Àìsáyà 56:1-12

  • Àwọn àjèjì àti àwọn ìwẹ̀fà máa rí ìbùkún (1-8)

    • Ilé àdúrà fún gbogbo èèyàn (7)

  • Àwọn olùṣọ́ tó fọ́jú, ajá tí kò lè fọhùn (9-12)

56  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo,+ kí ẹ sì máa ṣe òdodo,Torí ìgbàlà mi máa tó dé,A sì máa ṣí òdodo mi payá.+   Aláyọ̀ ni ẹni tó ń ṣe èyíÀti ọmọ èèyàn tó rọ̀ mọ́ ọn,Tó ń pa Sábáàtì mọ́, tí kò sì kẹ́gàn rẹ̀,+Tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohunkóhun tó burú.   Àjèjì tó bá fara mọ́ Jèhófà+ ò gbọ́dọ̀ sọ pé,‘Ó dájú pé Jèhófà máa yà mí sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn rẹ̀.’ Ìwẹ̀fà ò sì gbọ́dọ̀ sọ pé, ‘Wò ó! Igi gbígbẹ ni mí.’”  Torí ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn ìwẹ̀fà nìyí, àwọn tó ń pa àwọn sábáàtì mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí inú mi dùn sí, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi:   “Màá fún wọn ní ohun ìrántí àti orúkọ ní ilé mi àti lára àwọn ògiri mi,Ohun tó dára ju àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin. Màá fún wọn ní orúkọ tó máa wà títí láé,Èyí tí kò ní pa run.   Ní ti àwọn àjèjì tó fara mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un,Láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà,+Kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀,Gbogbo àwọn tó ń pa Sábáàtì mọ́, tí wọn ò sì kẹ́gàn rẹ̀,Tí wọ́n ń rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi,   Màá tún mú wọn wá sí òkè mímọ́ mi,+Màá sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Màá tẹ́wọ́ gba odindi ẹbọ sísun wọn àtàwọn ẹbọ wọn lórí pẹpẹ mi. Torí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo èèyàn.”+  Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tó ń kó àwọn tó fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ,+ kéde pé: “Màá kó àwọn míì jọ sọ́dọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kó jọ tẹ́lẹ̀.”+   Gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá, ẹ wá jẹun,Gbogbo ẹ̀yin ẹran inú igbó.+ 10  Afọ́jú ni àwọn olùṣọ́ rẹ̀,+ ìkankan nínú wọn ò kíyè sí i.+ Ajá tí kò lè fọhùn ni gbogbo wọn, wọn ò lè gbó.+ Wọ́n ń mí hẹlẹ, wọ́n sì dùbúlẹ̀; wọ́n fẹ́ràn oorun. 11  Ajá tó ń jẹun wọ̀mùwọ̀mù* ni wọ́n;Wọn kì í yó. Olùṣọ́ àgùntàn tí kò lóye ni wọ́n.+ Gbogbo wọn ti bá ọ̀nà tiwọn lọ;Àní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń wá èrè tí kò tọ́ fún ara rẹ̀, ó ń sọ pé: 12  “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí n mu wáìnì díẹ̀,Ẹ sì jẹ́ ká mu ọtí yó.+ Bí òní ṣe rí ni ọ̀la máa rí, ó tiẹ̀ máa dáa gan-an jù ú lọ!”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó ní ọkàn tó le.”