Àìsáyà 41:1-29
41 “Ẹ dákẹ́, kí ẹ sì fetí sí mi,* ẹ̀yin erékùṣù;Kí àwọn orílẹ̀-èdè pa dà ní agbára.
Kí wọ́n sún mọ́ tòsí; kí wọ́n wá sọ̀rọ̀.+
Ẹ jẹ́ ká kóra jọ fún ìdájọ́.
2 Ta ló ti gbé ẹnì kan dìde láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+Tó pè é nínú òdodo wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀,*Láti fa àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́,Kó sì mú kó tẹ àwọn ọba lórí ba?+
Ta ló ń sọ wọ́n di eruku níwájú idà rẹ̀,Bí àgékù pòròpórò tí atẹ́gùn ń gbé kiri níwájú ọfà rẹ̀?
3 Ó ń lé wọn, ohunkóhun ò sì dí i lọ́wọ́Lójú ọ̀nà tí kò fẹsẹ̀ tẹ̀ rí.
4 Ta ló ṣe èyí? Iṣẹ́ ọwọ́ ta sì ni,Tó ń pe àwọn ìran láti ìbẹ̀rẹ̀?
Èmi Jèhófà, ni Ẹni Àkọ́kọ́;+Èmi kan náà ni mo sì wà pẹ̀lú àwọn tó kẹ́yìn.”+
5 Àwọn erékùṣù rí i, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
Àwọn ìkángun ayé bẹ̀rẹ̀ sí í wárìrì.
Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì bọ́ síwájú.
6 Kálukú ń ran ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́,Wọ́n ń sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ẹ jẹ́ alágbára.”
7 Torí náà, oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin+ lókun;Ẹni tó ń fi òòlù irin* lu nǹkan di pẹlẹbẹŃ fún ẹni tó ń fi òòlù lu nǹkan lórí irin lókun.
Ó ń sọ nípa ohun tí wọ́n jó pọ̀ pé: “Ó dáa.”
Wọ́n wá fi ìṣó kàn án, kó má bàa ṣubú.
8 “Àmọ́ ìwọ Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ mi,+Ìwọ Jékọ́bù, ẹni tí mo yàn,+Ọmọ* Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi,+
9 Ìwọ tí mo mú láti àwọn ìkángun ayé,+Ìwọ tí mo pè láti àwọn apá ibi tó jìnnà jù níbẹ̀.
Mo sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;+Mo ti yàn ọ́; Mi ò kọ̀ ọ́.+
10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+
Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+
Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’
11 Wò ó! Ojú máa ti gbogbo àwọn tó ń bínú sí ọ, wọ́n sì máa tẹ́.+
Àwọn tó ń bá ọ jà máa di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì máa ṣègbé.+
12 O máa wá àwọn tó ń bá ọ jà, àmọ́ o ò ní rí wọn;Àwọn tó ń bá ọ jagun máa dà bí ohun tí kò sí, bí ohun tí kò sí rárá.+
13 Torí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú,Ẹni tó ń sọ fún ọ pé, ‘Má bẹ̀rù. Màá ràn ọ́ lọ́wọ́.’+
14 Má bẹ̀rù, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú,*+Ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì, màá ràn yín lọ́wọ́,” ni Jèhófà, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì wí.
15 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ohun tí wọ́n fi ń pakà,+Ohun tuntun tó ní eyín olójú méjì tí wọ́n fi ń pakà.
O máa tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, o máa fọ́ wọn túútúú,O sì máa ṣe àwọn òkè kéékèèké bí ìyàngbò.*
16 O máa fẹ́ wọn bí ọkà,
Atẹ́gùn sì máa gbé wọn lọ;Ìjì máa tú wọn ká.
Inú rẹ máa dùn torí Jèhófà,+O sì máa fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì yangàn.”+
17 “Àwọn aláìní àti àwọn tálákà ń wá omi, àmọ́ kò sí rárá.
