Àwọn Onídàájọ́ 17:1-13

  • Àwọn ère Míkà àti àlùfáà rẹ̀ (1-13)

17  Ọkùnrin kan wà ní agbègbè olókè Éfúrémù+ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà.  Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà tí wọ́n kó lọ́dọ̀ rẹ, tí mo gbọ́ tí o gégùn-ún nípa rẹ̀, wò ó! fàdákà náà wà lọ́wọ́ mi. Èmi ni mo kó o.” Ni ìyá rẹ̀ bá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi.”  Ó wá kó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, àmọ́ ìyá rẹ̀ sọ pé: “Ó dájú pé màá ya fàdákà náà sí mímọ́ fún Jèhófà látọwọ́ mi, kí ọmọ mi lè fi ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin.*+ Mo fún ọ pa dà báyìí.”  Lẹ́yìn tó dá fàdákà náà pa dà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba (200) ẹyọ fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà. Ó ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin;* wọ́n sì gbé e sínú ilé Míkà.  Ọkùnrin tó ń jẹ́ Míkà yìí ní ilé kan tó kó àwọn ọlọ́run rẹ̀ sí, ó ṣe éfódì kan+ àti àwọn ère tẹ́ráfímù,*+ ó sì yan* ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ pé kó jẹ́ àlùfáà rẹ̀.+  Nígbà yẹn, kò sí ọba ní Ísírẹ́lì.+ Kálukú ń ṣe ohun tó tọ́ lójú ara rẹ̀.*+  Ọ̀dọ́kùnrin kan wà tó jẹ́ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, látinú ìdílé Júdà. Ọmọ Léfì+ ni, ó sì ti ń gbé níbẹ̀ fúngbà díẹ̀.  Ọkùnrin náà kúrò nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ó ń wá ibi tó máa gbé. Bó ṣe ń rìnrìn àjò lọ, ó dé agbègbè olókè Éfúrémù, ní ilé Míkà.+  Míkà wá bi í pé: “Ibo lo ti wá?” Ó fèsì pé: “Ọmọ Léfì ni mí, láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, mò ń wá ibi tí mo lè máa gbé.” 10  Míkà wá sọ fún un pé: “Dúró sọ́dọ̀ mi, kí o di bàbá* àti àlùfáà fún mi. Màá máa fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá lọ́dún, pẹ̀lú àwọn aṣọ àti oúnjẹ tí wàá máa jẹ.” Ọmọ Léfì náà sì wọlé. 11  Bí ọmọ Léfì náà ṣe gbà láti máa gbé lọ́dọ̀ ọkùnrin náà nìyẹn, ọ̀dọ́kùnrin náà sì wá dà bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12  Yàtọ̀ síyẹn, Míkà fiṣẹ́ lé ọmọ Léfì náà lọ́wọ́* pé kó di àlùfáà rẹ̀,+ ó sì ń gbé ní ilé Míkà. 13  Míkà wá sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé Jèhófà máa ṣe rere sí mi, torí pé ọmọ Léfì ti di àlùfáà mi.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “ère dídà.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”
Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”
Tàbí “agbani-nímọ̀ràn.”
Ní Héb., “fi kún ọwọ́ ọmọ Léfì náà.”