Àwọn Onídàájọ́ 15:1-20

  • Sámúsìn gbẹ̀san lára àwọn Filísínì (1-20)

15  Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, nígbà ìkórè àlìkámà,* Sámúsìn lọ wo ìyàwó rẹ̀, ó mú ọmọ ewúrẹ́ kan dání. Ó sọ pé: “Ó wù mí kí n lọ bá ìyàwó mi nínú yàrá.”* Àmọ́ bàbá obìnrin náà ò jẹ́ kó wọlé.  Bàbá obìnrin náà sọ pé: “Èrò mi ni pé, ‘Ó dájú pé o kórìíra rẹ̀.’+ Torí náà, mo fún ọ̀rẹ́ ìwọ ọkọ ìyàwó.+ Ṣebí àbúrò rẹ̀ rẹwà jù ú lọ? Jọ̀ọ́, mú un dípò rẹ̀.”  Àmọ́ Sámúsìn sọ fún wọn pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn Filísínì ò lè dá mi lẹ́bi pé mo ṣe wọ́n léṣe.”  Torí náà, Sámúsìn lọ mú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. Ó wá mú àwọn ògùṣọ̀, ó so ìrù àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà mọ́ra, ó sì fi ògùṣọ̀ kan sáàárín ìrù méjì.  Ó wá fi iná sí àwọn ògùṣọ̀ náà, ó sì rán àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà lọ sínú oko ọkà àwọn Filísínì. Gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ ló dáná sun, látorí ìtí ọkà dórí ọkà tó wà ní òró, títí kan àwọn ọgbà àjàrà àti àwọn igi ólífì.  Àwọn Filísínì béèrè pé: “Ta ló ṣe èyí?” Wọ́n sọ fún wọn pé: “Sámúsìn ọkọ ọmọ ará Tímúnà ni, torí pé ọkùnrin náà gba ìyàwó rẹ̀, ó sì fún ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó.”+ Ni àwọn Filísínì bá lọ dáná sun obìnrin náà àti bàbá rẹ̀.+  Sámúsìn wá sọ fún wọn pé: “Tó bá jẹ́ pé bí ẹ ṣe ń ṣe nìyí, mi ò ní jáwọ́ títí màá fi gbẹ̀san lára yín.”+  Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í pa wọ́n níkọ̀ọ̀kan,* ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, lẹ́yìn náà, ó lọ ń gbé inú ihò* kan ní àpáta Étámì.  Lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì wá pàgọ́ sí Júdà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn káàkiri Léhì.+ 10  Àwọn ọkùnrin Júdà wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ wá gbógun tì wá?” Wọ́n fèsì pé: “A wá mú* Sámúsìn ni, ká lè ṣe ohun tó ṣe fún wa sí òun náà.” 11  Torí náà, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin Júdà wá lọ síbi ihò* àpáta Étámì, wọ́n sì sọ fún Sámúsìn pé: “Ṣé o ò mọ̀ pé àwọn Filísínì ló ń jọba lórí wa ni?+ Kí ló dé tí o ṣe báyìí sí wa?” Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni mo ṣe sí wọn.” 12  Àmọ́ wọ́n sọ fún un pé: “A wá mú* ọ ká lè fi ọ́ lé àwọn Filísínì lọ́wọ́ ni.” Sámúsìn wá sọ pé: “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin fúnra yín ò ní ṣèkà fún mi.” 13  Wọ́n sọ fún un pé: “Rárá, a kàn máa dè ọ́ ni, a sì máa fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àmọ́ a ò ní pa ọ́.” Wọ́n wá fi okùn tuntun méjì dè é, wọ́n sì gbé e jáde nínú àpáta náà. 14  Nígbà tó dé Léhì, àwọn Filísínì kígbe ayọ̀ bí wọ́n ṣe rí i. Nígbà náà, ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ àwọn okùn tí wọ́n fi de ọwọ́ rẹ̀ wá dà bíi fọ́nrán òwú ọ̀gbọ̀ tí iná jó gbẹ, àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ sì yọ́.+ 15  Ó rí egungun tútù kan tó jẹ́ egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; ó na ọwọ́ mú un, ó sì fi ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.+ 16  Sámúsìn wá sọ pé: “Pẹ̀lú egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, òkìtì kan, òkìtì méjì! Mo fi egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣá ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin balẹ̀.”+ 17  Nígbà tó sọ̀rọ̀ tán, ó sọ egungun náà nù, ó sì pe ibẹ̀ ní Ramati-léhì.*+ 18  Òùngbẹ wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ ẹ́ gan-an, ló bá ké pe Jèhófà, ó sì sọ pé: “Ìwọ lo jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà, àmọ́ ṣé kí òùngbẹ wá pa mí ni, kí ọwọ́ àwọn aláìdádọ̀dọ́* sì tẹ̀ mí?” 19  Ọlọ́run wá mú kí kòtò kan tó wà ní Léhì lanu, omi sì ṣàn jáde látinú rẹ̀.+ Nígbà tó mumi, okun* rẹ̀ pa dà, ó sì sọ jí. Ìdí nìyẹn tó fi pe ibẹ̀ ní Ẹn-hákórè,* èyí tó wà ní Léhì títí dòní. 20  Ogún (20) ọdún+ ló fi jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì nígbà ayé àwọn Filísínì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “yàrá inú.”
Ní Héb., “pa wọ́n, ẹsẹ̀ lórí itan.”
Tàbí “pàlàpálá.”
Tàbí “de.”
Tàbí “pàlàpálá.”
Tàbí “dè.”
Ó túmọ̀ sí “Ibi Gíga Egungun Páárì Ẹ̀rẹ̀kẹ́.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ẹ̀mí.”
Ó túmọ̀ sí “Ìsun Omi Ẹni Tó Ń Pè.”