Àìsáyà 30:1-33

  • Íjíbítì ò lè ṣèrànwọ́ kankan (1-7)

  • Àwọn èèyàn ò fetí sí àsọtẹ́lẹ̀ (8-14)

  • Ìgbẹ́kẹ̀lé máa fi hàn pé wọ́n lágbára (15-17)

  • Jèhófà ṣojúure sí àwọn èèyàn rẹ̀ (18-26)

    • Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá (20)

    • “Èyí ni ọ̀nà” (21)

  • Jèhófà máa dá Ásíríà lẹ́jọ́ (27-33)

30  “Àwọn alágídí ọmọ gbé,”+ ni Jèhófà wí,“Àwọn tó ń ṣe ohun tí mi ò ní lọ́kàn,+Tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀,* àmọ́ tí kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,Kí wọ́n lè dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀.   Wọ́n lọ sí Íjíbítì+ láì fọ̀rọ̀ lọ̀ mí,*+Láti wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Fáráò,*Kí wọ́n sì fi òjìji Íjíbítì ṣe ibi ìsádi wọn!   Àmọ́ ibi ààbò Fáráò máa dójú tì yín,Òjìji Íjíbítì tí ẹ sì fi ṣe ibi ìsádi máa rẹ̀ yín wálẹ̀.+   Torí àwọn ìjòyè rẹ̀ wà ní Sóánì,+Àwọn aṣojú rẹ̀ sì ti dé Hánésì.   Àwọn èèyàn tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankanMáa dójú ti gbogbo wọn,Àwọn tí kò ṣèrànwọ́ kankan, tí wọn ò sì ṣeni láǹfààní kankan,Ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ nìkan ni wọ́n ń mú wá.”+  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí àwọn ẹranko gúúsù: Wọ́n gba ilẹ̀ wàhálà àti ìnira kọjá,Ilẹ̀ kìnnìún, kìnnìún tó ń ké ramúramù,Paramọ́lẹ̀ àti ejò oníná tó ń fò,*Wọ́n gbé ọrọ̀ wọn sí ẹ̀yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,Àtàwọn ohun tí wọ́n fẹ́ lò sórí iké àwọn ràkúnmí. Àmọ́ àwọn nǹkan yìí ò ní ṣe àwọn èèyàn náà láǹfààní.   Torí ìrànlọ́wọ́ Íjíbítì ò wúlò rárá.+ Torí náà, mo pe ẹni yìí ní: “Ráhábù,+ tó jókòó jẹ́ẹ́.”   “Ó yá, lọ, kọ ọ́ sára wàláà níṣojú wọn,Kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé,+Kó lè wúlò lọ́jọ́ ọ̀la,Láti jẹ́ ẹ̀rí tó máa wà títí láé.+   Torí pé ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ni wọ́n,+ àwọn ẹlẹ́tàn ọmọ,+Àwọn ọmọ tí kò fẹ́ gbọ́ òfin* Jèhófà.+ 10  Wọ́n ń sọ fún àwọn aríran pé, ‘Ẹ má ṣe ríran,’ Àti fún àwọn olùríran pé, ‘Ẹ má sọ àwọn ìran tó jẹ́ òótọ́ fún wa.+ Ọ̀rọ̀ dídùn* ni kí ẹ bá wa sọ; ìran ẹ̀tàn ni kí ẹ máa rí.+ 11  Ẹ yà kúrò lọ́nà; ẹ fọ̀nà sílẹ̀. Ẹ má fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì síwájú wa mọ́.’”+ 12  Torí náà, ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Torí pé ẹ ò gba ọ̀rọ̀ yìí,+Tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé jìbìtì àti ẹ̀tàn,Tí ẹ sì gbára lé àwọn nǹkan yìí,+ 13  Ẹ̀ṣẹ̀ yìí máa dà bí ògiri tó ti sán fún yín,Bí ògiri gíga tó wú, tó máa tó wó,Ó máa wó lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́. 14  Ó máa fọ́ bí ìṣà ńlá tó jẹ́ ti amọ̀kòkò,Ó máa fọ́ túútúú débi pé kò ní sí àfọ́kù kankan,Láti fi wa iná láti ibi ìdáná Tàbí láti fi bu omi nínú adágún.”* 15  Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ sì sinmi, ẹ máa rígbàlà;Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+ Àmọ́ kò wù yín.+ 16  Dípò ìyẹn, ẹ sọ pé: “Rárá, a máa gun ẹṣin sá lọ!” Ẹ sì máa sá lọ lóòótọ́. “A máa gun àwọn ẹṣin tó ń yára kánkán!”+ Àwọn tó ń lépa yín sì máa yára kánkán.+ 17  Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) máa gbọ̀n rìrì nítorí ìhàlẹ̀ ẹnì kan;+Ìhàlẹ̀ ẹni márùn-ún máa mú kí ẹ sá,Títí ohun tó ṣẹ́ kù nínú yín fi máa dà bí òpó lórí òkè ńlá,Bí òpó tí wọ́n fi ṣe àmì lórí òkè kékeré.+ 18  Àmọ́ Jèhófà ń fi sùúrù dúró* láti ṣojúure sí yín,+Ó sì máa dìde láti ṣàánú yín.+ Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.+ Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.*+ 19  Tí àwọn èèyàn bá ń gbé ní Síónì, ní Jerúsálẹ́mù,+ o ò ní sunkún rárá.+ Ó dájú pé ó máa ṣojúure sí ọ tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́; ó máa dá ọ lóhùn ní gbàrà tó bá gbọ́ ọ.