Àìsáyà 50:1-11

  • Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fa wàhálà (1-3)

  • Ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ onígbọràn (4-11)

    • Ahọ́n àti etí àwọn tí a kọ́ (4)

50  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ ìyá yín tí mo lé lọ dà? Àbí èwo nínú àwọn tí mo jẹ ní gbèsè ni mo tà yín fún? Ẹ wò ó! Torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín+ ni mo ṣe tà yín,Mo sì lé ìyá yín lọ torí àwọn àṣìṣe yín.+   Kí ló wá dé tí kò sí ẹnì kankan níbí nígbà tí mo dé? Kí ló dé tí ẹnì kankan ò dáhùn nígbà tí mo pè?+ Ṣé ọwọ́ mi kúrú jù láti rani pa dà ni,Àbí mi ò lágbára láti gbani sílẹ̀ ni?+ Wò ó! Mo bá òkun wí, ó sì gbẹ táútáú;+Mo sọ àwọn odò di aṣálẹ̀.+ Ẹja wọn jẹrà torí kò sí omi,Wọ́n sì kú torí òùngbẹ.   Mo fi ìṣúdùdù bo ọ̀run,+Mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀ wọ́n.”   Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́,*+Kí n lè mọ bó ṣe yẹ kí n fi ọ̀rọ̀ tó yẹ* dá ẹni tó ti rẹ̀ lóhùn.*+ Ó ń jí mi ní àràárọ̀;Ó ń jí etí mi kí n lè fetí sílẹ̀ bí àwọn tí a kọ́.+   Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣí etí mi,Mi ò sì ya ọlọ̀tẹ̀.+ Mi ò yíjú sí òdìkejì.+   Mo tẹ́ ẹ̀yìn mi fún àwọn tó ń lù mí,Mo sì gbé ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tó fa irun tu títí ó fi dán.* Mi ò fi ojú mi pa mọ́ fún àwọn ohun tó ń dójú tini àti itọ́.+   Àmọ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ràn mí lọ́wọ́.+ Ìdí nìyẹn tí ìtìjú ò fi ní bá mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi ṣe ojú mi bí akọ òkúta,+Mo sì mọ̀ pé ojú ò ní tì mí.   Ẹni tó ń pè mí ní olódodo wà nítòsí. Ta ló lè fẹ̀sùn kàn mí?*+ Jẹ́ ká jọ dìde dúró.* Ta ló fẹ́ bá mi ṣe ẹjọ́? Kó sún mọ́ mi.   Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ máa ràn mí lọ́wọ́. Ta ló máa sọ pé mo jẹ̀bi? Wò ó! Gbogbo wọn máa gbó bí aṣọ. Òólá* ló máa jẹ wọ́n run. 10  Ta ló bẹ̀rù Jèhófà nínú yín,Tó sì ń fetí sí ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀?+ Ta ló ti rìn nínú òkùnkùn biribiri láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan? Kó gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà, kó sì fara ti* Ọlọ́run rẹ̀. 11  “Ẹ wò ó! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dá iná,Tí ẹ̀ ń mú kí iná ta pàrà,Ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,Láàárín iná tí ẹ̀ ń mú kó ta pàrà. Ohun tí ẹ máa gbà lọ́wọ́ mi nìyí: Inú ìroragógó lẹ máa dùbúlẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
Ní Héb., “fi ọ̀rọ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “fún ẹni tó ti rẹ̀ lókun.”
Tàbí “ahọ́n tí a kọ́ dáadáa.”
Tàbí “àwọn tó fa irùngbọ̀n tu.”
Tàbí “bá mi fà á.”
Tàbí “dojú kọ ara wa.”
Tàbí “Kòkòrò.”
Tàbí “gbára lé.”