Àìsáyà 9:1-21
9 Àmọ́, ìṣúdùdù náà kò ní rí bí ìgbà tí ìdààmú bá ilẹ̀ náà, bí ìgbà àtijọ́ tí wọ́n hùwà àbùkù sí ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì.+ Àmọ́ tó bá yá, Ó máa mú kí a bọlá fún un, ní ọ̀nà ibi òkun, ní agbègbè Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.
2 Àwọn èèyàn tó ń rìn nínú òkùnkùn
Ti rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò.
Ní ti àwọn tó ń gbé ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri,Ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.+
3 O ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀;O ti mú kó máa yọ̀ gidigidi.
Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹBí àwọn èèyàn ṣe ń yọ̀ nígbà ìkórè,Bí àwọn tó ń fayọ̀ pín ẹrù ogun.
4 Torí o ti fọ́ àjàgà ẹrù wọn sí wẹ́wẹ́,Ọ̀pá tó wà ní èjìká wọn, ọ̀pá ẹni tó ń kó wọn ṣiṣẹ́,Bíi ti ọjọ́ Mídíánì.+
5 Gbogbo bàtà tó ń kilẹ̀ bó ṣe ń lọÀti gbogbo aṣọ tí wọ́n rì bọnú ẹ̀jẹ̀Ló máa di ohun tí wọ́n fi ń dá iná.
6 Torí a ti bí ọmọ kan fún wa,+A ti fún wa ní ọmọkùnrin kan;Àkóso* sì máa wà ní èjìká rẹ̀.+
Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.
7 Àkóso* rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ,Àlàáfíà kò sì ní lópin,+Lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀,Kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+ kó sì gbé e ró,Nípasẹ̀ ìdájọ́+ tí ó tọ́ àti òdodo,+Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.
8 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ kan ránṣẹ́ sí Jékọ́bù,Ó sì ti wá sórí Ísírẹ́lì.+
9 Gbogbo èèyàn sì máa mọ̀ ọ́n,Éfúrémù àti àwọn tó ń gbé ní Samáríà,Tí wọ́n ń fi ìgbéraga àti àfojúdi ọkàn sọ pé:
10 “Àwọn bíríkì ti wó,Àmọ́ òkúta tí wọ́n gbẹ́ la máa fi kọ́lé.+
Wọ́n ti gé àwọn igi síkámórè lulẹ̀,Àmọ́ á máa fi àwọn igi kédárì rọ́pò wọn.”
11 Jèhófà máa gbé àwọn elénìní Résínì dìde sí i,Ó sì máa ru àwọn ọ̀tá rẹ̀ sókè láti jagun,
12 Síríà láti ìlà oòrùn àti àwọn Filísínì láti ìwọ̀ oòrùn,*+Wọ́n máa la ẹnu wọn, wọ́n á sì jẹ Ísírẹ́lì run.+
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+
13 Torí àwọn èèyàn náà kò tíì pa dà sọ́dọ̀ Ẹni tó ń lù wọ́n;Wọn ò wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+
14 Jèhófà máa gé orí àti ìrù, ọ̀mùnú àti koríko etídò*Kúrò ní Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ kan ṣoṣo.+
15 Àgbà ọkùnrin àti ẹni tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni orí,Wòlíì tó ń fúnni ní ìtọ́ni èké sì ni ìrù.+
16 Àwọn tó ń darí àwọn èèyàn yìí ń mú kí wọ́n rìn gbéregbère,Nǹkan sì ti dà rú mọ́ àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn lójú.
17 Ìdí nìyẹn tí inú Jèhófà ò fi ní dùn sí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn,Kò sì ní ṣàánú àwọn ọmọ aláìníbaba* àti àwọn opó wọnTorí apẹ̀yìndà àti aṣebi ni gbogbo wọn,+Gbogbo ẹnu sì ń sọ ọ̀rọ̀ òpònú.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+
18 Torí pé ìwà burúkú máa ń jó bí iná,Ó ń jó àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò run.
Ó máa dáná sí igbó tó díjú,Èéfín wọn tó ṣú sì máa ròkè lálá.
19 Torí ìbínú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,A ti dáná sí ilẹ̀ náà,Wọ́n á sì fi àwọn èèyàn náà dáná.
Ẹnì kankan ò ní dá ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ pàápàá sí.
20 Ẹnì kan máa gé nǹkan lulẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún,Àmọ́ ebi á ṣì máa pa á;Ẹnì kan sì máa jẹun ní ọwọ́ òsì,Àmọ́ kò ní yó.
Kálukú máa jẹ ẹran apá rẹ̀,
21 Mánásè máa jẹ Éfúrémù run,Éfúrémù sì máa jẹ Mánásè run.
Wọ́n máa para pọ̀ gbéjà ko Júdà.+
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ìjọba; Ìṣàkóso ọmọ aládé.”
^ Tàbí “Ìjọba; Ìṣàkóso ọmọ aládé.”
^ Ní Héb., “láti ẹ̀yìn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “imọ̀ ọ̀pẹ àti koríko etí omi.”
^ Tàbí “aláìlóbìí.”