Àwọn Onídàájọ́ 1:1-36

  • Àwọn tí Júdà àti Síméónì ṣẹ́gun (1-20)

  • Àwọn ará Jébúsì ò kúrò ní Jerúsálẹ́mù (21)

  • Jósẹ́fù gba Bẹ́tẹ́lì (22-26)

  • Wọn ò lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò tán (27-36)

1  Lẹ́yìn tí Jóṣúà kú,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ta ló máa kọ́kọ́ lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì jagun nínú wa?”  Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni kó lọ.+ Wò ó! Màá fi* ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”  Júdà wá sọ fún Síméónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé: “Jẹ́ ká jọ lọ sí ilẹ̀ tí wọ́n fún mi,*+ ká lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì jà. Èmi náà á sì bá ọ lọ sí ilẹ̀ tí wọ́n fún ọ.” Torí náà, Síméónì tẹ̀ lé e lọ.  Nígbà tí Júdà lọ, Jèhófà fi àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì lé wọn lọ́wọ́,+ wọ́n sì ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ní Bésékì.  Wọ́n rí Adoni-bésékì ní Bésékì, wọ́n bá a jà níbẹ̀, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì+ àti àwọn Pérísì.+  Nígbà tí Adoni-bésékì sá lọ, wọ́n lé e bá, wọ́n mú un, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ àti ti ẹsẹ̀ rẹ̀.  Adoni-bésékì wá sọ pé: “Àádọ́rin (70) ọba ni mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ àti ti ẹsẹ̀ wọn, tí wọ́n sì ń ṣa oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Ohun tí mo ṣe gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run fi san mí lẹ́san.” Lẹ́yìn náà, wọ́n mú un wá sí Jerúsálẹ́mù,+ ó sì kú síbẹ̀.  Bákan náà, àwọn ọkùnrin Júdà bá Jerúsálẹ́mù+ jà, wọ́n sì gbà á; wọ́n fi idà pa á run, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Júdà lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé agbègbè olókè jà, wọ́n tún bá Négébù àti Ṣẹ́fẹ́là+ jà. 10  Júdà tún lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Hébúrónì jà (Kiriati-ábà ni Hébúrónì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀), wọ́n sì pa Ṣéṣáì, Áhímánì àti Tálímáì.+ 11  Wọ́n kúrò níbẹ̀ lọ bá àwọn tó ń gbé Débírì+ jà. (Kiriati-séférì+ ni Débírì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.) 12  Kélẹ́bù+ wá sọ pé: “Ẹni tó bá pa Kiriati-séférì run, tó sì gbà á, màá fún un ní Ákúsà ọmọ mi pé kó fi ṣe aya.”+ 13  Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì,+ àbúrò Kélẹ́bù sì gbà á. Torí náà, ó fún un ní Ákúsà ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 14  Nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sílé, ó rọ ọmọkùnrin náà pé kó tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ bàbá òun. Ọmọbìnrin náà wá sọ̀ kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.* Kélẹ́bù sì bi í pé: “Kí lo fẹ́?” 15  Ó sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, bù kún mi, o ti fún mi ní ilẹ̀ kan ní gúúsù;* tún fún mi ní Guloti-máímù.”* Torí náà, Kélẹ́bù fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀. 16  Àtọmọdọ́mọ àwọn Kénì,+ tó jẹ́ bàbá ìyàwó Mósè+ pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà wá láti ìlú ọlọ́pẹ+ sí aginjù Júdà, tó wà ní gúúsù Árádì.+ Wọ́n lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń gbé láàárín àwọn èèyàn náà.+ 17  Àmọ́ Júdà ń tẹ̀ lé Síméónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, wọ́n gbéjà ko àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé Séfátì, wọ́n sì pa wọ́n run.+ Wọ́n wá pe orúkọ ìlú náà ní Hóómà.*+ 18  Nígbà náà, Júdà gba Gásà+ àti agbègbè rẹ̀, Áṣíkẹ́lónì+ àti agbègbè rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ́kírónì+ àti agbègbè rẹ̀. 