Àìsáyà 35:1-10
35 Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀,+Aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.+
2 Ó dájú pé ó máa yọ ìtànná;+Ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa kígbe ayọ̀.
A máa fún un ní ògo Lẹ́bánónì,+Ẹwà Kámẹ́lì+ àti ti Ṣárónì.+
Wọ́n máa rí ògo Jèhófà, ẹwà Ọlọ́run wa.
3 Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lágbára lókun,Ẹ sì mú kí àwọn orúnkún tó ń gbọ̀n dúró gbọn-in.+
4 Ẹ sọ fún àwọn tó ń ṣàníyàn nínú ọkàn wọn pé:
“Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má bẹ̀rù.
Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín máa wá gbẹ̀san,Ọlọ́run máa wá láti fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹni.+
Ó máa wá gbà yín sílẹ̀.”+
5 Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú máa là,+Etí àwọn adití sì máa ṣí.+
6 Ní àkókò yẹn, ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín,+Ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ sì máa kígbe ayọ̀.+
Torí omi máa tú jáde ní aginjù,Odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.
7 Ilẹ̀ tí ooru ti mú kó gbẹ táútáú máa di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Ilẹ̀ gbígbẹ sì máa di ìsun omi.+
Koríko tútù, esùsú àti òrépètéMáa wà ní ibùgbé tí àwọn ajáko* ti ń sinmi.+
8 Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀,+Àní, ọ̀nà tí à ń pè ní Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.
Aláìmọ́ kò ní gba ibẹ̀ kọjá.+
Àwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ló wà fún;Òmùgọ̀ kankan ò sì ní rìn gbéregbère lọ síbẹ̀.
9 Kò ní sí kìnnìún kankan níbẹ̀,Ẹranko ẹhànnà kankan kò sì ní wá sórí rẹ̀.
A ò ní rí wọn níbẹ̀;+Àwọn tí a tún rà nìkan ló máa gba ibẹ̀.+
10 Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà wá,+ wọ́n sì máa kígbe ayọ̀ wá sí Síónì.+
Ayọ̀ tí kò lópin máa dé orí wọn ládé.+
Wọ́n á máa yọ̀ gidigidi, inú wọn á sì máa dùn,Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́.+