Àìsáyà 57:1-21

  • Olódodo àti àwọn olóòótọ́ ṣègbé (1, 2)

  • Àgbèrè ẹ̀sìn tí Ísírẹ́lì ń ṣe hàn síta (3-13)

  • A tu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ nínú (14-21)

    • Àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru (20)

    • Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú (21)

57  Olódodo ṣègbé,Àmọ́ ẹnì kankan ò fi sọ́kàn. Àwọn olóòótọ́ èèyàn ti lọ,*+Ẹnì kankan ò sì fòye mọ̀ pé olódodo ti lọTorí* àjálù náà.   Ó wọnú àlàáfíà. Wọ́n sinmi lórí ibùsùn wọn,* gbogbo àwọn tó ń rìn lọ́nà títọ́.   “Àmọ́ ní tiyín, ẹ sún mọ́ tòsí,Ẹ̀yin ọmọ àjẹ́,Ẹ̀yin ọmọ alágbèrè àti aṣẹ́wó:   Ta lẹ fi ń ṣe yẹ̀yẹ́? Ta lẹ la ẹnu gbàù sí, tí ẹ sì yọ ahọ́n yín sí? Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín,Ẹ̀yin ọmọ ẹ̀tàn,+   Tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti kó sí lórí láàárín àwọn igi ńlá,+Lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì,+Lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta?   Ìpín rẹ wà níbi àwọn òkúta tó jọ̀lọ̀ ní àfonífojì.+ Àní, àwọn ni ìpín rẹ. Kódà, àwọn lò ń da ọrẹ ohun mímu sí, tí o sì ń mú ẹ̀bùn wá fún.+ Ṣé àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ mi lọ́rùn?*   Orí òkè tó ga, tó ta yọ lo gbé ibùsùn rẹ sí,+O sì gòkè lọ síbẹ̀ láti rúbọ.+   Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn àti férémù ilẹ̀kùn lo gbé ìrántí rẹ kalẹ̀ sí. O fi mí sílẹ̀, o sì ṣí ara rẹ sílẹ̀;O lọ, o sì mú kí ibùsùn rẹ fẹ̀ dáadáa. O sì bá wọn dá májẹ̀mú. O máa ń fẹ́ bá wọn pín ibùsùn wọn,+O sì ń wo nǹkan ọkùnrin.*   O sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Mélékì* pẹ̀lú òróróÀti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́fínńdà. O rán àwọn aṣojú rẹ lọ sọ́nà jíjìn,Tí o fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú.* 10  O ti ṣiṣẹ́ kára láti rìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà rẹ. Àmọ́ o ò sọ pé, ‘Kò sírètí!’ A wá sọ agbára rẹ dọ̀tun. Ìdí nìyẹn tí o kò fi sọ̀rètí nù.* 11  Ta ló ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ sì ń bà ọ́,Tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí í parọ́?+ O ò rántí mi.+ O ò fi nǹkan kan sọ́kàn.+ Ṣebí mo ti dákẹ́, tí mo sì fà sẹ́yìn?*+ O ò wá bẹ̀rù mi rárá. 12  Màá fi ‘òdodo’+ rẹ àti àwọn iṣẹ́ rẹ+ hàn,Wọn ò sì ní ṣe ọ́ láǹfààní.+ 13  Tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́,Àwọn òrìṣà tí o kó jọ ò ní gbà ọ́ sílẹ̀.+ Atẹ́gùn máa gbé gbogbo wọn lọ,Èémí lásán máa fẹ́ wọn lọ,Àmọ́ ẹni tó bá fi mí ṣe ibi ààbò máa jogún ilẹ̀ náà,Ó sì máa gba òkè mímọ́ mi.+ 14  Wọ́n máa sọ pé, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe é! Ẹ tún ọ̀nà ṣe!+ Ẹ mú gbogbo ohun ìdíwọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn èèyàn mi.’” 15  Torí ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Tó Ta Yọ sọ nìyí,Tó wà láàyè* títí láé,+ tí orúkọ rẹ̀ sì jẹ́ mímọ́:+ “Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé,+Àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,Láti mú kí ẹ̀mí ẹni tó rẹlẹ̀ sọ jí,Kí n sì mú kí ọkàn àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.+ 16  Torí mi ò ní ta kò wọ́n títí láé,Mi ò sì ní máa bínú títí lọ;+Torí àárẹ̀ máa bá ẹ̀mí èèyàn nítorí mi,+Títí kan àwọn ohun tó ń mí, tí mo dá. 17  Inú bí mi torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, bó ṣe ń wá èrè tí kò tọ́,+Torí náà, mo kọ lù ú, mo fi ojú mi pa mọ́, inú sì bí mi. Àmọ́ kò yéé rìn bí ọ̀dàlẹ̀,+ ó ń ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ̀. 18  Mo ti rí àwọn ọ̀nà rẹ̀,Àmọ́ màá wò ó sàn,+ màá sì darí rẹ̀,+Màá mú kí òun àti àwọn èèyàn rẹ̀+ tó ń ṣọ̀fọ̀ pa dà rí ìtùnú.”*+ 19  “Màá dá èso ètè. Màá fún ẹni tó wà lọ́nà jíjìn àti ẹni tó wà nítòsí ní àlàáfíà tí kò lópin,”+ ni Jèhófà wí,“Màá sì wò ó sàn.” 20  “Àmọ́ àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru, tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀,Omi rẹ̀ sì ń ta koríko inú òkun àti ẹrẹ̀ sókè. 21  Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú,”+ ni Ọlọ́run mi wí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn ni pé, wọ́n kú.
Tàbí kó jẹ́, “Kúrò lọ́wọ́.”
Ìyẹn, nínú sàréè.
Tàbí “Ṣé kí n fi àwọn nǹkan yìí tu ara mi nínú ni?”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìjọsìn òrìṣà ló ń sọ.
Tàbí kó jẹ́, “ọba.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “tí kò fi rẹ̀ ọ́.”
Tàbí “fi ọ̀rọ̀ pa mọ́?”
Tàbí “Tó ń gbé.”
Tàbí “Màá sì fi ìtùnú san àsandípò fún òun àti àwọn èèyàn rẹ̀.”