́n fi ìlú náà sílẹ̀ ní àwókù;Wọ́n ti wó ẹnubodè wómúwómú, ó ti di òkìtì àwókù.+ 13  Bó ṣe máa rí ní ilẹ̀ náà nìyí, láàárín àwọn èèyàn náà: Bí ìgbà tí wọ́n bá lu igi ólífì,+Bí ìgbà tí wọ́n pèéṣẹ́* nígbà tí ìkórè èso àjàrà dópin.+ 14  Wọ́n máa gbóhùn sókè,Wọ́n máa kígbe ayọ̀. Wọ́n máa kéde títóbi Jèhófà láti òkun.*+ 15  Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa yin Jèhófà lógo ní agbègbè ìmọ́lẹ̀;*+Ní àwọn erékùṣù òkun, wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+ 16  À ń gbọ́ àwọn orin láti ìkángun ayé pé: “Ògo ni fún Olódodo!”*+ Àmọ́ mo sọ pé: “Mò ń kú lọ, mò ń kú lọ! Ó mà ṣe fún mi o! Àwọn ọ̀dàlẹ̀ ti dalẹ̀;Ìwà ọ̀dàlẹ̀ wọn ni àwọn ọ̀dàlẹ̀ fi dalẹ̀.”+ 17  Ìbẹ̀rù, kòtò àti pańpẹ́ ń dúró dè ọ́, ìwọ tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ 18  Ẹnikẹ́ni tó bá ń sá fún ìró ìbẹ̀rù á já sínú kòtò,Pańpẹ́ sì máa mú ẹnikẹ́ni tó bá ń jáde látinú kòtò.+ Torí àwọn ibú omi ọ̀run máa ṣí,Àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ sì máa mì tìtì. 19  Ilẹ̀ náà ti fọ́ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀;A ti mi ilẹ̀ náà jìgìjìgì;Ilẹ̀ náà ń gbọ̀n rìrì.+ 20  Ilẹ̀ náà ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ẹni tó mutí yó,Ó sì ń fì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà lórí rẹ̀, ó sì wúwo gan-an,+Ó máa ṣubú, débi pé kò ní dìde mọ́. 21  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa yíjú sí àwọn ọmọ ogun ibi gíga lókèÀti sí àwọn ọba ayé lórí ilẹ̀. 22  A máa kó wọn jọBí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n kó jọ sínú kòtò,A máa tì wọ́n pa mọ́ inú àjà ilẹ̀;Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, a máa rántí wọn. 23  Òṣùpá àrànmọ́jú máa tẹ́,Ojú sì máa ti oòrùn tó ń ràn,+Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti di Ọba+ ní Òkè Síónì+ àti ní Jerúsálẹ́mù,Ògo rẹ̀ ń tàn níwájú àwọn àgbààgbà àwọn èèyàn rẹ̀.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ó ń yí ojú rẹ̀ po.”
Tàbí “ayé.”
Tàbí kó jẹ́, “gbẹ táútáú.”
Tàbí “májẹ̀mú àtijọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “gbẹ táútáú.”
Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
Tàbí “ìwọ̀ oòrùn.”
Tàbí “ní ìlà oòrùn.”
Tàbí “Ẹ ṣe Olódodo lọ́ṣọ̀ọ́!”
Ní Héb., “níwájú àwọn àgbààgbà rẹ̀.”