Àìsáyà 55:1-13

  • Ìkésíni láti jẹ, kí wọ́n sì mu lọ́fẹ̀ẹ́ (1-5)

  • Ẹ wá Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ṣeé gbára lé (6-13)

    • Ọ̀nà Ọlọ́run ga ju ti èèyàn lọ (8, 9)

    • Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa yọrí sí rere (10, 11)

55  Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òùngbẹ ń gbẹ,+ ẹ wá síbi omi!+ Ẹ̀yin tẹ́ ò ní owó, ẹ wá, ẹ rà, kí ẹ sì jẹ! Àní, ẹ wá, ẹ ra wáìnì àti wàrà+ lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó.+   Kí ló dé tí ẹ fi ń sanwó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ,Kí ló sì dé tí ẹ fi ń lo ohun tí ẹ ṣiṣẹ́ fún* sórí ohun tí kì í tẹ́ni lọ́rùn? Ẹ tẹ́tí sí mi dáadáa, kí ẹ sì jẹ ohun tó dáa,+Ohun tó dọ́ṣọ̀* sì máa mú inú yín dùn* gidigidi.+   Ẹ dẹ etí yín sílẹ̀, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi.+ Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ* ó sì máa wà láàyè nìṣó,Ó sì dájú pé màá bá yín dá májẹ̀mú tó máa wà títí láé+Bí mo ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tó jẹ́ òótọ́,* hàn sí Dáfídì.+   Wò ó! Mo fi ṣe ẹlẹ́rìí+ fún àwọn orílẹ̀-èdè,Aṣáájú+ àti aláṣẹ+ àwọn orílẹ̀-èdè.   Wò ó! O máa pe orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀,Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́ sì máa sáré wá sọ́dọ̀ rẹ,Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,Torí pé ó máa ṣe ọ́ lógo.+   Ẹ wá Jèhófà nígbà tí ẹ lè rí i.+ Ẹ pè é nígbà tó wà nítòsí.+   Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀,+Kí ẹni ibi sì yí èrò rẹ̀ pa dà;Kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀,+Sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, torí ó máa dárí jini fàlàlà.*+   “Torí èrò mi yàtọ̀ sí èrò yín,+Ọ̀nà yín sì yàtọ̀ sí ọ̀nà mi,” ni Jèhófà wí.   “Torí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,Èrò mi sì ga ju èrò yín.+ 10  Torí bí òjò àti yìnyín ṣe ń rọ̀ láti ọ̀run gẹ́lẹ́,Tí kì í sì í pa dà síbẹ̀, àfi tó bá mú kí ilẹ̀ rin, tó jẹ́ kó méso jáde, kí nǹkan sì hù,Tó jẹ́ kí ẹni tó fúnrúgbìn ká irúgbìn, tí ẹni tó ń jẹun sì rí oúnjẹ, 11  Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde máa rí.*+ Kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ,+Àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí,*+Ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere. 12  Ẹ máa fi ayọ̀ jáde lọ,+A sì máa mú yín pa dà ní àlàáfíà.+ Àwọn òkè ńlá àtàwọn òkè kéékèèké máa fi igbe ayọ̀ túra ká níwájú yín,+Gbogbo àwọn igi inú igbó sì máa pàtẹ́wọ́.+ 13  Dípò àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún, igi júnípà máa hù,+Dípò èsìsì tó ń jóni lára, igi mátílì máa hù. Ó sì máa mú kí Jèhófà lókìkí,*+Àmì tó máa wà títí láé, tí kò ní pa run.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “owó tí ẹ ṣiṣẹ́ kára fún.”
Ní Héb., “Ọ̀rá.”
Tàbí “ọkàn yín yọ̀.”
Tàbí “tó ṣeé gbọ́kàn lé; tó ṣeé gbára lé.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Ní Héb., “lọ́nà títóbi.”
Tàbí “tó bá jẹ́ ìfẹ́ mi.”
Tàbí “máa já sí.”
Tàbí “ṣe orúkọ fún Jèhófà.”