Àìsáyà 34:1-17

  • Jèhófà máa gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè (1-8)

  • Édómù máa di ahoro (9-17)

34  Ẹ sún mọ́ tòsí kí ẹ lè gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,Kí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ̀yin èèyàn. Kí ayé àti ohun tó kún inú rẹ̀ fetí sílẹ̀,Ilẹ̀ àti gbogbo èso rẹ̀.   Torí Jèhófà ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,+Inú rẹ̀ sì ń ru sí gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn.+ Ó máa pa wọ́n run;Ó máa pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ.+   A máa ju àwọn èèyàn tí a pa síta,Òórùn burúkú àwọn òkú wọn sì máa ròkè;+Àwọn òkè máa yọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn.*+   Gbogbo ọmọ ogun ọ̀run máa jẹrà dà nù,A sì máa ká ọ̀run jọ bí àkájọ ìwé. Gbogbo ọmọ ogun wọn máa rọ dà nù,Bí ewé tó ti rọ ṣe ń já bọ́ lára àjàràÀti bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó ti bà jẹ́ ṣe ń já bọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́.   “Torí idà mi máa rin gbingbin ní ọ̀run.+ Ó máa sọ̀ kalẹ̀ sórí Édómù láti ṣèdájọ́,+Sórí àwọn èèyàn tí màá pa run.   Jèhófà ní idà kan; ẹ̀jẹ̀ máa bò ó. Ọ̀rá+ máa bò ó,Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ àgbò àti ewúrẹ́ máa bò ó,Ọ̀rá kíndìnrín àwọn àgbò máa bò ó. Torí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà,Ó máa pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Édómù.+   Àwọn akọ màlúù igbó máa bá wọn sọ̀ kalẹ̀,Àwọn akọ ọmọ màlúù pẹ̀lú àwọn alágbára. Ẹ̀jẹ̀ máa rin ilẹ̀ wọn gbingbin,Ọ̀rá sì máa rin iyẹ̀pẹ̀ wọn gbingbin.”   Torí Jèhófà ní ọjọ́ ẹ̀san,+Ọdún ẹ̀san torí ẹjọ́ lórí Síónì.+   Àwọn odò rẹ̀* máa yí pa dà di ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀,Iyẹ̀pẹ̀ rẹ̀ máa di imí ọjọ́,Ilẹ̀ rẹ̀ sì máa dà bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tó ń jó. 10  A ò ní pa á, ní òru tàbí ní ọ̀sán;Èéfín rẹ̀ á máa ròkè títí láé. Ibi ìparun ló máa jẹ́ láti ìran dé ìran;Kò sẹ́ni tó máa gba ibẹ̀ kọjá títí láé àti láéláé.+ 11  Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ á máa gbé ibẹ̀,Àwọn òwìwí elétí gígùn àti àwọn ẹyẹ ìwò á máa gbé inú rẹ̀. Ó máa na okùn ìdíwọ̀n òfìfo sórí rẹ̀ Àti okùn ìwọ̀n, láti sọ ọ́ di ahoro.* 12  Wọn ò ní pe ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì wá jọba,Gbogbo ìjòyè rẹ̀ ò sì ní já mọ́ nǹkan kan mọ́. 13  Ẹ̀gún máa hù nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,Èsìsì àti èpò ẹlẹ́gùn-ún máa hù nínú àwọn ibi ààbò rẹ̀. Ó máa di ilé àwọn ajáko,*+Ibi àkámọ́ àwọn ògòǹgò. 14  Àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀ máa pàdé àwọn ẹranko tó ń hu,Ewúrẹ́ igbó* sì máa ké sí èkejì rẹ̀. Àní, ibẹ̀ ni ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́ máa wọ̀ sí, tó sì ti máa rí ibi ìsinmi. 15  Ibẹ̀ ni ejò ọlọ́fà máa kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí, tó sì máa yé ẹyin sí,Ó máa pa ẹyin, ó sì máa kó wọn jọ sábẹ́ òjìji rẹ̀. Àní, ibẹ̀ ni àwọn àwòdì máa kóra jọ sí, kálukú pẹ̀lú èkejì rẹ̀. 16  Ẹ wá a nínú ìwé Jèhófà, kí ẹ sì kà á sókè: A ò ní wá ìkankan nínú wọn tì;Èyíkéyìí nínú wọn ò ní ṣaláìní ẹnì kejì,Torí pé ẹnu Jèhófà ni àṣẹ náà ti wá,Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì kó wọn jọ. 17  Òun ni Ẹni tó ṣẹ́ kèké fún wọn,Ọwọ́ rẹ̀ sì ti wọn ibi tí a yàn fún wọn.* Ó máa jẹ́ tiwọn títí láé;Ibẹ̀ ni wọ́n á máa gbé láti ìran dé ìran.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ẹ̀jẹ̀ wọn á máa ṣàn lórí àwọn òkè.”
Ó ṣe kedere pé Bósírà, olú ìlú Édómù ló ń tọ́ka sí.
Ní Héb., “Àti àwọn òkúta ahoro.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́.”
Ní Héb., “fi okùn ìdíwọ̀n pín in fún wọn.”