Àìsáyà 45:1-25
45 Ohun tí Jèhófà sọ fún ẹni tó yàn nìyí, fún Kírúsì,+Ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú,+Láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀,+Láti gba ohun ìjà* àwọn ọba,Láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀,Kí wọ́n má sì ti àwọn ẹnubodè:
2 “Màá lọ níwájú rẹ,+Màá sì mú kí àwọn òkè di ilẹ̀ tó tẹ́jú.
Màá fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà sí wẹ́wẹ́,Màá sì gé àwọn ọ̀pá irin lulẹ̀.+
3 Màá fún ọ ní àwọn ìṣúra tó wà nínú òkùnkùnÀti àwọn ìṣúra tó pa mọ́ láwọn ibi tí kò hàn síta,+Kí o lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń fi orúkọ rẹ pè ọ́.+
4 Torí ìránṣẹ́ mi Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì àyànfẹ́ mi,Màá fi orúkọ rẹ pè ọ́.
Màá fún ọ ní orúkọ tó lọ́lá, bó ò tiẹ̀ mọ̀ mí.
5 Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.
Kò sí Ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+
Màá fún ọ lókun,* bó ò tiẹ̀ mọ̀ mí,
6 Kí àwọn èèyàn lè mọ̀,Láti ibi tí oòrùn ti ń yọ, dé ibi tó ti ń wọ̀*Pé kò sí ẹnì kankan yàtọ̀ sí mi.+
Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.+
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀,+ mo sì ṣe òkùnkùn,+Mo dá àlàáfíà,+ mo sì ṣe àjálù;+Èmi Jèhófà ni mò ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.
8 Ẹ̀yin ọ̀run, ẹ rọ òjò sílẹ̀ látòkè;+Kí ojú ọ̀run rọ òdodo sílẹ̀.
Kí ilẹ̀ lanu, kó sì so èso ìgbàlà,Kó mú kí òdodo rú yọ lẹ́ẹ̀kan náà.+
Èmi Jèhófà ti dá a.”
9 Ó mà ṣe fún ẹni tó ń bá Aṣẹ̀dá rẹ̀* fa nǹkan* o,Torí ó dà bí àfọ́kù ìkòkò lásánLáàárín àwọn àfọ́kù ìkòkò míì tó wà nílẹ̀!
Ṣé ó yẹ kí amọ̀ sọ fún Amọ̀kòkò* pé: “Kí lò ń mọ?”+
Àbí ó yẹ kí iṣẹ́ rẹ sọ pé: “Kò ní ọwọ́”?*
10 Ó mà ṣe o, fún ẹni tó ń sọ fún bàbá pé: “Kí lo bí?”Àti fún obìnrin pé: “Kí lo fẹ́ bí?”*
11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ Ẹni tó dá a:
“Ṣé o máa bi mí nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ ni,Kí o sì pàṣẹ fún mi nípa àwọn ọmọ mi+ àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi?
12 Mo dá ayé,+ mo sì dá èèyàn sórí rẹ̀.+
Ọwọ́ ara mi ni mo fi na ọ̀run,+Mo sì ń pàṣẹ fún gbogbo ọmọ ogun wọn.”+
13 “Mo ti gbé ẹnì kan dìde nínú òdodo,+Màá sì mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
Òun ló máa kọ́ ìlú mi,+Tó sì máa dá àwọn ìgbèkùn mi sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ + tàbí láìgba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
14 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Èrè* Íjíbítì àti ọjà* Etiópíà àtàwọn Sábéà, àwọn tó ga,Máa wá bá ọ, wọ́n á sì di tìrẹ.
Wọ́n á máa rìn lẹ́yìn rẹ, pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè wọ́n,Wọ́n á wá bá ọ, wọ́n á sì tẹrí ba fún ọ.+
Wọ́n á gbàdúrà, wọ́n á sọ fún ọ pé, ‘Ó dájú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ,+Kò sì sí ẹlòmíì; kò sí Ọlọ́run míì.’”
15 Lóòótọ́, Ọlọ́run tó ń fi ara rẹ̀ pa mọ́ ni ọ́,Ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Olùgbàlà.+
16 Ojú máa ti gbogbo wọn, wọ́n sì máa tẹ́;Ìtìjú ni gbogbo àwọn tó ń ṣe ère máa bá kúrò.+
17 Àmọ́ Jèhófà máa gba Ísírẹ́lì là, ìgbàlà náà sì máa jẹ́ títí láé.+
Ojú ò ní tì yín, ìtìjú ò sì ní bá yín títí ayé.+
18 Torí ohun tí Jèhófà sọ nìyí,Ẹlẹ́dàá ọ̀run,+ Ọlọ́run tòótọ́,Ẹni tó dá ayé, Aṣẹ̀dá rẹ̀ tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+Ẹni tí kò kàn dá a lásán,* àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀:+
“Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.
19 Mi ò sọ̀rọ̀ ní ibi tó pa mọ́,+ ní ilẹ̀ tó ṣókùnkùn;Mi ò sọ fún ọmọ* Jékọ́bù pé,‘Ẹ kàn máa wá mi lásán.’*
Èmi ni Jèhófà, tó ń sọ ohun tó jẹ́ òdodo, tó sì ń kéde ohun tó tọ́.+
20 Ẹ kóra jọ, kí ẹ sì wá.
Ẹ jọ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin tí ẹ yè bọ́ látinú àwọn orílẹ̀-èdè.+
Wọn ò mọ nǹkan kan, àwọn tó ń gbé ère gbígbẹ́ kiri,Tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbà wọ́n.+
21 Ẹ sọ tẹnu yín, ẹ ro ẹjọ́ yín.
Kí wọ́n fikùn lukùn ní ìṣọ̀kan.
Ta ló ti sọ èyí tipẹ́tipẹ́,Tó sì kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́?
Ṣebí èmi, Jèhófà ni?
Kò sí Ọlọ́run míì, àfi èmi;Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà,+ kò sí ẹlòmíì yàtọ̀ sí mi.+
22 Ẹ yíjú sí mi, kí ẹ sì rí ìgbàlà,+ gbogbo ìkángun ayé.
Torí èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíì.+
23 Mo ti fi ara mi búra;Ọ̀rọ̀ ti jáde lẹ́nu mi nínú òdodo,Kò sì ní pa dà:+
Gbogbo eékún máa tẹ̀ ba fún mi,Gbogbo ahọ́n máa búra láti dúró ṣinṣin,+
24 Wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé inú Jèhófà ni òdodo tòótọ́ àti okun wà.
Gbogbo àwọn tó ń bínú sí i máa fi ìtìjú wá síwájú rẹ̀.
25 Gbogbo ọmọ* Ísírẹ́lì máa fi hàn pé àwọn ṣe ohun tó tọ́ nínú Jèhófà,+Òun ni wọ́n á sì máa fi yangàn.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “tú àmùrè ìbàdí.”
^ Ní Héb., “dì ọ́ lámùrè gírígírí.”
^ Tàbí “Láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”
^ Tàbí “Ẹni tó dá a.”
^ Tàbí “bá Aṣẹ̀dá rẹ̀ jiyàn.”
^ Tàbí “Ẹni tó mọ ọ́n.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Àbí ó yẹ kí amọ̀ sọ pé: ‘Iṣẹ́ rẹ ò ní ọwọ́’?”
^ Tàbí “Kí lò ń rọbí rẹ̀?”
^ Tàbí kó jẹ́, “Àwọn alágbàṣe.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn oníṣòwò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “dá a pé kó ṣófo.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Tàbí “wá mi lórí òfo.”
^ Ní Héb., “èso.”