Àìsáyà 40:1-31
40 “Ẹ tu àwọn èèyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,” ni Ọlọ́run yín wí.+
2 “Ẹ sọ ọ̀rọ̀ tó máa wọ Jerúsálẹ́mù lọ́kàn,*Kí ẹ sì kéde fún un pé iṣẹ́ rẹ̀ tó pọn dandan ti parí,Pé a ti san gbèsè ẹ̀bi tó jẹ.+
Ó ti gba ohun tó kún rẹ́rẹ́* lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”+
3 Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé:
“Ẹ tún ọ̀nà Jèhófà ṣe!*+
Ẹ la ọ̀nà tó tọ́ + gba inú aṣálẹ̀ fún Ọlọ́run wa.+
4 Kí ẹ mú kí gbogbo àfonífojì ga sókè,Kí ẹ sì mú kí gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké wálẹ̀.
Kí ilẹ̀ tó rí gbágungbàgun di ilẹ̀ tó tẹ́jú,Kí ilẹ̀ kángunkàngun sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀.+
5 A máa ṣí ògo Jèhófà payá,+Gbogbo ẹran ara* sì jọ máa rí i,+Torí Jèhófà ti fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.”
6 Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń sọ pé: “Ké jáde!”
Ẹlòmíì béèrè pé: “Igbe kí ni kí n ké?”
“Koríko tútù ni gbogbo ẹran ara.*
Gbogbo ìfẹ́ wọn tí kì í yẹ̀ dà bí ìtànná àwọn ewéko.+
7 Koríko tútù máa ń gbẹ dà nù,Ìtànná máa ń rọ,+Torí pé èémí* Jèhófà fẹ́ lù ú.+
Ó dájú pé koríko tútù ni àwọn èèyàn náà.
8 Koríko tútù máa ń gbẹ dà nù,Ìtànná máa ń rọ,Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa máa wà títí láé.”+
9 Lọ sórí òkè tó ga,Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Síónì.+
Gbé ohùn rẹ sókè tagbáratagbára,Ìwọ obìnrin tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá fún Jerúsálẹ́mù.
Gbé e sókè, má bẹ̀rù.
Kéde fún àwọn ìlú Júdà pé: “Ọlọ́run yín rèé.”+
10 Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa wá tagbáratagbára,Apá rẹ̀ sì máa bá a ṣàkóso.+
Wò ó! Èrè rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,Ẹ̀san rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀.+
11 Ó máa bójú tó* agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn.+
Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ,Ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.
Ó máa rọra da àwọn tó ń fọ́mọ lọ́mú.+
12 Ta ló ti fi àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ wọn omi,+Tó sì ti fi ìbú àtẹ́lẹwọ́* rẹ̀ wọn* ọ̀run?
Ta ló ti kó gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sínú òṣùwọ̀n,+Tàbí tó ti wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n,Tó sì ti wọn àwọn òkè kéékèèké lórí òṣùwọ̀n?
13 Ta ló ti díwọ̀n* ẹ̀mí Jèhófà,Ta ló sì lè dá a lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?+
14 Ta ló ti bá fikùn lukùn kó lè ní òye,Tàbí ta ló kọ́ ọ ní ọ̀nà ìdájọ́ òdodo,Tó kọ́ ọ ní ìmọ̀,Tàbí tó fi ọ̀nà òye tòótọ́ hàn án?+
15 Wò ó! Àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan látinú korobá,A sì kà wọ́n sí eruku fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ lórí òṣùwọ̀n.+
Wò ó! Ó ń gbé àwọn erékùṣù sókè bí eruku lẹ́búlẹ́bú.
