Àìsáyà 54:1-17
54 “Kígbe ayọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ!+
Tújú ká, kí o sì kígbe ayọ̀,+ ìwọ tí o kò ní ìrora ìbímọ rí,+Torí àwọn ọmọ* ẹni tó ti di ahoro pọ̀Ju àwọn ọmọ obìnrin tó ní ọkọ,”*+ ni Jèhófà wí.
2 “Mú kí ibi àgọ́ rẹ fẹ̀ sí i.+
Na àwọn aṣọ àgọ́ rẹ tó tóbi.
Má fawọ́ sẹ́yìn, mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn sí i,Kí o sì jẹ́ kí àwọn èèkàn àgọ́ rẹ lágbára.+
3 Torí pé o máa tàn sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì.
Àwọn ọmọ rẹ máa gba àwọn orílẹ̀-èdè,Wọ́n sì máa gbé àwọn ìlú tó ti di ahoro.+
4 Má bẹ̀rù,+ torí ojú ò ní tì ọ́;+Má sì jẹ́ kí ìtìjú bá ọ, torí o ò ní rí ìjákulẹ̀.
Torí o máa gbàgbé ìtìjú ìgbà ọ̀dọ́ rẹ,O ò sì ní rántí bí ojú ṣe tì ọ́ nígbà opó rẹ mọ́.”
5 “Torí pé Aṣẹ̀dá rẹ Atóbilọ́lá+ dà bí ọkọ* rẹ,+Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni Olùtúnrà rẹ.+
Ọlọ́run gbogbo ayé la ó máa pè é.+
6 Torí Jèhófà pè ọ́ bí ìyàwó tí wọ́n pa tì, tí ẹ̀dùn ọkàn sì bá,*+Bí ìyàwó tí wọ́n fẹ́ nígbà ọ̀dọ́, tí wọ́n wá kọ̀ sílẹ̀,” ni Ọlọ́run rẹ wí.
7 “Torí mo pa ọ́ tì fún ìgbà díẹ̀,Àmọ́ màá ṣàánú rẹ gidigidi, màá sì kó ọ jọ pa dà.+
8 Mo fi ojú mi pa mọ́ fún ọ fún àkókò díẹ̀ torí inú bí mi gidigidi,+Àmọ́ màá ṣàánú rẹ nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tó wà títí láé,”+ ni Jèhófà, Olùtúnrà rẹ+ wí.
9 “Bí àwọn ọjọ́ Nóà ló ṣe rí sí mi.+
Bí mo ṣe búra pé omi Nóà ò ní bo ayé mọ́,+Bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra pé mi ò ní bínú sí ọ mọ́, mi ò sì ní bá ọ wí mọ́.+
10 Àwọn òkè ńlá lè ṣí kúrò,Àwọn òkè kéékèèké sì lè mì tìtì,Àmọ́ ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+Májẹ̀mú àlàáfíà mi ò sì ní mì,”+ ni Jèhófà, Ẹni tó ń ṣàánú rẹ wí.+
11 “Ìwọ obìnrin tí ìyà ń jẹ,+ tí ìjì ń gbé síwá-sẹ́yìn, tí a kò tù nínú,+Màá fi àpòrọ́ líle mọ àwọn òkúta rẹ,Màá sì fi sàfáyà ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.+
12 Òkúta rúbì ni màá fi ṣe odi orí òrùlé rẹ,Àwọn òkúta tó ń tàn yinrin* ni màá fi ṣe àwọn ẹnubodè rẹ,Màá sì fi àwọn òkúta iyebíye ṣe gbogbo ààlà rẹ.
13 Jèhófà máa kọ́ gbogbo àwọn ọmọ* rẹ,+Àlàáfíà àwọn ọmọ* rẹ sì máa pọ̀ gan-an.+
14 O máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo.+
Ìnilára máa jìnnà réré sí ọ,+O ò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ohunkóhun ò sì ní já ọ láyà,Torí pé kò ní sún mọ́ ọ.+
15 Tí ẹnikẹ́ni bá gbéjà kò ọ́,Èmi kọ́ ni mo pa á láṣẹ.
Ẹnikẹ́ni tó bá gbéjà kò ọ́ máa ṣubú nítorí rẹ.”+
16 “Wò ó! Èmi fúnra mi ni mo dá oníṣẹ́ ọnà,Ẹni tó ń fẹ́ atẹ́gùn sí iná èédú,Tí iṣẹ́ rẹ̀ sì mú ohun ìjà jáde.
Èmi náà ni mo dá apanirun tó ń pani run.+
17 Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí ọ kò ní ṣàṣeyọrí,+Ahọ́n èyíkéyìí tó bá sì dìde sí ọ láti dá ọ lẹ́jọ́ ni wàá dá lẹ́bi.
Ogún* àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nìyí,Ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá,” ni Jèhófà wí.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọ̀gá.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
^ Tàbí “ọ̀gá.”
^ Ní Héb., “tí ẹ̀mí rẹ̀ sì gbọgbẹ́.”
^ Tàbí “òkúta iná.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
^ Tàbí “Ohun àjogúnbá.”