+ 20  Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa fi wàhálà ṣe oúnjẹ fún yín, tó sì máa fi ìyà ṣe omi fún yín,+ Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá ò ní fi ara rẹ̀ pa mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, o sì máa fi ojú ara rẹ rí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá.+ 21  Etí rẹ sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ pé, “Èyí ni ọ̀nà.+ Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,” tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá ọ̀tún tàbí tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yà sí apá òsì.+ 22  Ẹ ó sọ fàdákà tí ẹ fi bo àwọn ère gbígbẹ́ yín àti wúrà tí ẹ fi bo àwọn ère onírin*+ yín di aláìmọ́. Ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí wọ́n fi ṣe nǹkan oṣù, ẹ ó sì sọ fún wọn pé: “A ò fẹ́ mọ́!”*+ 23  Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+ 24  Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ máa jẹ oúnjẹ ẹran tí wọ́n fi ewéko olómi-kíkan sí, èyí tí wọ́n fi ṣọ́bìrì àti àmúga fẹ́. 25  Odò àti ipadò máa wà lórí gbogbo òkè ńlá tó rí gogoro àti gbogbo òkè kéékèèké tó ga,+ ní ọjọ́ tí a pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ tí àwọn ilé gogoro bá ṣubú. 26  Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú máa dà bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; ìmọ́lẹ̀ oòrùn sì máa lágbára sí i ní ìlọ́po méje,+ bí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ méje, ní ọjọ́ tí Jèhófà bá di àfọ́kù àwọn èèyàn rẹ̀,*+ tó sì wo ọgbẹ́ ńlá tó dá sí wọn lára nígbà tó kọ lù wọ́n sàn.+ 27  Wò ó! Orúkọ Jèhófà ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,Inú ń bí i gan-an, ó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà* tó ṣú bolẹ̀. Ìbínú kún ètè rẹ̀,Ahọ́n rẹ̀ sì dà bí iná tó ń jẹni run.+ 28  Ẹ̀mí* rẹ̀ dà bí àkúnya ọ̀gbàrá tó muni dé ọrùn,Láti mi àwọn orílẹ̀-èdè jìgìjìgì nínú ajọ̀ ìparun;*Ìjánu sì máa wà ní páárì àwọn èèyàn+ náà láti kó wọn ṣìnà. 29  Àmọ́ orin yín máa dà bí èyí tí wọ́n kọ ní òruNígbà tí ẹ̀ ń múra sílẹ̀* fún àjọyọ̀,+Inú yín sì máa dùn bíi ti ẹniTó ń rìn tòun ti fèrè*Bó ṣe ń lọ sí òkè Jèhófà, sọ́dọ̀ Àpáta Ísírẹ́lì.+ 30  Jèhófà máa mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀ tó gbayì,+Ó sì máa fi apá rẹ̀ hàn+ bó ṣe ń fi ìbínú tó le sọ̀ kalẹ̀ bọ̀,+Pẹ̀lú ọwọ́ iná tó ń jẹni run,+Òjò líle tó bẹ̀rẹ̀ lójijì,+ ìjì tó ń sán ààrá àti àwọn òkúta yìnyín.+ 31  Nítorí ohùn Jèhófà, jìnnìjìnnì máa bo Ásíríà;+Ó máa fi ọ̀pá lù ú.+ 32  Gbogbo bó ṣe ń fi ọ̀pá rẹ̀ tó fi ń jẹni níyà,Èyí tí Jèhófà máa mú wá sórí Ásíríà,Máa jẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlù tanboríìnì àti háàpù,+Bó ṣe ń fi ọwọ́ rẹ̀ sí wọn lójú ogun.+ 33  Torí pé ó ti múra Tófétì*+ rẹ̀ sílẹ̀;Ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba pẹ̀lú.+ Ó ti to igi jọ pelemọ, ó sì fẹ̀,Pẹ̀lú iná tó ń jó lala àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi. Èémí Jèhófà, tó dà bí ọ̀gbàrá imí ọjọ́,Máa dáná sí i.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ta ohun tí wọ́n fi rúbọ sílẹ̀,” ó ṣe kedere pé ṣíṣe àdéhùn ló ń sọ.
Ní Héb., “sínú ibi ààbò Fáráò.”
Tàbí “láìgbọ́ tẹnu mi.”
Tàbí “ejò olóró tó ń yára kánkán.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Ní Héb., “tó dùn-ún gbọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “kòtò omi.”
Tàbí “ń fojú sọ́nà.”
Tàbí “ń fojú sọ́nà fún un.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí kó jẹ́, “ẹ sì máa pè wọ́n ní ohun ìdọ̀tí.”
Ní Héb., “ó sì máa lóròóró dáadáa.”
Tàbí “egungun àwọn èèyàn rẹ̀ tó fọ́.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Ní Héb., “ajọ̀ àìníláárí.”
Tàbí “Èémí.”
Tàbí “sọ ara yín di mímọ́.”
Tàbí “tó ń tẹ̀ lé ìró fèrè bó ṣe ń rìn.”
“Tófétì” tí wọ́n lò níbí dúró fún ibi tí wọ́n ti ń dáná sun nǹkan, èyí tó ṣàpẹẹrẹ ìparun.