19  Jèhófà wà pẹ̀lú Júdà, wọ́n sì gba agbègbè olókè náà, àmọ́ wọn ò lè lé àwọn tó ń gbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà kúrò, torí pé wọ́n ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin.*+ 20  Wọ́n fún Kélẹ́bù ní Hébúrónì, bí Mósè ṣe ṣèlérí,+ ó sì lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kúrò níbẹ̀. 21  Àmọ́ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ò lé àwọn ará Jébúsì tó ń gbé Jerúsálẹ́mù kúrò, torí náà, àwọn ará Jébúsì ṣì ń bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì gbé ní Jerúsálẹ́mù títí dòní.+ 22  Ìgbà yẹn ni ilé Jósẹ́fù+ lọ bá Bẹ́tẹ́lì jà, Jèhófà sì wà pẹ̀lú wọn.+ 23  Nígbà tí ilé Jósẹ́fù ń ṣe amí Bẹ́tẹ́lì (bẹ́ẹ̀ sì rèé, Lúsì+ ni ìlú náà ń jẹ́ tẹ́lẹ̀), 24  àwọn amí náà rí ọkùnrin kan tó ń jáde lọ látinú ìlú náà. Torí náà, wọ́n sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fi ọ̀nà tí a máa gbà wọnú ìlú yìí hàn wá, a sì máa ṣe ọ́ dáadáa.”* 25  Ọkùnrin náà wá fi ọ̀nà tí wọ́n máa gbà wọnú ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi idà pa ìlú náà run, àmọ́ wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ sí.+ 26  Ọkùnrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì, ó kọ́ ìlú kan síbẹ̀, ó sì pè é ní Lúsì, orúkọ ìlú náà nìyẹn títí dòní. 27  Mánásè ò gba Bẹti-ṣéánì àti àwọn àrọko rẹ̀,* Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Dórì àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Íbíléámù àti àwọn àrọko+ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé Mẹ́gídò àti àwọn àrọko rẹ̀. Àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé ní ilẹ̀ yìí. 28  Nígbà tí Ísírẹ́lì lágbára sí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó àwọn ọmọ Kénáánì ṣiṣẹ́ àṣekára,+ àmọ́ wọn ò lé wọn kúrò pátápátá.+ 29  Éfúrémù náà ò lé àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ní Gésérì kúrò. Àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé láàárín wọn ní Gésérì.+ 30  Sébúlúnì ò lé àwọn tó ń gbé Kítírónì kúrò àti àwọn tó ń gbé Náhálólì.+ Àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé láàárín wọn, wọ́n sì ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára.+ 31  Áṣérì ò lé àwọn tó ń gbé Ákò kúrò, kò sì lé àwọn tó ń gbé Sídónì,+ Álábù, Ákísíbù,+ Hélíbà, Áfíkì+ àti Réhóbù+ kúrò. 32  Àwọn ọmọ Áṣérì ṣì ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà, torí pé wọn ò lé wọn kúrò. 33  Náfútálì ò lé àwọn tó ń gbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti àwọn tó ń gbé Bẹti-ánátì+ kúrò, wọ́n ṣì ń gbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó àwọn tó ń gbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti Bẹti-ánátì ṣiṣẹ́ àṣekára. 34  Àwọn Ámórì sé àwọn ọmọ Dánì mọ́ agbègbè olókè, wọn ò jẹ́ kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.+ 35  Torí náà, àwọn Ámórì ṣì ń gbé ní Òkè Hérésì, Áíjálónì+ àti Ṣáálíbímù.+ Àmọ́ nígbà tí agbára* ilé Jósẹ́fù pọ̀ sí i,* wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó wọn ṣiṣẹ́ àṣekára. 36  Ilẹ̀ àwọn Ámórì bẹ̀rẹ̀ láti ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù,+ láti Sẹ́ẹ́là sókè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “Mo ti fi.”
Ní Héb., “tí wọ́n fi kèké pín fún mi.”
Tàbí kó jẹ́, “ó pàtẹ́wọ́ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.”
Tàbí “Négébù.”
Ó túmọ̀ sí “Bàsíà (Abọ́) Omi.”
Ó túmọ̀ sí “Ìparun Pátápátá.”
Ní Héb., “kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n fi irin ṣe.”
Ní Héb., “fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “ọwọ́.”
Ní Héb., “rinlẹ̀.”