16 Lẹ́bánónì pàápàá kò tó láti mú kí iná máa jó,*Àwọn ẹran igbó rẹ̀ kò sì tó fún ẹbọ sísun.
17 Gbogbo orílẹ̀-èdè dà bí ohun tí kò sí ní iwájú rẹ̀;+Ó kà wọ́n sí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan, bí ohun tí kò sí rárá.+
18 Ta ni ẹ lè fi Ọlọ́run wé?+
Kí lẹ lè fi sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó máa jọ ọ́?+
19 Oníṣẹ́ ọnà ṣe ère,*Oníṣẹ́ irin fi wúrà bò ó,+Ó sì fi fàdákà rọ ẹ̀wọ̀n.
20 Ó mú igi láti fi ṣe ọrẹ,+Igi tí kò ní jẹrà.
Ó wá oníṣẹ́ ọnà tó já fáfá,Láti ṣe ère gbígbẹ́ tí kò ní ṣubú.+
21 Ṣé ẹ kò mọ̀ ni?
Ṣé ẹ kò tíì gbọ́ ni?
Ṣé wọn ò sọ fún yín láti ìbẹ̀rẹ̀ ni?
Ṣé kò yé yín látìgbà tí a ti dá ayé?+
22 Ẹnì kan wà tó ń gbé orí òbìrìkìtì* ayé,+Àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ sì dà bíi tata,Ó ń na ọ̀run bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó ní ihò wínníwínní,Ó sì tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé.+
23 Ó ń sọ àwọn aláṣẹ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan,Ó sì ń sọ àwọn adájọ́* ayé di ohun tí kò sí rárá.
24 Bóyá la gbìn wọ́n rí,Bóyá la fúnrúgbìn wọn rí,Bóyá ni kùkùté wọn ta gbòǹgbò rí nínú ilẹ̀,A fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n, wọ́n sì gbẹ dà nù,Afẹ́fẹ́ gbé wọn lọ bí àgékù pòròpórò.+
25 “Ta lẹ lè fi mí wé bóyá mo bá a dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.
26 “Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó.
Ta ló dá àwọn nǹkan yìí?+Òun ni Ẹni tó ń mú wọn jáde bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní iye-iye;Ó ń fi orúkọ pe gbogbo wọn.+
Torí okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu, agbára rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù,+Ìkankan nínú wọn ò di àwátì.
27 Ìwọ Jékọ́bù, kí ló dé tí o fi sọ báyìí, àti ìwọ Ísírẹ́lì, kí ló dé tí o fi kéde pé,‘Jèhófà ò rí ọ̀nà mi,Mi ò sì rí ìdájọ́ òdodo gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run’?+
28 Ṣé o ò mọ̀ ni? Ṣé o ò tíì gbọ́ ni?
Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ayé, jẹ́ Ọlọ́run títí ayé.+
Kì í rẹ̀ ẹ́, okun rẹ̀ kì í sì í tán.+
Àwámáridìí ni òye rẹ̀.*+
29 Ó ń fún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára,Ó sì ń fún àwọn tí kò lókun* ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun.+
30 Ó máa rẹ àwọn ọmọdékùnrin, okun wọn sì máa tán,Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa kọsẹ̀, wọ́n á sì ṣubú,
31 Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà.
Wọ́n máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì.+
Wọ́n máa sáré, okun ò ní tán nínú wọn;Wọ́n máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún Jerúsálẹ́mù.”
^ Tàbí “ìlọ́po méjì.”
^ Tàbí “Ẹ múra ọ̀nà Jèhófà sílẹ̀!”
^ Tàbí “Gbogbo èèyàn.”
^ Tàbí “gbogbo èèyàn.”
^ Tàbí “ẹ̀mí.”
^ Tàbí “darí.”
^ Àlàfo tó wà láàárín orí àtàǹpàkò àti ìka tó kéré jù téèyàn bá yàka. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “díwọ̀n.”
^ Tàbí kó jẹ́, “lóye.”
^ Tàbí “kò lè mú igi ìdáná tó máa tó jáde.”
^ Tàbí “ère dídà.”
^ Tàbí “òbìrí.”
^ Tàbí “àwọn alákòóso.”
^ Tàbí “Òye rẹ̀ kò ṣeé lóye.”
^ Tàbí “tí kò ní agbára (okun) láti ṣiṣẹ́.”