Àwọn Onídàájọ́ 10:1-18

  • Tólà àti Jáírì onídàájọ́ (1-5)

  • Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀, ó sì ronú pìwà dà (6-16)

  • Àwọn ọmọ Ámónì halẹ̀ mọ́ Ísírẹ́lì (17, 18)

10  Lẹ́yìn Ábímélékì, Tólà ọmọ Púà, ọmọ Dódò, ọkùnrin kan látinú ìdílé Ísákà, dìde láti gba Ísírẹ́lì sílẹ̀.+ Ṣámírù ló ń gbé, ní agbègbè olókè Éfúrémù.  Ọdún mẹ́tàlélógún (23) ló fi jẹ́ onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, ó kú, wọ́n sì sin ín sí Ṣámírù.  Lẹ́yìn rẹ̀, Jáírì ọmọ Gílíádì dìde, ó sì ṣe onídàájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méjìlélógún (22).  Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin tó ń gun ọgbọ̀n (30) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì ní ọgbọ̀n (30) ìlú, èyí tí wọ́n ń pè ní Hafotu-jáírì+ títí di òní yìí; wọ́n wà ní ilẹ̀ Gílíádì.  Lẹ́yìn náà, Jáírì kú, wọ́n sì sin ín sí Kámónì.  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn Báálì,+ àwọn ère Áṣítórétì, àwọn ọlọ́run Árámù,* àwọn ọlọ́run Sídónì, àwọn ọlọ́run Móábù,+ àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn ọlọ́run àwọn Filísínì.+ Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọn ò sì sìn ín.  Jèhófà wá bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n lé àwọn Filísínì àtàwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́.+  Wọ́n ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n gidigidi ní ọdún yẹn. Ọdún méjìdínlógún (18) ni wọ́n fi fìyà jẹ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì lápá ibi tó jẹ́ ilẹ̀ àwọn Ámórì tẹ́lẹ̀ ní Gílíádì.  Àwọn ọmọ Ámónì náà máa ń sọdá Jọ́dánì láti lọ bá Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti ilé Éfúrémù jà; ìdààmú sì bá Ísírẹ́lì gidigidi. 10  Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ wọ́n sọ pé: “A ti ṣẹ̀ ọ́, torí a fi Ọlọ́run wa sílẹ̀, a sì ń sin àwọn Báálì.”+ 11  Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ṣebí mo gbà yín lọ́wọ́ Íjíbítì+ àti lọ́wọ́ àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì,+ 12  àwọn ọmọ Sídónì, Ámálékì àti Mídíánì, nígbà tí wọ́n ń fìyà jẹ yín? Nígbà tí ẹ ké pè mí, mo gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. 13  Àmọ́ ẹ fi mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin àwọn ọlọ́run míì.+ Ìdí nìyẹn tí mi ò fi ní gbà yín sílẹ̀ mọ́.+ 14  Ẹ lọ bá àwọn ọlọ́run tí ẹ yàn, kí ẹ sì ké pè wọ́n pé kí wọ́n ràn yín lọ́wọ́.+ Kí wọ́n gbà yín sílẹ̀ nígbà tí wàhálà dé bá yín.”+ 15  Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ fún Jèhófà pé: “A ti ṣẹ̀. Ohunkóhun tó bá dáa lójú rẹ ni kí o ṣe sí wa. Jọ̀ọ́, ṣáà ti gbà wá sílẹ̀ lónìí.” 16  Wọ́n wá kó àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò láàárín wọn, wọ́n sì ń sin Jèhófà,+ débi pé ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́* bí Ísírẹ́lì ṣe ń jìyà.+ 17  Nígbà tó yá, a pe àwọn ọmọ Ámónì+ jọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Gílíádì. Torí náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Mísípà. 18  Àwọn èèyàn náà àtàwọn ìjòyè Gílíádì sọ fún ara wọn pé: “Ta ló máa ṣáájú láti lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà?+ Kó di olórí gbogbo àwọn tó ń gbé Gílíádì.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Síríà.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ mọ́ torí.”