Òùngbẹ ti mú kí ahọ́n wọn gbẹ.+
Èmi Jèhófà máa dá wọn lóhùn.+
Èmi Ọlọ́run Ísírẹ́lì ò ní fi wọ́n sílẹ̀.+
18 Màá mú kí odò ṣàn lórí àwọn òkè tí nǹkan ò hù sí,+Màá sì mú kí omi sun ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.+
Màá sọ aginjù di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Màá sì sọ ilẹ̀ tí kò lómi di orísun omi. +
19 Màá gbin igi kédárì sínú aṣálẹ̀,Màá gbin igi bọn-ọ̀n-ní, igi mátílì àti igi ahóyaya síbẹ̀.+
Màá gbin igi júnípà sí aṣálẹ̀ tó tẹ́jú,Pẹ̀lú igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì,+
20 Kí gbogbo èèyàn lè rí i, kí wọ́n sì mọ̀,Kí wọ́n fiyè sí i, kó sì yé wọn,Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ló sì dá a.”+
21 “Ẹ ro ẹjọ́ yín,” ni Jèhófà wí.
“Ẹ gbèjà ara yín,” ni Ọba Jékọ́bù wí.
22 “Ẹ mú ẹ̀rí wá, kí ẹ sì sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún wa.
Ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́* fún wa,Ká lè ronú nípa wọn,* ká sì mọ ibi tí wọ́n máa já sí.
Tàbí kí ẹ kéde àwọn ohun tó ń bọ̀ fún wa.+
23 Ẹ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa,Ká lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.+
Àní, ẹ ṣe nǹkan kan, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú,Kó lè yà wá lẹ́nu tí a bá rí i.+
24 Ẹ wò ó! Ohun tí kò sí ni yín,Iṣẹ́ ọwọ́ yín kò sì já mọ́ nǹkan kan.+
Ohun ìríra ni ẹnikẹ́ni tó bá yàn yín.+
25 Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, ó sì máa wá,+Ẹnì kan láti ibi tí oòrùn ti ń yọ*+ tó máa ké pe orúkọ mi.
Ó máa tẹ àwọn alákòóso* mọ́lẹ̀ bíi pé amọ̀ ni wọ́n,+Bí amọ̀kòkò tó ń tẹ amọ̀ rírin mọ́lẹ̀.
26 Ta ló sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀, ká lè mọ̀,Tàbí láti ìgbà àtijọ́, ká lè sọ pé, ‘Ó tọ̀nà’?+
Lóòótọ́, kò sí ẹni tó sọ ọ́!
Kò sí ẹni tó kéde rẹ̀!
Kò sí ẹni tó gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ rẹ!”+
27 Èmi ni mo kọ́kọ́ sọ fún Síónì pé: “Wò ó! Àwọn nìyí!”+
Màá sì rán ẹni tó ń mú ìròyìn ayọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù.+
28 Àmọ́ mò ń wò, kò sì sí ẹnì kankan;Kò sí ìkankan nínú wọn tó ń gbani nímọ̀ràn.
Mo sì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n fèsì.
29 Wò ó! Gbogbo wọn jẹ́ ẹ̀tàn.*
Iṣẹ́ wọn kò já mọ́ nǹkan kan.
Afẹ́fẹ́ lásán àti ohun tí kò sí rárá ni àwọn ère onírin* wọn.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ẹ dákẹ́ níwájú mi.”
^ Tàbí “láti ìlà oòrùn.”
^ Ìyẹn, láti sìn Ín.
^ Ìyẹn, hámà ńlá tí àwọn alágbẹ̀dẹ máa ń lò.
^ Ní Héb., “Èso.”
^ Ìyẹn, ẹni tó rẹlẹ̀ tí kò sì lè gbèjà ara rẹ̀.
^ Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
^ Ìyẹn, koríko etí omi.
^ Ní Héb., “àkọ́kọ́.”
^ Tàbí “fọkàn sí i.”
^ Tàbí “láti ìlà oòrùn.”
^ Tàbí “ìjòyè.”
^ Tàbí “ohun tí kò sí rárá.”
^ Tàbí “ère dídà.”